Gbajumọ akọrin Simi ati oṣere tiata Chigul tan imọlẹ si idẹyẹsi awọn obinrin lagbo tiata Naijiria

Oríṣun àwòrán, Macanthony Studios
Awọn gbajumọ oṣere ati akọrin obirin Naijiria ti bẹrẹ si ni sọ iriri wọn lori idẹyẹsi ti wọn n ba pade nitori pe wọn jẹ obinrin.
Eyi ko si ṣẹyin bi gbajugbaja akọrin Naijiria nii Simi ṣe lewaju pẹlu #NobodyLikeWoman to ti gbalẹ loju opo Instagram.
Labẹ hastag yi, awọn obinrin naa le na tan lati sọ nipa iriri wọn pẹlu idẹyẹsi nitori pe wọn jẹ obinrin.
- Ẹkún sọ nibi ìsìnkú Itunu Babalola tó kú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Ivory Coast
- Nàìjíríà ko ni lè wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì nítori ẹ̀ya Covid-19 Omicron
- Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nìyí nínú ìrọra kí ó tó kú, òní ni ọjọ́ ìbí rẹ̀!
- Wo ohun tí àwọn ọmọ Naijiria sọ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College, Sylvester Onoromi
- Ṣé lóòtọ́ ni ajínigbé sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí di iṣu ní Ibadan?
Simi ba BBC sọrọ to si tọka si awọn aworan to wa loju opo Instagram tawọn obinrin fi n beere pe ki lo de tawọn fi n koju idẹyẹsi.
O ni boun ti ṣe n wo aworan wọnyi, niṣe lomije n jabọ loju oun.
Ọkan to mẹnu ba lelelyi to ṣafihan obinrin kan ti awọn eeyan n dẹyẹsi nitori pe o ṣiṣẹ abẹ.
Awọn eeyan kan n beere lọwọ rẹ pe ki lo de ti ko fi le da ọmọ naa bi lalae ṣe iṣ abẹ.
Simi sọ pe 'ọrọ tawọn eeyan sọ yi buru pupọ: "'Ko tiẹ ṣe daa rara.Ṣe ko le da ọmọ rẹ bini?Wọn ni lati se iṣẹ abẹ fun ati pe ọkan ninu awọn ọmọ naa papa ku''
Iru nkan bayi lo mu ki akọrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn yi sọ pe oun fẹ bẹrẹ ipolongo ti yoo jẹ ki awọn obinrin mọ pe awọn nikan kọ ni wn da koju ipenija yi.

Ohun to ṣe yi se deede asiko to gbe orin tutnun jade.
Iyalẹnu lo jẹ plu bi awọn obinrin ti ṣe suugba ọrọ r yi tiu wn si bẹrẹ si ni ṣe alabapin hashtag to da silẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Aworan Simi kan to kọ si ara rẹ pe ''bawo lo ṣe le maa beere iru owo bẹẹ, ṣebi o loyun?'' jẹ eleyi to jẹ ki ipolongo yi gbinaya
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Gẹgẹ bi akọrin ilumọọka, Simi ri apejuwe iruidẹyẹsi to n koju paapa lagbo orin kikọ ni ilẹ Afrika.
O ni nigba toun bẹrẹ iṣ orin kikọ yi, awọn ọga oun s pe oun ni lati jẹ tabi ṣebi arẹwa bi oun ba fẹ ṣe aṣeyọri nidi orin.
O ni eti ikun loun kọ si ọrọ wọn.
Iyalẹnu lo jẹ fun wọn nigba to di ilumọọka.
O ṣalaye pe awọn eeyan kan til wa ti ko f ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn obinrin to ba ti bimọ nitori wn ro pe wọn ko wulo mọ.
Ninu iriri rẹ kan o sọ pe eeyan kan n beere pe ki lo de ti oun ṣe n beereowo pupọ lati kọrin lasiko ti o loyun.
'Bi o ba fẹ di ilumọka, mo gbọdọ ba ẹ ni ibalopọ'
Osere Nollywood,Chioma Omeruah tawọn eeyan mọ si Chigul naa tẹnu bọ iriri tiẹ to si ni kini ọhun nii ṣe pẹlu aṣa.
''Aṣa wa ni pe ki awọn eeyan maa sọrọ soke'' ni alaye to sọ fun BBC

