Remi Tinubu ati Adeleke fèsì lórí ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé n'Ile Ife

Èsì ti de lori Iṣẹlẹ kan to ṣẹ nibi ayẹyẹ ọdun kẹwaa igbade Ọọni Ile Ife, Oba Enitan Ogunwusi laipẹ yii.
Ẹ o ranti pe iyawo aarẹ ilẹ wa, Oluremi Tinubu, lo ni oun fun Gomina ipinlẹ naa, Ademola Adeleke, ni iṣẹju marun-un lati sọrọ, ko si dakẹ orin to n kọ nita gbangba.
Latilẹ ni awọn eeyan ti mọ Gomina Ademola Adeleke fun ijo jijo, nigba to si tun bẹrẹ orin nibi ayẹyẹ Ọọni, ko jọ ẹnikẹni loju.
Ṣugbọn nigba ti ariwo ọrọ ti Remi Tinubu sọ si I naa ko dakẹ lori ayelujara, ti ọpọ eeyan n sọ pe iyawo aarẹ ko lẹtọọ lati sọrọ bẹẹ si odidi gomina ipinlẹ to gba a lalejo, ni Remi Tinubu fesi.
Bo si tilẹ jẹ pe Gomina Adeleke ko binu lọjọ naa, to ṣe bi iyawo aarẹ ṣe fẹ, oun naa ti pada mu esi wa si ohun ti ọpọ eeyan ka si abuku ọhun.
Ninu alaye Adeleke lasiko to n sọrọ lori tẹlifiṣan Channels l'Ojoru ana, nipa iṣẹlẹ naa lo ti ni:
Kò yẹ kí ẹ bu mi nitori ohun to ṣẹlẹ laaarin emi ati Adeleke- Remi Tinubu
Lati ṣalaye oju to fi wo ọrọ ti awọn eeyan n sọ si lori ohun to sọ fun Adeleke nita gbangba, Remi Tinubu ti sọ pe ko yẹ ki ẹnikẹni bu oun lori rẹ rara.
Ninu ọrọ kan to kọ si oju op Facebook rẹ lọjọ Iṣẹgun, Iyawo Aarẹ sọ pe awọn eeyan fẹran ki wọn maa sọ ohun ti ko to nnkan di nla.
Remi Tinubu kọ ọ sibẹ pe:
" Awọn eeyan ti wọn gba iṣẹ idari ti mọ ojuṣe wọn, ati bi wọn yoo ṣe ṣe ọrọ to ba kan awujọ.
" Ọpọ igba lo jẹ pe awọn araalu ati awọn to n wa aleebu eeyan lo maa n fẹ ohun ti ko to nnkan loju, wọn yoo si sọ ọ di awuyewuye ti ko tiẹ yẹ ko waye. Ọṣun lè tèǹtẹ̀".
Ọrọ ti iyawo aarẹ fi lede yii lo waye bi esi fun awọn eeyan to n koro oju si bo ṣe ba Gomina Osun sọrọ.
Ẹ o ranti pe yatọ si awon araalu to n gbe ọrọ naa kiri, Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Gomina Adeleke, Akintunde Bello, naa bu ẹnu atẹ lu iwa Remi Tinubu.
O ni ko yẹ ko ri bẹẹ, o si yẹ ki wọn pe mama naa si akiyesi.
Bakan naa ni Dele Momodu toun naa jẹ oloṣelu, ṣapejuwe ọrọ iyawo aarẹ bii ikonilayajẹ, o ni Remi Tinubu doju ti gomina nibi ayẹyẹ ọlọpọ ero.
'Ko sohun to le ni ki n ma jo, ijo ti mo n jo ko di iṣẹ mi lọwọ'
Ninu alaye rẹ, Adeleke to ti n jo latigba to ti wa nipo Sẹnetọ, to si ṣe bẹẹ gba inagije 'Sẹnetọ onijo', sọ pe:
"Jẹ ki n sọ nnkan kan fun ẹ, emi a maa jo lọ ni, nitori mo fẹran ijo jijo gan-an, mo fẹran ki n maa yin Ọlọrun mi. Iyẹn ko yi ohunkohun pada.
