Senator Olujimi on Yoruba Nation: Ẹ wo Sẹ́nétọ̀ obìnrin tó gbàgbọ́ nínú àtúntò Nàìjíríà àti ìjà fún ìyapa Nàìjíríà
"Olóore ni mo jẹ́ sí Fayose la ṣe le ṣiṣẹ papọ, ko si ija laarin wa".
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Guusu Ekiti nile igbimọ aṣofin, Abiodun Christine Olujimi ti ni bo pẹboya, ko si igba ti awọn adari Naijiria ko ni gba si awn to n ja fun ẹtọ wọn lẹnu.
Bakan naa lo ṣalaye idi to fi dara ki awọn obinrin kopa ninu oṣelu.
O fi ara rẹ ṣe apẹrẹ gẹgẹ bo ṣe n ṣoju ẹkun kan l'Ekiti to jẹ ilu baba rẹ.
"Too ba fẹ dupo, wọn a ni ilu ọkọ ẹ ni koo lọ, boo ba tun lọ si ilu ara rẹ, awọn naa a ni ṣebi o lọkọ. Ọpẹlọpẹ Ọlọrun ni mo ṣe wa ni ipo ti mo wa yii".
- Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Imo
- Mo ṣèlérí láti lọ gbà'mọ̀ràn gidi kí n tó ṣe ìpinu dídupò ààrẹ ní 2023
- Ìròyìn òfegè lásán ni! Ilé ẹjọ́ kò gba agbára lọ́wọ́ àwọn ibùdó ìgbéyàwó tí a dá sílẹ̀, ẹ m'ẹ́nu kúró lórí Ikoyi Registry
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó dáná sún akẹ́kọ̀ọ́ Fásítì Osun, ohun táá ṣe nìyìí - Àláṣẹ iléèwé
Arabinrin Olujimi tun ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn to n ja fun Yoruba Nation ati ipo ti Naijiria wa lọwọlọwọ.
Àtúntò Nàìjíríà ni mo tò fún o, ìdí tí ẹ ṣe ní láti gbọ́ sí àwọn tó ń jà fún Yoruba Nation lẹ́nu rèé - Sẹnetọ Olujimi
O ni ilu le gan lasiko ti a wa yii ti gbogbo eniyan si n duro de asiko idibo to n bọ lati ṣe ipinnu to yatọ ti yoo mu aye wọn lọ siwaju.
