Ilé ẹjọ́ yẹ àga mọ́ olùdíje LP nídìí, Ó ní APC ló wọlé

Aworan Asia Ileẹjọ

Oríṣun àwòrán, Daily post

Ileẹjọ to n gbọ awuyewuye esi idibo nipinlẹ Eko ti wọgile ibo to gbe Seyi Sowunmi ti ẹgbẹ oselu Labour Party wọle gẹgẹ aṣoju ẹkun idibo Ojo nipinlẹ Eko.

Igbimọ ẹlẹni mẹta to gbe idajọ naa kalẹ, eyi ti Adajọ Abdullahi Ozegya lewaju rẹ kede pe Lanre Ogunyemi ti ẹgbẹ oselu All Progressives Congress lo jawe olubori nínu eto idibo sile igbimọ aṣofin apapọ to waye lọjọ kẹdọgbọn oṣu kejì ọdun 2023.

Awọn igbimọ yooku ni Adajọ Ashu Ewah ati Adajọ Muhammad Sambo.

Ogunyemi, ẹni to ti lo saa meji ọtọọtọ gẹgẹbi asojuṣofin fun ẹkun Ọjọ nipinlẹ Eko nile aṣofin apapọ keji nilu Abuja gbe igbesẹ lati tako esi idibo to gbe Sowunmi wọle.

Ogunyemi fẹsun kan Sowunmi pe ko lẹtọ lati jade dupo aṣoju fun ẹkun idibo Ojo nipinlẹ Eko ati labẹ ẹgbẹ oselu Labour Party.

Nínu Idajọ, ileẹjọ gba pẹlu olpuẹjọ pe Oludije ẹgbẹ oselu Labour Party ko lẹtọ lati kopa ninu eto idibo naa.