Agbébọn tún kọlu ilé ìjọ́sìn, wọ́n pa ìyàwó pásítọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀ níná, ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn lèṣe

Àwòrán àwọn ọkọ̀, ọ̀kadà àti ilé ìjọ́sìn táwọn agbébọn náà jó níná

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn agbébọn ṣe ṣèkọlù sí ilé ìjọ́sìn St Andrews Anglican Church, Lilu ní ìjọba ìbílẹ̀ Ihiala níbi tí èèyàn kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Keje, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 lásìkò tí ìjọ́sìn ń lọ lọ́wọ́ ni ìkọlù ọ̀hún wáyé gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra, Tochukwu Ikenga ṣẹ sọ.

Ikenga nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé àwọn agbébọn náà tún ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn léṣe yàtọ̀ sí èèyàn kan tí wọ́n pa, jó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ àti apá kan ilé ìjọ́sìn náà níná.

Nígbà táwọn olùjọ́sìn ń ṣe ìsìn lọ́wọ́ làwọn agbébọn yawọ ṣọ́ọ̀ṣì, sina ìbọn bolẹ̀

Gómìnà Ikenga wòye pé ìkọlù ọ̀hún jẹ́ ìwà ọ̀daràn ńlá sí ìlú náà, ó ní ó jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn náà mọ́lẹ̀ láti ṣe ẹ̀sìn wọn.

Bákan náà ló bá àwọn ẹbí èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn kẹ́dùn, tó fi mọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Lilu lápapọ̀ bó ṣe ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá t bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣàwárí àwọn tó ṣe ìkọlù ọ̀hún, kí wọ́n sì lè fimú wọn jófin.

Ìwádìí ní lásìkò táwọn olùjọ́sìn wà nínú ilé ìjọ́sìn St Andrews Anglican Churchń ṣe ìsìn lọ́wọ́ làwọn agbébọn náà yawọ ibẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiíná ìbọn bolẹ̀.

Èyí mú kí àwọn èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn ṣùgbọ́n àwọn agbébọn náà yìnbọn bá obìnrin kan tí ìgbàgbọ́ wà pé ó jẹ́ ìyàwó àlùfáà ìjọ náà, tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì sì fara gbọta.

Báwo ni ìkọlù náà ṣe wáyé?

Àwọn agbébọn náà kò dúró lórí ìyẹn nìkan, níṣe ni wọ́n tún dáná sun àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi máa ń gbé àwọn èèyàn ilé ìjọ́sìn náà, tí wọ́n sì tún dáná sun ara ṣọ́ọ̀ṣì náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tí ẹnikẹ́ni k]o sì le sọ pé àwọn kan báyìí ló wà nídìí ùkọlù ọ̀hún.

Ìkọlù yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ táwọn èèyàn Lilu ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣán àwọn igbó tó yí ìlú náà ká, táwọn èèyàn sì ń gbìyànjú láti padà sílé wọn lẹ́yìn bíi ọdún mẹ́rin táwọn èèyàn tis á fi ìlú sílẹ̀ látàrí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìlú náà.

Lilu tó kó àwọn ìlú bíi Isseke, Orsu-Ihiteukwa, Awo Idemmiri, Orsu sínú jẹ́ ìlú táwọn èèyàn tis á kúrò níbẹ̀ nígbà tí àwọn tó ní àwọn ń jà fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra máa ń ṣe ìkọlù sí ìlú náà lemọ́lemọ́.

Àmọ́ láìpẹ́ yìí ni àwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí ní tún ojú ọ̀nà tó lọ sínú ìlú náà látàrí pé wọ́n fẹ́ padà sílé wọn kí ìkọlù ọ̀tun yìí tó wáyé.

Ẹni tí ọ̀rọ̀ ṣojú rẹ̀ kan sọ fún àwọn akọ̀ròyìn abẹ́lé pé ó jọ pé pásítọ̀ ìjọ náà ni àwọn agbébọn náà tọpasẹ̀ rẹ̀ wá ṣùgbọ́n tó sá mọ́ wọn lọ́wọ́.

Ó ní òun rò pé ìdí nìyí tí wọ́n fi yìnbọn pa ìyàwó pásítọ̀ náà.