"Òbí mi gbé mi sálọ sílé ọkọ tí ń kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ a ti lo ọdún 48 pọ̀ nínú ìgbéyàwó, ojú rí tó"
Ni ilẹ Yoruba, igbeyawo jẹ ọkan lara awọn aṣa ti ko ṣe fọwọ rọ ti sẹyin, to si ni ilana ọlọkan-o-jọkan ti ilu tabi ẹbi kọọkan n lo.
Yatọ si ilana ifojusode wa iyawo fun ọmọkunrin, ti alarina yoo yanju rẹ nigba to ba ti fi ọkunrin ati obinrin naa han ara wọn, ilana kan wa laye ọjọun ti wọn n lo lati fi gbe iyawo lọ sile ọkọ rẹ, bi ko tilẹ tẹ iyawo naa lọrun rara.
Iru ilana igbeyawo naa ni wọn n pe ni Asante, iru rẹ ni tọkọtaya Amos Gbolagade ati Maria Adejinmi ṣe lọjọ Keje, oṣu Keje ọdun 1977.
Nigba ti wọn n ba BBC News Yoruba sọrọ, tọkọtaya naa sọ pe sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko mọ ara awọn ri tẹlẹ, ti Maria ko si gba lati fẹ Amos, sibẹ, awọn obi Maria ṣeto pẹlu awọn ẹgbọn rẹ, wọn si gbe e lọ sile ọkọ rẹ ti wọn fẹ ko fẹ, iyẹn Gbolagade.
Awọn tọkọtaya naa ṣalaye bi igbeyawo ọhun ṣe ri, ati bi wọn ṣe n ba a bọ lati ọdun mejidinlaadọta (48) sẹyin.

Ki ni igbeyawo Asante, bawo ni igbeyawo Maria ati Gbolagade ṣe waye?
Nigba ti Alagba Gbolagade Adejinmi n ṣalaye igbeyawo Asante, o ni:
''Igbeyawo Asante wa laaarin obi ọkọ ati iyawo, ti won ba ti ri i pe ọmọ awọn ti fẹ lọ fẹ ẹlomi-in, wọn o ni fẹ ba ẹbi wọn jẹ.
Iyẹn ni won a fi ṣeto lati mu iyawo wa sile baba ọkọ, oju ẹsẹ to ba si ti dele naa ni wọn yoo ṣeto lati lọ sanwo ori fawọn obi ẹ."
O ni nigba toun ri Maria, toun si ti beere ti wọn ni awọn ki i ṣe mọlẹbi, ẹsẹkẹsẹ loun ti ba awọn obi oun sọ pe oun nifẹẹ rẹ, bi won ṣe yanju rẹ silẹ foun niyẹn bo tilẹ jẹ pe ilu Eko loun wa.
Gbolagade sọ pe wọn pe oun lati maa bọ nile ni, pe iyawo oun ti wa nile.
O ni bo si tilẹ jẹ pe o ṣe agidi gẹgẹ bii obinrin, oun lo ti ọkunrin fun un, awọn si n ba a bọ latigba naa titi di oni.
Ṣaa, baba to ti le laaadọrin ọdun naa sọ pe ilana ọhun ki i ṣe ohun ti oun le fi ọwọ si bayii, o ni bi eeyan ba ṣe iru rẹ pẹlu ọmọ oun obinrin, ijinigbe loun yoo ka a si.
Bakan naa ni Maria naa si ṣalaye, o ni oun ti ni ẹni to oun fẹ nigba ti oun wa lọmọge, iyẹn ọmọ baba onile toun n gbe.
Ṣadeede lo ni wọn pe oun pe oun yoo ni lati fẹ Gbolagade to wa l'Ekoo, nigba toun wa n'Ibadan.
Maria ni bi ere lọrọ naa jọ loju oun, afi bi awọn ẹgbọn oun, pẹlu ifọwọsowọpọ awọn obi oun ṣe ni ni ile ọkọ ya, bẹẹ ni wọn si ṣe gbe oun lọ sile Gbolagade lọwọ irọlẹ, toun di iyawo rẹ bi ko tilẹ tẹ oun lọrun nigba naa.
"Igbeyawo Asante ni mo ṣe loootọ, ṣugbọn ti eeyan ba ji ọmo mi gbe lasiko yii, to ni oun n ṣe Asante, wahala lo gbe o.''
Bẹẹ ni mama naa wi.
O ṣalaye pe ifarada ati aforiti loun fi gbele ọkọ oun di asiko yii, bẹẹ ni baba naa sọ pe igbeyawo ki i ṣe nnkan ẹ̀fẹ̀, o si gba ki tọkọtaya sọwọpọ ko too le gba oju ọwọ.


