Ayo Adebanjo: Èèkàn Afenifere ní kìí ṣe Tinubu ló kọ́ ilé fún òun gẹ́gẹ́ bí Bisi Akande ṣe sọ

Bisi Akande, Bola Tinubu ati Ayo Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Olórí ẹgbẹ Afenifere, alagba Ayo Adebanjo ti sọ pé owo ti oun ya ni banki ni oun fi kọ ilé òun to wà ní Lekki, kii ṣe oloye Bola Tinubu lo kọ ile náà fún òun.

Adebanjo lo sọ ọrọ naa nínú atẹjade kan to fi ṣọwọ sí àwọn akọroyin ni ìdáhùn sí ọrọ alagba Bisi Akande ninu iwe rẹ, eyiti o sọ pe Tinubu lo kọ ile Adebanjo to wa ni Lekki fun un.

Adebanjo si tun sọ pe ki Akande kan si EFCC lati ṣe iwadi ọrọ́ toun sọ to ba da a loju.

Atẹjade náà ni "Ni ọsẹ kan sẹyin, wọn sọ níbi tí wọn ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ iwe ti oloye Bisi Akande kọ pe mo ke sí Bola Tinubu lati kọ ilé fún mi.

"Niwọn igba ti Tinubu fúnra rẹ wà níbí ìfilọ́lẹ̀ ìwé náà, mo gbagbọ pe o yẹ kó ti sọrọ pe kò sí ootọ kankan ninu ọrọ naa."

Adebanjo sọ pé bó tilẹ jẹ pé Tinubu fúnra rẹ ti sọ ṣaaju pe oun ko ipa ribiribi ninu bi Tinubu ṣe di gomina nipinlẹ Eko, oun ko figba kankan tọrọ owo lọwọ rẹ ri, anbelete pe o kọ ilé fún òun.

Baba Adebanjo ni awọn èèyàn oun ko fẹ kí òun fún Bisi Akande lesi lórí ọrọ naa, ṣugbọn oun yan láti fèsì ki Akande ma lọ ro pe ọlọgbọn ni o n ṣe.

Àkọlé fídíò, Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

Gẹgẹ bíi ohun tó sọ, ile rẹ to wa ní àdúgbò Nuru Oniwo, ìyẹn ni Àgùdà Surulelre ni oun n gbe ki oun to ko lọ sí Lekki.

O ni "Ile ifowopamọ GTB ni mo ti ya owo ti mo fi parí ilé mi to wa ni Lekki, eyiti mo n gbe báyìí.

"Lẹyin naa lo ké sí àjọ EFCC lati wa yẹ idi oro oun wo.

Ija ina

Oríṣun àwòrán, LASEMA

O tun ké sí Bisi Akande lati sọ okodoro ọrọ nipa oun to ti kọkọ sọ ṣaaju pe Tinubu lo kọ òun.