Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà àti olórin tó kú ní 2025

Oríṣun àwòrán, Facebook
Nigba ti ọdun 2025 bẹrẹ, kaluku to ṣoju rẹ ni wọn ki ọdun tuntun naa ku aabọ, ṣugbọn ko sẹni to mọ ọdun aṣegbẹyin,gbogbo ẹni to ki ọdun naa kaabọ kọ lo ṣẹku saye loni mọ.
Ko wu awọn ti ko si laye mọ naa lati lọ, amọ asiko lo to fun wọn lati san gbese ti gbogbo ẹni to ba wa saye maa n jẹ, iyẹn naa si ni iku.
Iku ṣoro lẹka ọtọọtọ, ẹni to kan lo le sọ ni.
Lẹka awọn amuludun lorilẹede Naijiria, iku mu awọn eeyan kan lọ ni 2025 yii, eyi si ni iroyin yii yanna-na rẹ bi wọn ṣe ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn onitiata, sọrọsọrọ ori ayelujara to ku ni 2025
- Asakoko:
Ọgbọnjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni agba oṣere tiata Yoruba tawọn eeyan mọ si Asakoko, jade laye.
Nnkan bii ọdun meji ni ọkunrin naa fi dubulẹ aisan, ki ọlọjọ to de ni 2025.
Ọkan lara awọn oṣere ti awọn eeyan ko gbọ nipa rẹ fun ọdun pipẹ ni Asakoko.
- Pat Ugwu: Oṣere tiata to jẹ ẹya Igbo ni obinrin yii, ẹni ọdun marundinlogoji (35) pere ni nigba to dagbere faye lọjọ karun-un oṣu Keji ọdun 2025.
Oṣu kẹfa lẹyin ti Pat Ugwu sinku baba rẹ ni oun naa jade laye, wọn si sin in lọjọ keje oṣu Keji ọdun 2025.
- Rotimi Raji: Adari ere ni ọkunrin yii nigba aye rẹ. Inu baluwẹ rẹ lo ti ṣubu lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Keji ọdun 2025. Ọjọ keji ni awọn araale si too mọ pe Rotimi Raji tawọn eeyan mọ si Genius ti ku.
- Olaoluwa Dare Lawal: Ọdọmọde onitiata yii ri sinu odo lasiko to n ya iṣẹ kan lọwọ alẹ nipinlẹ Ogun.Ọjọ Abamẹta, ọgbọnjọ oṣu Karun-un ọdun 2025 ni iṣẹlẹ aburu naa waye, ọpọ awọn onitiata Yoruba lo si daro ọmọdekunrin naa, wọn ni iku to ṣee dena lo pa Dare.
- Monalisa Stephen: Ọkan lara awọn eeyan ti Ọlọrun fun ni ẹbun ara sisan ni Oloogbe Monalisa Stephen, awọn kan maa n fi bo ṣe sanra naa bu u lori ayelujara, eyi to jẹ ko maa kede lodi si iru ọrọ bẹẹ.Karun-un ọdun 2025. Ọhun ti a gbọ pe o fa iku naa ni pe ṣuga ara rẹ kere si bo ṣe yẹ ko to, bẹẹ lo si tun n ṣe ẹjẹ lati inu lai han jade (Internal bleeding).
Omotola Odunsi:
Oṣerebinrin to ṣẹṣẹ n goke agba lagbo tiata ni ọmọbinrin yii, o ti ṣiṣẹ lẹka ifowopamọ ko too wọ tiata ni 2018, nigba to darapọ mọ agba oṣere, Odunlade Adekola.
Aisan ranpẹ to tilẹ ti n lọ lara rẹ lo pada mu Omotola Odunsi tawọn eeyan mọ si Motola the Actor, lọ lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025.
- Kayode Peters:
Oṣere tiata to tun maa n dari ere ni Oloogbe Kayode Peters nigba aye rẹ.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa ọdun 2025 lo dagbere faye ni Toronto, orilẹede Canada.
Aisan ọlọdun pipẹ ni wọn lo ṣe Kayode, ẹni ọdun mọkandinlaadọta (49) ni I ṣe ti ọlọjọ fi de.
- Tolani Akintunde:Oṣere to kopa ninu ere agbelewo kan, 'Everyday people' ni Tolani Akintunde. O gbajumọ daadaa nipasẹ ere naa ko too fi Naijiria silẹ lọ si UK. Ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Karun-un ọdun 2025 ni ọkan oṣere yii daṣẹ silẹ, o si dagbere faye.
- Chief Kanran: Oloogbe Segun Remi, agba oṣere tawọn eeyan mọ si Chief Kanran, ku lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2025. Gbajumọ oṣere to maa n kopa olowo ninu ere ni Oloye Kanran, o koju iṣoro oriṣiiriṣii lawọn asiko kan, ko si fi bẹẹ kopa ninu fiimu mọ ki ọlọjọ too de lẹni ọdun mejilelaadọrin (72).
- Sanku: Orukọ ọmọdekunrin to maa n ṣe ẹfẹ lori ayelujara yii gan-an ni Raji Samad Adetola, ṣugbọn Sanku ni ọpọ eeyan mọ ọn si.Ọjọ Aje, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 ni Sanku n ku inu ijamba ọkọ to ni loju ọna Ogbomoso-Oyo. Ọmọ ilu Osogbo ni Sanku , ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) ni nigba to ṣe alaisi.
- Ayomikun Oluwanisola Omobolanle: Gbajumọ oṣerebinrin, Peju Ogunmola Omobolanle lo bi Oloogbe Ayomikun, ọmọ kan ṣoṣo ti oṣere yii bi fun ọkọ rẹ, Sunday Omobolanle, (Aluwe) naa ree.Ayomikun ku lọjọ keji, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025. Bo tilẹ jẹ pe awọn kan sọ pe o ṣubu ni ile iwẹ ni, awọn ẹbi rẹ pada kede pe Ayomikun tawọn mi-in tun mọ Shina, ku lẹyin aisan ranpẹ ni.
Awọn olorin

- Akin Shuga (Akinloye Tofowomo), olorin ẹmi ni ọkunrin yii oun ni oludasilẹ Shuga Band.
O jade laye ni Canada ni ọgbọnjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2025. Ẹni aadọta ọdun ni Akin Shuga.
- Big Bolaji: Olorin ẹmi loun naa, Bolaji Adedotun Olanrewaju gan-an ni orukọ rẹ. O si jẹ pasitọ ninu ijọ RCCG, bẹẹ lo maa n gbe ohun safẹfẹ.
Big Bolaji jade laye lọjọ ọdun Ajinde, ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹrin ọdun 2025, lẹyin aisan ranpẹ.
- Toluwalope Adegboyega (Flora):
Ọkan lara awọn oṣere ẹgbẹ Mount Zion, ti Pasitọ Mike Bamiloye n dari ni obinrin yii.
Oṣu Kejila ọdun 2024 lo ni ijamba ọkọ, o si ku lọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun 2025.
Gbajumọ oṣere ninu ere kan ti wọn pe ni Abbatoir ni Toluwalope Adegboyega















