Báyìí ni ètò ìsìnkú Sina Ghami àti Latif Ayodele tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìjàmbá ọkọ̀ pẹ̀lú Anthony Joshua yóò ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, Social media
Ètò ìsìnkú fún Sina Ghami àti Abdul Latif Kevin Ayodele, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká akànṣẹ́gbayì, Anthony Joshua ni wọ́n ti kéde pé ó máa wáyé lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kìín, ọdún 2026.
Àtẹ̀jáde kan tí Boxing King Media fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta sọ pé aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ni ètò ìsínkù ọ̀hún máa bẹ̀rẹ̀ ní mọ́ṣáláṣí ńlá London Central Mosque, 146 Park Road, London NW8 7RG.
Ṣáájú ni wọ́n ti gbé òkú Sina Ghami àti Latif Ayodele ránṣẹ́ sí United Kingdom lẹ́yìn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2025.
Ètò ìsìnkú náà ni ìgbàgbọ́ wà pé yóò mú kí àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àtàwọn olólùfẹ́ eré ìdárayá ẹ̀ṣẹ́ kíkàn láti ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún wọn.
Iléeṣẹ́ ìròyìn Boxing King Media sọ pé àwọn ń fi àdúrà ránṣẹ́ sáwọn ẹbí àtàwọn olólùfẹ́ àwọn èèyàn náà.

Oríṣun àwòrán, Boxing King Media
Kókó ẹ̀sùn mẹ́rin tí wọ́n fi kan awakọ̀ Anthony Joshua nílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣalaye koko ẹsun mẹrin ti wọn fi kan awakọ Lexus SUV ti Anthony Joshua atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ meji wa ninu rẹ, eyi to ni ijamba lọna marosẹ ilu Eko si Ibadan lọjọ Aje ọsẹ yii.
Lonii ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 ni awakọ naa, Adeniyi Kayode, foju ba ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Sagamu nipinlẹ Ogun.
Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan awakọ naa ni pe o wa ọkọ lọna to lewu eyi to ṣokunfa iku awọn eeyan.
Eleyii ni igbimọ olupẹjọ sọ pe o tako abala 5(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.
Ẹsun keji ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode ni ẹsun aibikita ati wiwa ọkọ ni iwakuwa eyi to lodi sofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.
Wiwa ọkọ lai na-an ni nnkan to le ṣẹlẹ lẹsun kẹta ti wọn fi kan Ọgbẹni Kayode, ati pe wọn lo tun ṣakoba fawọn to wa ninu ọkọ naa ti wọn fi farapa.
Labẹ ẹsun yii kan naa ni wọn tun ti sọ pe awakọ naa ba dukia jẹ eyi to lodi si abala 7(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ ti ọdun 2004.
Ẹsun kẹrin ti wọn fi kan awakọ Anthony Joshua ni pe o n wa ọkọ lai ni iwe ẹri iwakọ to yanranti lọwọ, eyi to lodi abala 10(1) ofin ọna marosẹ ijọba apapọ.
Lẹyin o rẹyin, ile ẹjọ fun awakọ naa ni beeli pẹlu miliọnu marun un naira (N5m) ati oniduro meji.
Ile ẹjọ ni Ọgbẹni Kayode yoo wa ni ahamọ titi ti yoo fi pese nnkan ti ile ẹjọ ni ko san fun beeli rẹ.
Ogunjọ oṣu Kinni yii ni igbẹjọ yoo tun waye.
Adeniyi Kayode, awakọ̀ tó wa ọkọ̀ Anthony Joshua tó ní ìjàmbá níbi téèyàn méjì ti kú ti fojú ba ilé ẹjọ́
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe awakọ to wa ọkọ Lexus SUV ti Anthony Joshua atawọn alabaṣiṣẹpọ rẹ wa ninu rẹ, eyi to ni ijamba nibi ti eeyan meji ti ku ti foju ba ile ẹjọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi, sọ pe Ọgbẹni Adeniyi Mobolaji Kayode foju ba ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Sagamu lonii ọjọ Ẹti ọjọ keji oṣu Kinni ọdun 2026 yii.
DSP Babaseyi sọ loju opo Facebook rẹ pe ile ẹjọ ti sun igbẹjọ Kayode ẹni ọdun mẹrindinlaadọta siwaju si ogunjọ oṣu yii.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọgbẹni Kayode ni Eleweeran niluu Abeokuta lanaa ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun.
Ọpọ eeyan lo ti n beere nipa awakọ to wa ọkọ naa lati igba ti ijamba naa ti ṣẹlẹ ti Joshua si n gba itọju nile iwosan.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Àwakọ tó wa ọkọ̀ Anthony Joshua wà níàhámọ́, ó ṣeéṣé kó fojú ba ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Othrs/getty images
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, ṣalaye pe wọn mu awakọ naa si ahamọ gẹgẹ bi ara ilana fun iwadi ati pe o ṣeeṣe ki wọn faa lọ sile ẹjọ.
Lọjọru ni iroyin jade pe Ilumọọka akanṣẹgbayii ni, Anthony Joshua ti fi ile iwosan silẹ lẹyin to kagbako ijamba mọto eyi to gb'ẹmi awọn ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ rẹ meji lọjọ Aje.
Bakannaa, l'awọn alaṣẹ sọ pe eto n waye lati gbe oku awọn ọrẹ rẹ mejeeji, Latif Ayodele 'Latz' ati Sina Ghami, to ku ninu ijamba ọkọ naa.
Anthony Joshua kúrò níléèwòsàn lẹ́yìn tórí kóoyọ nínú ìjàmbá mọ́tò tó gbẹ̀mí ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì

