King of Satan: Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù

Awaye malọ kan o si, ọrun nikan ni are mabọ.
Ọgbẹni Simon Odo ti ọpọ mọ si Ọba Satani ti pari iṣẹ tiẹ laye yii lẹni ọdun mẹrinlelaadọrin.
Amọ, oriṣiiriṣii nkan manigbagbe lo wa ninu ọrọ igbeaye Ọba Satani to fi mọ eto isinku rẹ gan an.
- Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- Idán oríta nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners Chapel, okùnrin kan kù gììrì mọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo lórí pẹpẹ ìwàásù
- Kìí ṣe Tinubu ló kọ́ ilé tí mò ń gbé fún mi, GTB ló yá mi lówó tí mo fi parí ilé náà - Ayo Adebanjo
- Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ tí ọwọ́ àjọ DSS tẹ èèyàn 30 lára wọn
- Obìnrin kan tó ti Ìnsìpẹ́kítọ̀ Ọlọ́pàá ṣubú lulẹ̀ kàgbákò, ó dèrò ilé ẹjọ́ Badagry
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, iyawo mẹtadinlọgọta ni Ọgbẹni Odo fẹ nigba to wa laye.
Koda, oun gan an sọ fun ra rẹ pe oun ko mọ iye ọmọ ti oun bi tan.
Bakan naa, gbẹgẹdẹ gbina nibi eto isinku Ọba Satani, ọkó bọginni olowo iyebiye ni wọn fi gbe oku rẹ wa.
Nigba ti wọn fẹ sin Ọba Satani, wọn kọkọ gbe ọkọ kan sinu koto, lori ọkọ naa ni wọn gbe posi to wa ninu rẹ si.
Ọkọ naa ṣi n ṣiṣẹ bi wọn ti n sin in, bakan naa orin to fẹran ju naa n lọ labẹlẹ lai si idiwọ.
Uchenna Odo to jẹ ọmọ Ọba Satani ṣalaye pe baba oun lo sọ pe ki awọn sin oun bẹẹ ti oun ba papoda.
Ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2021 yii ni Ọba Satani jẹ Ọlọrun ni pe.
Uchenna sọ fun BBC Igbo pe nkan bi ago mẹta oru ni Ọgbẹni Odo dakẹ lẹyin ailera ranpẹ.
Ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa Ọba Satani
Yatọ si wi pe Ọgbẹni Odo fẹ iyawo to pọ, gbajugbaja babalawo nii ṣe ti ọpọ si mọ ọn si Ọba Satani.
Ilu Aji ni ijọba ibilẹ Ariwa Igbo-Eze ni Ọba Satani ti wa nipinlẹ Enugu.
O tiẹ sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC pe oun gan an ni Ọba Satani, o ni oun yoo gba ẹnikẹni to ba gba oun leti pada fun ra oun.
Ọba Satani ni lati idile iya oun ni oun ti jogun iṣẹ iṣegun yii.
Amọ, kii ṣe pe iṣẹ iṣegun yii ni Ọgbẹni Odo fi gbogbo ọjọ aye rẹ ṣe tori inu nijọ Aguda ni wọn bi i si.
Odo ni ''Ọdun 1956 ni mo ṣe itẹbọmi, mo si sin Oluwa laarin ọdun 1959 si 1960.
Bawo ni ọdọ ṣe wa di Babalawo?
O ṣalaye pe ọdun marun un ni ife fi mu oun eyi to gbagbọ pe wọn fi ṣe oun ni.
Lẹyin rẹ ni Ọba Satani tun dubulẹ aisan eleyi ti ko jẹ ko le rin fun ọdun marun un mii.
Aisan yii gan an lo mu ki Odo wa iwosan de Ijebu Ode nibẹ ni wọn ti sọ fun un pe awọn kan lo wa nidi ọrọ rẹ.
Ọdun meje ni Ọba Satani lo ni Ijebu Odo nibi to ti kọ iṣẹ alawo ki o to pada sile lati maa tọju awọn eeyan rẹ.
Amọ, Ọgbẹni Odo sọ pe oun kii ṣe oogun lati gba ẹmi eeyan ni toun, koda ti wọn ba gbowo tabua foun gan an.












