Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti wọ ọdún 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kìí ṣe ohun tuntun mọ́ pé wákàtí díẹ̀ ló kú ki a wọ ọdún 2026 tí a ó sì máa ju ọwọ́ òdìgbà sí ọdún 2025 káàkiri àgbáyé.
Àmọ́ nígbà tí àwọn tó wà ní àwọn orílẹ-èdè bíi Naijiria, yoo fi máa kí ara wọn kú àmójúbà ọdún tuntun ní òru Ọjọ́bọ̀, ti ń ṣe ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 2026, kò ní jẹ́ ohun tuntun mọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn orílẹ̀-èdè kan yóò ti rí ọdún 2026 nígbà ti Nàìjíríà bá ṣì wà ní ọdún 2025 lọ́jọ́bọ̀ tí ọdún ń parí.
Àwọn orílẹ̀-èdè tó ti wọ 2025
1. Ìlú Kiritimati tí wọ́n tún n pè ní 'Christmas Island', erékùsù tó wà ní ààrin gbùngbùn Pacific Ocean ló kọ́kọ́ máa kí ọdún 2026 káàbọ̀ l'ágbàáyé, bí wọ́n ṣe ti gba àlejò ọdún tuntun náà lásìkò tí àwa bá ṣì wà ní aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́rú.
2. Lẹ́yìn náà ni Chattam Islands ní orílẹ̀ èdè New Zealand náà tẹ̀le nígbà tí àwọn ṣe mójúba ọdún 2026 ní aago mọ́kànlá òwúrọ̀ kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún.
3. Nígbà tó fi máa di aago méjìlá ọ̀sán ti wa níbi ni ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tó wà ní orílẹ̀-èdè New Zealand yàtọ̀ sí Tokelau, Samoa àti Tonga ti wọ ọdún 2026.
4. Bákan náà ni ìlú Fiji, tó jẹ́ ìlú kéréje kan ní ìlà oòrùn orílẹ̀ ède Russia gbàlejò ọdún 2026 ní aago kan ọ̀sán ọjọ́rú ní Nàìjíríà.
5. Aago méjì ọ̀sán ọjọ́rú ní Nàìjíríà ni ọ̀pọ̀ ìlú ní orílẹ̀-èdè Australia tó fi mọ́ Melbourne àti Sydney àtàwọn ibòmíràn bíi Vanuatu, Bougainville ní Papua New Guinea kí 2026 káàbọ̀.
Àwọn ìlú tí yòó tún wọ 2026 lọ́jọ́rú
8:30 a.m. ET àwọn agbègbe kan ní Australia, tó fi mọ́ Adelaide
9 a.m. ET Queensland ní Australia, àti àwọn ìlú míì bíi Micronesia, the Northern Mariana Islands, díẹ̀ lára Antarctica, àti Guam máa wọ 2026.
9:30 a.m. ET Australia's Northern Territory
10 a.m. ET Japan, South Korea, díẹ̀ lára Russia, North Korea, díẹ̀ lára Indonesia, Timor-Leste, ati Palau
10:15 a.m. ET Western Australia
11 a.m. ET China, Philippines, Malaysia, díẹ̀ lára Indonesia, ọ̀pọ̀ agbègbè ní Mongolia, Taiwan, Brunei, Russia's Irkutsk region, àwọn ibì kan ní Antarctica, Hong Kong, Singapore, àti Macao
Indonesia, Thailand, Vietnam, Cambodia, Laos, àtàwọn ibì kan ní Russia, Mongolia, Antarctica, àti Christmas Island ní Australia máa wọ ọdún 2026 nígbà tí Nàìjíríà bá ṣì wà ní ọdún 2025/
ET túmọ̀ sí Eastern Time - aago náà fi wákàtí mẹ́fà sáàjú Naijiria














