Cult attack in Osun Varsity: Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ fásìtì Osun táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn dáná sún

Awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun kan ti dana sun akẹkọọ ọmọ Naijiria kan ni ile ẹkọ fasiti rẹ to wa ni Osogbo to jẹ olu ilu ipinlẹ Osun.
Gẹgẹ bi atẹjade to tọwọ fasiti naa jade ṣe sọ, akẹkọọ yi wa ni ipele aṣekagba ni fasiti ipinlẹ Osun.
Ile ẹkọ naa sọ pe iṣẹlẹ yi waye lagbegbe Osunlepo ni Osogbo lọjọ Kọkanla oṣu Kejila ọdun yi.
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- Pásítọ̀ àti ìyàwó rẹ̀ l'Ogun ní Èṣù ló wà nídìí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ pẹ́lú ọmọ akọrin ọdún 16 ní ṣọ́ọ̀ṣì- Ọlọ́pàá
- Kí ló kàn báyìí lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ ọmọ ogun orí omi Nàìjíríà (Navy) tú Cute Abiola sílẹ̀?
Agbẹnusọ Fasiti, Ademola Adesoji ni ṣadede lawọn ri pe Victor Oke ko yọju lọsan ọjọ to yẹ ki o kọ idanwo rẹ ikẹyin.
Wn kan si awọn obi rẹ ti wọn si pada wa rii pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun ṣe ikọlu si lowurọ ọjọ Abamẹta.
Bo ti ṣe ṣẹlẹ

Oríṣun àwòrán, OSUN STATE UNIVERSITY
Gẹgẹ bi fasiti naa ti ṣe sọ, awọn oṣoju mi koro ni ṣe lawọn n gbọ ti Vitor n pariwo pe oun ko ni darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
Atẹjade naa sọ pe ''Wọn fi ada ṣa, wọn fọ okuta nla mọ ti wọn si fẹ dana sun ki awọn eeyan to gba a lẹ''.
Kaakiri loju opo ayelujara lawọn eeyan n ṣalabapin aworan ibi ti wọn ti lu Victor lalubolẹ.
Bẹẹ la ri ninu aworan naa pe o joko si inu omi ti awọn eeyan da lu lori lati le fi pa ina ti wn da sun un.
Fasiti sọ pe awọn beere bi nkan ti ṣe n lọ lọdọ awọn obi rẹ tawọn si gbọ pe o ti n gba itọju lọwọ.
Alukoro ọlọpaa Osun Yemisi Opalola naa fidi iṣẹlẹ yi mulẹ fun BBC
Opalola sọ pe awọn afurasi ẹlẹgbẹ okunkun yi le Victor de adugbo yi niti wn si ṣa lada ki wọn to da bẹntiroo si lori lati le dana sun.
''A o mu awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi nitori awọn oṣiṣẹ wa ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ yi''
O tẹsiwaju pe ''awọn ẹka alaabo fasiti ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu wa lati ri pe awọn to wa nidi iṣẹlẹ yifoju wina ofin''
Ipenija nla lọrọ ẹlẹgbẹ okunkun jẹ lawọn fasiti Naijiria
Ọpọ ẹmi lo wa ninu akọsilẹ pe o ti padanu lati ọwọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun ni Naijiria.
Titi di asiko yi ni ipolongo ṣi n waye lati koju aburu yi.
Lọpọ igba lawọn ẹlẹgbẹ okunkun maa n doju ija kọ ara wọn ti wọn a si maa pa arawọn ni ipakupa.
- Lẹ́ẹ̀mẹta, ọwọ́ tẹ ọmọ ọdún 18 l'Eko tó ń dúró sójú pópó ja olè
- Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá Osun fẹ́ fi panpẹ́ mú ọmọ Adedoyin tó ni Hòtẹ́ẹ̀lì tí Timothy Adegoke kú sí? Ọ̀rọ̀ ń rùn bọ̀ o
- 'Lójú mi, ọmọ ìyá mẹ́fà jóná, ọkàn kú nínú iná gàásì nílùú Abuja'
- Àṣírí gómìnà kan tó ti gbà tó N60B ní àpò àsùnwọ̀n ìpínlẹ́ rẹ̀ ti tú síwa lọ́wọ́ - EFCC
- Àgùnbánirọ̀ tí kò bá tíì gbabẹ́rẹ́ covid-19 kò ní lánfààní láti wọ kámpù- NYSC
Ọrọ yi ka ọpọ obi laya lati le jẹ ki awọn ọmọ wọn lọ kawe lawọn fasiti Naijiria nitori ẹru pe wọn le fẹ fi tipa mu wọn lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun
Ninu awọn ẹgbẹ okunkun tawọ
One of di cults for Nigerian higher institutions na Black Axe also known as Aye, Eiye, and Buccaneers.
For Osun State wey di sad incident hapun, di state police command bin launch campaign against cultism and oda crimes di youths dey engage in for just dis October 2021 wey pass.
