Oríṣun àwòrán, Anthony Joshua/x
Ilumọọka akanṣẹgbayii ni, Anthony Joshua ti fi ile iwosan silẹ lẹyin to kagbako ijamba mọto eyi to gb'ẹmi awọn ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ rẹ meji lọjọ Aje.
Awọn dokita da Anthony Joshua silẹ pe o le maa lọ sile lọjọru lẹyin ti wọn gbe e digbadigba lati ibi ijamba naa lopopona marosẹ Eko si Ibadan fun itọju.
Awọn dokita ṣalaye pe yoo tẹsiwaju pẹlu itọju to n gba ni ile ati pe ilera rẹ ti ṣe deede to bayii.
Bakannaa, l'awọn alaṣẹ sọ pe inu gbajugbaja akanṣẹgbayii naa bajẹ pupọ nipa iṣẹlẹ iku awọn ọrẹ rẹ meji, Latif Ayodele 'Latz' ati Sina Ghami ti wọn ku ninu ijamba ọkọ mọto naa.
Ijọba ipinlẹ Eko ati Ogun ti ba awọn mọlẹbi awọn mejeeji to doloogbe ninu ijamba mọto naa kẹdun.
Bakan naa ni wọn fi kun un pe Anthony Joshua ati iya rẹ ṣe abẹwo si ile igbokupamọsi ti oku awọn ọrẹ rẹ mejeeji wa lati ṣe ọwọ ikẹyin fun wọn, ni imurasilẹ fun gbigbe oku wọn pada.
Ta ni Sina Ghami àti Latif Ayodele, àwọn ọmọ ikọ̀ Anthony Joshua to kú nínú ìjàmbá ọkọ̀?

Oríṣun àwòrán, social media
Ni ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọ̀n oṣu kejila ọdun 2025 ni gbajumọ akanṣẹgbayi, Anthony Joshua atawọn ikọ rẹ ni opopona marosẹ Eko si Ibadan eleyi to gbẹmi awọn meji lara awọn ikọ to n baa ṣiṣẹ.
Awọn ọrẹ ati alabaṣiṣẹ rẹ meji to padanu ẹmi wọn ni Sina Ghami ati Latif Ayodele ti ọpọ tun mọ si Latz.
Ileeṣẹ to n ṣe agbatẹru fun Anthony Joshua, Matchroom lo kede orukọ awọn mejeeji yii ninu atẹjade ibanikẹdun ti wọn fi sita lori ayelujara.
Alaga ileeṣẹ Matchroom, Eddie Hearn sọ̀ pe: ''Pẹlu iporuru ọkan. Awọn ogbontagi meji. Sunre o o Sina ati Latz. Ero mi pẹlu adura mi wa pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan.''
Agbẹnusọ kan fun Joshua sọ pe Ghami ati Ayọdele jẹ ọkan pataki lara ikọ akanṣẹgbayi naa, ati pe iroyin iku wọn "bani lọkan jẹ pupọ".
Ta ni Sina Ghami?

Oríṣun àwòrán, Sina Ghami/instgram
Ghami ni akọnimọẹṣẹkan fun Anthony Joshua, o si ti le lọdun mẹwaa to ti wa pẹlu Anthony Joshua.
O si jẹ gboogi ninu awọn igbaradi Anthony Joshua fun awọn ija ẹṣẹ kikan to jẹ gboogi ninu irinajo iṣẹ rẹ gẹgẹbi akanṣẹgbayi ninu eyi ti a ti ri ija oun pẹlu Wladimir Klitschko lọdun 2017 ati ija rẹ pẹlu Jake Paul laipẹ yii.
Ta ni Latif Ayodele 'Latz'?

Oríṣun àwòrán, Snapshot
Ayọdele jẹ ọkan lara awọn ọrẹ pẹkipẹki fun Anthony Joshua. Ni wakati diẹ ṣaaju iṣẹlẹ ijamba ọkọto mu ẹmi oun ati Ghami, akọnimọẹṣẹkan Joshua lọ ni Anthony Joshua ṣi fi fidio ibi ti awọn mejeeji ti n ṣe ere idaraya Table tennis pẹlu Ayọdele to tun jẹ olukọ rẹ.
Pẹlu awọn ọrọ idaro tawọn to sun mọ wọn n sọ, eeyan to jẹ korikosun Anthony Joshua ni Ayọdele ti ọpọ tun mọ si Latz, ti iku rẹ yoo si fa ọpọlọpọ ọgbẹ ọkan ti ko ṣe e wosan ni kiakia fun Anthony Joshua.