"Kaluku lo ni ọna ti wọn n gba ṣere tabi to jẹ ohun ti wọn fẹran. Temi ni ijo jijo ati yinyin Ọlorun mi, iyẹn ko pa iṣẹ mi lara."
Bẹẹ ni Gomina Adeleke wi.
"Oluremi Tinubu bá Gomina Adeleke wí bí ìyá ṣe ń bọ́mọ wí ni, ìwà wèrè ni wọ́n fi ń wo wèrè ni aya ààrẹ hù sí gómìnà"

Awuyewuye si n lọ lori ohun to ṣẹlẹ laarin Gomina Ademola Adeleke ati Aya Aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu, nibi ayẹyẹ ọdun mẹwaa ti Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, gori itẹ baba rẹ niluu Ile Ife lopin ọsẹ to kọja.
Fidio kan, eyi ti BBC News Yoruba ka silẹ nibi ayẹyẹ ọdun mẹwa Ọọni naa, amọ to ti lu ori ayelujara pa bayii, ti ṣafihan bi Sẹnẹtọ Oluremi ṣe lọ ba Gomina wi pe ko dẹkun orin kikọ, wi pe ko sọrọ apilẹkọ to fẹ sọ nibi ayẹyẹ naa.
Aya aarẹ, ti Ooni fi oye Yeye Aṣiwaju Gbogbo Ilẹ Oodua da lọla nibi ayẹyẹ naa tun lọ ba gomina fun igba keji wi pe, ko sọrọ to ba fẹ sọ pe orin to kọ ti to.
Nigba naa ti Sẹnẹtọ Oluremi sọ pe ''orin ti ẹ kọ ti to, bi bẹẹ kọọ maa ni ki wọn pa ẹrọ gbohungbohun o, mo fun yin ni iṣẹju marun un lati sọrọ ti ẹ ba fẹ sọ.''
Ọrọ ti aya aarẹ sọ pa awọn kan lẹrin in ninu awọn to wa nibi eto naa, nigba ti o jẹ iyalẹnu fawọn mii to wa nibẹ.
Lati igba ti fọnran nnkan to ṣẹlẹ ti de ori ayelujara lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa rẹ.
Bi awọn kan ti n sọ pe ere ni aya aarẹ n ba gomina ṣe, lawọn mii n sọ pe iwa ti Sẹnẹtọ Oluremi hu kudiẹ kaato.
''Ohun to ṣẹlẹ laaarin Gomina Adeleke Osun ati Aya Aarẹ Oluremi Tinubu ju ọrọ ofin lọ''
Ẹwẹ, Agbẹjọro agba Yomi Aliu (SAN) sọ pe nnkan to ṣẹlẹ laarin Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun ati aya Aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu ni Ile Ife ju ọrọ ofin lasan lọ.
Agbẹjọro Aliu ṣalaye pe ''ti a bo wo o lati ibẹrẹ, Gomina Adeleke ati Rauf Aregbesola toun naa jẹ gomina ana nipinlẹ Osun ti jọ lẹdi apo ṣaaju akoko yii, ti awọn mejeeji si jo takubu Aarẹ Bola Tinubu.
Bakan naa, nigba ti Adeleke gba ipo lọwọ Gboyega Oyetola to jẹ ibatan Tinubu, ko si nnkan ti Adeleke ko fi Oyetola we tan.
Gbogbo ọba atawọn eeyan ti Oyetola yan sipo ni Adeleke yọ loye pata pata.
Adeleke ko fi bo rara wi pe ọta loun n ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC.''
''Were ni wọn fi n wo were ni Oluremi ṣe fun Gomina ipinlẹ Osun''
Agbẹjọro agba Aliu sọ pe ''were ni wọn fi n wo were ni Sẹnẹtọ Oluremi ṣe fun Gomina Adeleke nibi to ti n kọrin.
Amofin agba naa sọ pe ode olode ni Adeleke ti lọ n kọrin to ni ṣe pẹlu ara rẹ, eyi to jẹ ki aya aarẹ lọ ba a wi pe oun loun lode.
