Wo bí Amala, moimoi, àtàwọn ọ̀rọ̀ míì ṣe wọ ìwé atúmọ̀ èdè Oxford àti ìtumọ̀ tí wọ́n fún wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìwé atúmọ̀ èdè, Oxford English Dictionary, ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí orírun wọn jẹ́ ti Nàìjíríà sára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń túmọ̀ nínú ìwé náà.
Nínú àtẹ̀jáde ti oṣù Kejìlá, ọdún 2025 tí wọ́n fi léde lójú òpó ìtàkùn ayélujára wọn ṣàfihàn àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sínú ìwé atúmọ̀ èdè náà tó fi mọ́ DM, amala, moimoi, brainfart àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn ọ̀rọ̀ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ni wọ́n ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀, tí wọ́n sì ń wá ìtàn tó rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ bíi troll àti snooker.
Àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tí wọ́n fi kún ìwé atúmọ̀ yìí ló jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n yọ lára èdè Gẹ̀ẹ́sì káàkiri àgbáyé bíi èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń sọ ní ìwọ̀ oòrùn Africa, Japan, South Africa àti Malta.
Lára àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tó wọ ìwé atúmọ̀ èdè náà láti Nàìjíríà ni nyash," "mammy market," "amala," "moi moi," "abeg," "biko," àti "Ghana Must Go."
Bákan náà ni "Afrobeats" tó túmọ̀ sí orin ìwọ̀ oòrùn Africa àti àpapọ̀ jazz àti sóòlù.
Àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tí wọ́n fi kún ìwé atúmọ̀ yìí ló jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n yọ lára èdè Gẹ̀ẹ́sì káàkiri àgbáyé bíi èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń sọ ní ìwọ̀ oòrùn Africa, Japan, South Africa àti Malta.
Lára àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tó wọ ìwé atúmọ̀ èdè náà láti Nàìjíríà ni nyash," "mammy market," "amala," "moi moi," "abeg," "biko," àti "Ghana Must Go."
Bákan náà ni "Afrobeats" tó túmọ̀ sí orin ìwọ̀ oòrùn Africa àti àpapọ̀ jazz àti sóòlù.
Báyìí ni ìwé atúmọ̀ náà ṣe júwe àwọn ọ̀rọ̀ tuntun náà:
- Abeg - ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi máa ń ṣàfihàn ìmọ̀lára bíi tí nǹkan bá ya èèyàn lẹ́nu, kí èèyàn má gba nǹkan gbọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
- Biko – tó jẹ́ ọ̀rọ̀ láti inú èdè Igbo ni wọ́n túmọ̀ sí ẹ̀bẹ̀ tàbí kí èèyàn gba nǹkan gbọ́ tàbí kí èèyàn fi bèèrè ohun kan ní pàjáwìrì
- Nyash – èyí túmọ̀ sí ìdí pàápàá ìdí obìnrin, ẹ̀yìn.
- Ghana Must Go – èyí ni ìwé atúmọ̀ yìí túmọ̀ sí báàgì ńlá èyí tí wọ́n máa ń lò ní ìwọ̀ oòrùn Africa tí wọ́n le tọpinpin orírun rẹ̀ sí ọdún 1983 nígbà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ní káwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana fi Nàìjíríà sílẹ̀. Ó túmọ̀ sí báàgì ńlá tó ní ohun tí wọ́n ń wọ́ láti fi tì í pẹ̀lú àwọ̀ oríṣiríṣi tí èèyàn fi máa ń kó ẹrù.
- Mammy market – mammy market túmọ̀ sí ọjà táwọn obìnrin máa ń ṣe àkóso rẹ̀ ní ibùgbé àwọn ológun èyí tó ti wà láwọn ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn agùnbánirọ̀ báyìí.
- Àmàlà – Oúnjẹ tí wọ́n máa ń fi èlùbọ́ iṣu, ẹ̀gẹ́ tàbí ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú ṣe. Ìwé atúmọ̀ èdè náà júwe àmàlà bíi oúnjẹ tí wọ́n ń ṣe sí róbóróbó tí wọ́n máa ń fi onírúurú ọbẹ̀ jẹ.
- Moimoi – ìwé atúmọ̀ èdè náà júwe rẹ̀ bíi óunjẹ tí orírun rẹ̀ jẹ́ ìran Yorùbá, wọ́n máa ń fi ẹ̀wà tí wọ́n lọ̀ papọ̀ mọ́ ata, àlùbọ́sà àtàwọn nǹkan míì sè.
Nínú oṣù Kìíní, ọdún 2025, àwọn ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà ogún ló wọ ìwé atúmọ̀ èdè Oxford English Dictionary, èyí tó ń ṣàfihàn bí àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí Nàìjíríà àtàwọn ọ̀rọ̀ míì ṣe ń nípa káàkiri àgbáyé.
Lára àwọn ọ̀rọ̀ tó wọ ìwé atúmọ̀ nígbà náà ni japa, agbero, eba, 419, abi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.