Oríṣun àwòrán, Alistair Englebert
Ohun naa kopa ninu ipolongo #NobodyLikeWoman pẹlu aworan to kọ sara rẹ pe ''Arabinrin! Lọ bimọ''
Chigul sọ pe oun ko ni ọmọ eyi ko si ni kawọn ọrẹ ati ẹbi ma ma beere pe nigba wo ni yoo bimọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O ni awọn to sunmọ oun le maa ro ibi pẹlu ọrọ yi ṣugbọn o maa n fọwọ kan lẹmi.
O ṣalaye pe aimọye awọn obinrin lagbo tiata lo ti wa ba ohun lati sọ bi awọn ọga nlanla lagbo tiata ti ṣe n fi ibalopọ lọ awọn.
O sọ pe ninu wọn la ti ri awọn adari fiimu ti wọn a si maa sọ pe ''Wa ki n ba laṣepọ ki o ba le di irawọ nidi tiata. mo le jẹ ki o ri ipa toda gba ninu ere''
O sọ nipa oṣere kan ti wn fi ibalopọ lọ to si kọ ṣugbọn ti ọkunrin naa sọ fun pe ''ọmọ de lo n ṣe''
Nigba taa bere lọwọ Chigurl ko darukọ iye awọn obinrin to ti mu iru ẹjọ yi wa setiigbọ rẹ, o ni ''aimọye''
Ati Chigurl ati Simi lo gba pe o yẹ ki wọn mu iyipada ba ofin to n daabo bo awọn obinrin lọwọ idẹyẹsi.

Gẹgẹ bi ajọ UN Women ṣe sọ, Naijiria ti fidi ida 75% ofin ti wọn nilo lati tẹsiwaju iṣedeede laarin ọkunrin ati obinrin eleyi ti UN fẹ fi rinlẹ jakejado agbaye ni ọdun 2030
Amọ ko to idaji awọn ilana ti yoo mojuto bi orileede naa ṣe n gbiyanju si ni wọn ti ri fi lelẹ lọdun to kọja.
Bi apẹrẹ bigba iroyin loore koore lori aidọgba owo oṣu laarin ọkunrin ati obinrin ati ifiyajẹni to fi mọ ifipabanilopọ.
Wọna tun maa fi ọrọ bibeeli jẹri pe o tọ lati fi iya jẹ obinrin
Sotonye Kelechi-Nwuzi to jẹ gbajumọ agbẹjọrọ ati ajafẹtọ obinrin sọ pe ẹsin naa ni ninu ẹbi ọrọ yi.
Ninu alaye rẹ, o sọ pe awọn aṣofin Naijiria a maa wo nkan ti sin ba s ki wọn to gbe ofin kalẹ lori iṣedeede laarin ọkunrin ati obinrin
Arabinrin Kelechi-Nwuzi to jẹ ọmọ lẹyin Kristi sọ pe iṣoro nla leleyi jẹ.
''Bi ọna ba wa lati ya awujọ ati ẹsin lọtọ mo lerope itsiwaju yoo de ba wa''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa lo tun da awọn ọlọpaa Naijria naa lẹbi.
O ni pupọ ẹjọ ti awọn gbe lọ sọdọ wọn to ni ṣe plu ifiyajẹ obinrin ni wọn kii ka kun.
Lọpọ igba o ni awọn eeyan a maa ka ẹsẹ bibeeli lati le fi jri si pe ki ọkunrin fi iya jẹ iyawo rẹ ko laburu.




















