Sunday Igboho: Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹjọ to ti n lọ lati bii oṣu meji laarin ilumọọka ajafẹtọ Yoruba Nation ati akroyin kan to ka ohun rẹ silẹ lahamọ to si gbe e sori iwe iroyin titi to fi tan ka gbogbo agbaye ti wa sopin.

Ni ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ aṣemaṣe eyi ti wọn n pe ni "Chamber of Misdemeanors of the Court of First Instance" ni Cotonou ni ọpọlọpọ ibeere ti jade si olujẹjọ.

Nigba ti agbẹjọro Kato Attita n sọrọ ni atilẹyin Ọgbẹni Sunday Igboho, Aarẹ ile ẹjọ naa jẹ ko di mimọ pe awọn sun ẹjọ naa si waju lati le pe eeyan ti ọrọ kan.

Tori naa, Aarẹ ile ẹjọ ọhun fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ẹwẹ nigba ti olujẹjọ bọ sinu koto ẹjọ, o juwe ara rẹ o si bẹrẹ alaye pe Oloye Sunday Igboho lo pe oun lati wa kọ iroyin ohun to ṣẹlẹ nigba ti agbẹjọro rẹ Ibrahim David Salami ṣe ibẹwo si i latimọle Cotonou to wa, oun (oniroyin) wa tun pe agbẹjọro Salami fun alaye kikun.

Agbẹjọro fun ijọba bi olujẹjọ leere boya o gba aṣẹ lọwọ Ọgbẹni Sunday Adeyemo ko to ka ohun ọrọ ti wọn jọ sọ silẹ, esi to fọ ni wipe foonu oun ni Aapu kan to ma n dede ka ibaraẹnisọrọ lori foonu silẹ.

"Eyi ni mo gbe sita loju opo iroyin "Ede" tori pe iyawo Oloye Sunday Igboho jẹ ọmọ ilu kan naa pẹlu mi".

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho‘s Birthday: Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti túu sílẹ̀,

Agbẹjọro ijọba tun beere pe ki lo de ti ko fi ohun naa ranṣẹ taara siiyawo Sunday Igboho, o fesi pe oun ko mọ pe o yẹ ki oun fi ohun yẹn nikan ranṣẹ si iyawo Sunday Igboho.

Lori eyi, Ọgbni Kato Attita wa bọ sita to si pe akiyesi ile ẹjọ si aduru ewu ati ipalara ti Ọgbẹni Adekunle ti fa fun onibara rẹ, sunday Igboho pẹlu bo ṣe tu ohun naa sita fun gbogbo agbaye ati bo ṣe da aaw silẹ laarin Igboho ati awọn agbẹjọro rẹ, pataki julọ Ọgbni Ibrahim David Salami to lọ pe lẹyin.

Lori ipa ti yoo ni lori ipo sunday igboho laarin awọn mọ Yoruba, o tẹsiwaju pe ohun to ṣee yii ti ba ọpọlọpọ nkan jẹ fun Ọgbẹni Sunday Igboho.

O ni bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ naa ti tọrọ aforijin, ko le dede tan sibẹ, o rọ Aarẹ ile ẹjọ naa lati bu ẹnu atẹ lu olujẹjọ naa iyẹ akọroyin Adekunle ki wọn si ni ko san faani ogun miliọnu Naira ati pe ko lọ kọ iroyin abajade ati ipinu ile ẹjọ lori ẹjọ yii si awọn oju opo ayelujara kaakiri ko lee tan ka bi aṣiri to tu naa ṣe tan kari aye.

Agbẹjọro ijọba tun bọ siwaju adajọ lẹẹkan sii lati sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Ọgbẹni Adekunle Aremu ni pe o ja wọ inu aṣiri ikọkọ eeyan toun naa si gba pe oun ṣe bẹẹ.

"Ohun to ka silẹ naa lagbara gan ati pe bo ṣe pin in ka buru jai gẹgẹ bo ṣe wa labẹ aba la ofin 608".

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network

Ọgbẹni Adis Salami to jẹ agbẹjọro fun olujẹjọ sọ pe Ọgbẹni Adekunle lasiko to n ba Sunday Igboho sọrọ pe ko bu omi suuru mu koda pe o tun kan sara si Agbẹjọro Ibrahim David Salami.

"O ni agbẹjọro nla ni ati pe Ọgbẹni Sunday Igboho bọwọ fun un gidi gan. Ko jẹ ki ero aburu bọ sii lọkan rara nigba ohun ti akọroyin gbe jade yii.

Olujẹjọ wa tun bẹbẹ fun aanu lọdọ Aarẹ ile ẹjọ lẹ́ẹkan sii o si tun rawọ ẹbẹ si Ọgbẹni Sunday Adeyemo.

Nigba ti wọn lọ siwa lọ sẹyin tan lori ẹjọ naa to si yanju, Aarẹ ṣe idajọ.

Awọn abajade idajọ naa niyi:

- Wọn dajọ ẹwọn oṣu mejila fun un (amọ o ti ṣe oṣu meji nibẹ ti wọn si tu u silẹ bayii)

- Sisan faani 500,000 (FCFA)

- Wọn tẹwọ gba iwe awọn aṣoju ilu wọn si paṣẹ ki olujẹjọ san iye owo 2,000,000 (FCFA) fun Ọgbẹni Sunday Adeyemo

- Asẹ pe o gbudọ ṣe agbejade abajade idajọ yii lori ayelujara

Ẹwẹ, gbedeke ọjọ ti wọn fun un lati san faani ni ọjọ mẹwaa.

Gbedeke ọjọ ti wọn fun un san owo ibanilorukọ jẹ ni ọjọ aadọrun.

Gbedeke ọjọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun ni ọjọ mẹẹdogun