Ọlọ́pàá Ogun ní pásítọ̀ àti ìyàwó rẹ̀ sọ pé Èṣù ló wà nídìí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ pẹ́lú ọmọ akọrin ọdún 16 ní ṣọ́ọ̀ṣì

Oríṣun àwòrán, Rolling stone
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe pasitọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Peter Taiwo ati iyawo rẹ, Elizabeth yoo foju ba ileẹjọ laipẹ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan wọn pẹlu ọmọ akọrin ẹni ọdun mẹrindinlogun ni Alaja Oke lagbegbe Saje niluu Abeokuta.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ogun. Abimbola Oyeyemi, sọ fun BBC Yoruba pe awọn tọkọ taya naa ni iṣẹ Eṣu ni iṣẹlẹ naa,
Ọgbẹni Oyeyemi ni awọn mejeeji ti tọrọ aforijin lọwọ ọmọ ọdun mẹrindinlogun naa lori ohun ti wọn ṣe fun un.
- Àgùnbánirọ̀ tí kò bá tíì gbabẹ́rẹ́ covid-19 kò ní lánfààní láti wọ kámpù- NYSC
- Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrin Yinka Alaseyori àti Sola Allyson tí Alaseyori ń bẹ̀bẹ̀?
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pẹ̀lú omíjé kíkorò ...'
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ awakọ̀ tírélà tó gbá akẹ́kọ̀ọ́ mérìnlá nílùú Eko
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
- Wọ́n gé gògòńgò ìyá wa lọ lẹ́yìn tí wọ́n pa a- Omo Iya Deeper Life
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni iyawo pasitọ naa lo sọ fun ọmọdebinrin naa pe pasitọ fẹ ran niṣẹ.
O ni kete ti ọmọ naa wọle tan ni iyawo ti ilẹkun ti ọkọ rẹ si bẹrẹ si ni wọ ijakandi pẹlu ọmọ naa ki o to pada fi ipa ba ọmọ naa lopọ.
Ọgbẹni Oyeyemi ni lẹyin ti pasitọ fipa ba ọmọ naa lopọ tan ni iyawo pasitọ ri nibi ti o ti n sọkun.
''Amọ ohun ti iyawo pasitọ sọ fun un ni pe ko maa sọ fun ẹnikan nitori o le ku to ba ṣe bẹẹ.
Iyawo pasitọ tun sọ fun ọmọdebinrin yii pe o ti di obinrin niyẹn lẹyin ti pasitọ ba lopọ tan.''
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ọmọdebinrin yii lo mu ẹjọ wa si agọ ọlọpaa fun ra rẹ lẹyin ti pasitọ fi tipa tikuuku ba lopọ tan.
Ọgbẹni Oyeyemi ni wọn ti gbe ọmọbinrin naa lọ si ile iwosan fun itọju lẹyin ti pasitọ ati iyawo rẹ ti ko si gbaga ọlọpaa tan.












