Ondo Deeper life cleaner killed: Wọ́n gé gògòńgò ìyá wa lọ lẹ́yìn tí wọ́n pa a- Omo Iya deeper Life
Ojọ Isinmi ni wọn pa iya agba kan ni Akoko nipinlẹ Ondo lasiko to n tun ayika ile ijọsin rẹ ṣe.
Okan lara awọn ọmọ iya agba naa salaye fun BBC pe, ọjọ ti pe ti iya oun ti maa n lọ tun ayika ile ijọsin Deeper Life Bible Church se ni Iwaro oke ni Akoko ni ipinle Ondo laisi iyọnu.
Bakan naa ni Arabinrin Ajifola Aduke to jẹ akọbi oku naa royin iya rẹ.
O sapejuwe rẹ gẹgẹ bii onisuuru to fẹran alaafia to si n fi gbogbo ara rẹ ṣiṣẹ fun Oluwa nipa titun ile ijọsin ṣe.
- Ọgọ́ta èèyàn tí àwọn jàndùkú jí gbé nínú ìjọ Baptist ní Kaduna ti gba ìtúsílẹ̀
- Aṣọ ń pe aṣọ rán níṣẹ́ ni lónìí nílé ìjọsìn Wolii Sotitobire lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tú olùdásílẹ̀ wọn sílẹ̀
- Awọn gbajumọ akọrin ati oṣere tiata obinrin Naijiria sọ nipa idẹyẹsi lọwọ awọn ọkunrin
- Ní kíákíá ẹ yí ìpinnu yín padà sí Nàìjíríà lórí ẹda ààrùn COVID-19 Omicron-Lai Mohammed
- Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Itunu Babalola kó tó di olóògbé tí wọ́n ń fi òkú rẹ̀ ránṣẹ́ sílé...
Ariwo ẹ dide, wọn ti pa iya yin ni gbogbo ara adugbo gbọ ti wọn si ba oku iya naa niwaju ṣoọṣi Deeper Life nibi ti awọn oniṣẹ ibi ti ge ọrun rẹ ti wọn si yọ gogongo rẹ lọ.
Oloye Bolorunduro Dele to jẹ alaga agbegbe Iwaro Oka Akoko naa ba BBC soro pe iru iṣẹlẹ yii ko ṣẹlẹ ri ati pè gbogbo ilu ti dide sii.
Arabinrin Omoode Comfort to jẹ aburo oloogbe naa sapejuwe rẹ gẹgẹ bii alaanu to jẹ olufọkan sin tootọ.

Nigba ti BBC Yoruba kan si agọ ọlọpaa. Agbenusọ fun ọlọpaa, Funmilayo Odunlami salaye ibi ti iṣẹ iwadii de duro lori iṣẹlẹ naa.
O tun kilọ pe ki onikaluku ṣora fun irin oru ati irin idaji lasiko yii pẹlu imọran pe ki awọn eeyan maa fi ifura ti wọn ba kẹfin to ọlọpaa leti ladungbo wọn lasiko.





