Breast disappearance: Ohun tí kò dára ni láti máa lọ́ ọmú obìnrin

Omo ti wwon di asọ mọ láya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Apere eni ti wọn lọ ọmu fún lasiko ti ẹgbo ba a n jina

O ti wá ṣe pataki báyìí láti fi ẹkọ lílọ ọmu sinu ìwé ìlàna ẹkọ ilé ẹkọ alakọbẹ̀rẹ̀ fun ilanilọyẹ àti láti dènà ìpalára fún awọn ọmọ obinrin.

Ajọ to n ri si ètò ẹkọ ló sọ èyí pé àṣà kí à máa fi Nkan gbigbiona pọn àyà ọmọ obinrin to ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnmú láti maa yọri àti kí ó maa ba wu ọkunrin kii ṣe ohun to dára.

Aṣofin ilẹ̀ Gẹẹsi kan, Nicky Morgan sọ pe ó ṣe pàtàkì láti kọ àwọn olùkọ náà nítori wọn ní ipa pàtàkì láti kó.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network

'kò sí ààye fún ẹkún'

''Kinaya" ni orukọ ẹni ti a fi ọrọ wa lẹnuwo ṣugbọn kii ṣe orukọ rẹ nitootọ bi ko ṣe pe a pààrọ orúkọ rẹ̀ jẹ ẹni to n gbe ni ilẹ Gẹ̀ẹ́sì

Awọn ebí rẹ̀ wá láti ìwọ -oòrun ilẹ Afríkà ní ibi ti àṣà ọmú lílọ tí ṣẹ̀ wá, ò sí jẹ ọkan nínú àwọn ti ó la irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kọjá nígbà ti ó wà ní ọmọ ọdun mẹwàá.

O ní ìyá òun sọ fún òun pé " tí ǹ kò bá lọ ọmu rẹ̀ àwọn ọkunrin yóò bẹrẹ̀ si ni wá ọ wá láti le ba ọ ni àjọṣepọ̀"

Iyá ọmọ náà lo máa ṣe ètò ọmú lílọ yìí nígba ti wọn ba mú òkúta gbigbona tabi ṣíbi gbigbona láti fi lọ ọmu ọmọbinrin náà mọlẹ̀, wọn máà ń ṣe èyí fun bii oṣù kan tàbi jù bẹ ẹlọ

O ṣalaye pe : "ohun máa le gbàgbé ní irú ǹkan báyìí"

"Kódà kò si ààye fún ẹkún sísun." Bí o bá sunkun ó tumọ si pé ó ti mu ìtìjú ba ẹbi náà nìyẹn ati pe O kìí ṣe akọni ọmọbinrin"

eniyan meji ti won keyin
Àkọlé àwòrán, Kinaya àti ọmọ rẹ̀

Ní bayi Kinaya ti dàgbà ó si ti bi ọmọ ara rẹ.

Nígbà ti èyí to dágbà jùlọ pẹ ọmọ ọdun mẹwàá ni ìyá rẹ̀ dàbàá láti ṣe ọmu lilọ fún un.

Mó sọ pé rárá, rárá, rárá, kò si ọkan ninu àwọn ọmọ mi ti yóò la ǹkan ti mo lakọja kọja nítori pe ràbàràba rẹ̀ kò ti kúrò lára mi.

Nítori náà ó kó kuro lọdọ̀ àwọn mọlẹbi rẹ, nítori pe ó ni ìgbàgbọ pe èwu ńla ni ti òun ba si ń gbe pẹ̀lú wọn nítori wọn lẹ lọ ọmu ọmọ oun láì gba aṣẹ.

Kinaya ko ẹyin
Àkọlé àwòrán, Kinaya ni nigba ti oun wa ni omo odun mewaa ni won ti lọ omu òun mọlẹ

Igbàgbọ wà wí pé ó lé ni ọmọ ẹgbẹ́run kan ni wọn ti lọ ọmu fún ni ilẹ Gẹẹsi.

Sùgbọn bi ìlanilọye ṣe ń lọ lóri abẹ dida fún ọmọ obinrin, ó ṣeni láànú pé ènìyàn péréte ló mọ nipa ọmu lílọ nji eyi to yẹ ko ti dohun igbagbe nilẹ Afrika bayii

Àkọlé fídíò, Wọ́n nílò ìrànlawọ́ mi láti ṣèmọ́tótó ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ní Coronavirus