O ni ara aya aarẹ ko le gba a mọ bi gomina ipinlẹ Osun ṣe n kọrin idupẹ lori nnkan ti Ọlọrun ṣe fun un ninu oṣelu, lo jẹ ko lọ ba a wi pe ko sọrọ to ba fẹ sọ pe ko si ye kọrin mọ.
Agbẹjọro Aliu ni Oluremi kọkọ sọ fun Ooni ko to lọ ba Adeleke nibi to ti n kọrin.
Aliu ni Ooni ko lagbara lati lọ sọ fun gomina pe ko ma kọrin mọ, iyẹn lo jẹ ki aya aarẹ lọ sọ fun un funra rẹ.
''Ti a ba tun foju ofin wo o, Gomina Adeleke lo nilẹ, oun lo ni ipinlẹ Osun, koda, o le yọ ọba nipo.
Amọ, wọn fiwe pe Gomina Adeleke sibi ayẹyẹ ọdun mẹwaa Ooni lori itẹ ni, kii ṣe iṣẹ ijọba lo lọ ṣe nibẹ.
Ka ni pe Tinubu wa nibi ayẹyẹ ọhun ni, aarẹ ati iyawo rẹ ni wọn maa kọkọ pe ki wọn to pe ẹlomiran nibi ayẹyẹ naa ṣaaju ẹnikẹni.
Ofin Naijiria sọ pe ti ofin ipinlẹ ba tako ofin orilẹede Naijiria, ofin ipinlẹ lo maa tẹ,'' amofin Aliu lo sọ bẹẹ.
Agbẹjọro agba naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe o yẹ ki aya aarẹ naa gbe nnkan to ṣe gba ọna ibomiran.
O sọ pe ''aya aarẹ ko dide gẹgẹ bii Remi Tinubu, amọ, o dide gẹgẹ bii aya aarẹ pẹlu gbogbo agbara ti Tinubu ni.
Loootọ ni ọfiisi aya aarẹ ko si ninu iwe ofin Naijiria, ṣugbọn ọrọ aṣa ni gomina ba lọ sibi ayẹyẹ ọdun mẹwaa Ooni lori oye.
Ti a ba wo o bayii, Oluremi dagba ju Adeleke lọ, ati pe o tun ju u lọ pẹlu oye Yeye Aṣiwaju ilẹ Oodua ti Ooni ṣẹsẹ fi jẹ.
''Oluremi ba Adeleke wi bi iya ṣe maa n ba ọmọ wi''
Amofin agba Aliu ni ''Oluremi ba Adeleke wi bi iya ṣe maa n ba ọmọ wi ni.
Ode aya aarẹ ni Adeleke wa nigba naa, ko lẹtọọ lati maa kọrin nipa ara rẹ ni ode olode.
Ko si ọrọ ofin nibi iru ayẹyẹ ti Oluremi ti sọ fun Adeleke wi pe ko dẹkun orin kikọ ko le sọrọ to fẹ sọ.
Oye kọ ni Oluremi Tinubu lọ jẹ ni Ile Ife, ipolongo oṣelu loun ati Adeleke ba lọ ṣe nibẹ.
Ọjọ kẹẹdogun oṣu Kejila yii ni idibo abẹnu yoo waye nipinlẹ Osun, bẹẹ ni idibo gomina naa si n kan lẹkun gbọn gbọn.
Tori naa, eto ipolongo oṣelu lawọn mejeeji ba lọ si Ile Ife, ipolongo ibo lo kọlu ara wọn kii ṣọrọ aṣa ara,'' Agbẹjọro Aliu ṣalaye.
Amofin agba naa sọ pe nnkan to ṣẹlẹ ko pọn awọn mejeeji le, amọ, o ni gomina lo lọ ode olode.
Ẹwẹ, akọwe ìròyìn Gomina ipinlẹ Osun, Rasheed Olawale, sọ fun BBC Yoruba wi pe Sẹnẹtọ Adeleke ko le sọrọ bayii lori iṣẹlẹ to waye ni Ile Ife.















