Itunu Burial: Ẹkún sọ nibi ìsìnkú Itunu Babalola tó kú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Ivory Coast

Wọ́n ti gbé òkú Itunu Babalola ti ó kú sí ọgbà ẹ̀wọn Ivory Coast wa sílé ní ilú Ibadan ti ṣe olúúlú ipínle Oyo
Wọ́n sọ Itunu si ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ti kò mọ̀dí sùgbọ́n ti ó kú sínu ẹ̀wọn náà nínú oṣù tó kọjá.
Àná òde yìí ni wọ́n gbé òkú ọmọ náà dé láti mu u wọ káà ilẹ̀ sùn ni ibòjì Sango lónìí ọjọ́ Sátidé.
Gbogbo àwọn aṣòjú àjọ tó ń ri si ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkeèrè ló péjú síbẹ́ ìsìnkú náà láti sojú alága àjọ náà, Abike Dabiri-Erewa.
- Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nìyí nínú ìrọra kí ó tó kú, òní ni ọjọ́ ìbí rẹ̀!
- Òbí akẹ́kọ̀ọ́ girama da ìpàdé òbí rú, lu Tíṣà ní àlùkì l‘Oyo, ohun tó wáyé lẹ́yìn rẹ̀ rèé
- Òfo ni 'White Paper' Sanwo-Olu kò sí ǹkan tó n jẹ́ bẹ́ẹ̀ lábẹ́ òfin - Adegboruwa
- Obìnrin ẹni ọdún 28 kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ariwo sọ!
Alẹ́ ọjọ́ Eti ni òkú Itunu balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurú Muritala Muhammed pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú Air Côte D'Ivoire tí wọ́n sì gbé e lọ sí ìpínlẹ̀ Oyo.
Ọjọ́ kẹrinla, osù kọkànlá, ọdún 2021 ni Itunu kú ti àwọn ọmọ Nàìjíríà sì polongo ọ̀rọ̀ náà lójú òpó ìkànsíraẹni pé Itunu kú, ti ọ̀pọ̀ sì barajẹ lórí ikú tó pa ọmọ náà.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, Itunu ẹni ọdún mọ́kànlélógún náà jẹ onísòwò ni Bondoukou ni Cote d'Ivoire ti àwọn ọ̀daràn kan si já ilé rl lásìkò tí kò sí nílé nínú oṣù kẹsán an, ọdún 2019.
Ìdí èyí ló fi mu ẹjọ́ náà lọ bá àwọn ọlọ́pàá, sùgbọ́n, sùgbọ́n ọlọpàá sọ fún un pé ìbátan òun ni ẹni a funrasí náà.
Leyin naa ló sì bẹ Itunu kí o je ki àwọn lọ yanjú ọ̀rọ̀ náà níta ati pé o bẹe láti gba ẹgbẹ̀rún lọnà ọgọrun un nàírà, sùgbọ́n ọmọ náà ni owó ọ̀hún kéré si dúkía òhun ti wọ́n jí.

Ó ní ǹkan ti wọn jí yóò tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ̀dúnrún náírà, lẹ́yin èyí ni wọ́n padà mú Itunu nítori ko gba owó tí wọ́n fi lọ̀ọ́ ti won si fí ẹsùn ìṣòwò ẹrú kan an àti pé wọn dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́waa fún-un

Àṣẹyìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, ikú ló já sí fún Itunu nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ti wọ́n fi sí.

Ẹkún sọ nibi ìsìnkú Itunu Babalola tó kú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Ivory Coast
Lásíkò ìsìnkú náà ni Baba Itunu tí n dupẹ lọ́wọ́ alága àjọ tó n ri sí ọ̀rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó n gbe níll òkeèrè, Abike Dabiri-Erewa fún àwọn iṣẹ takùntakun ti ó ṣe láti jẹ ki wọ́n ri oku ọmọ náà gbá pàdà wá sílé.
O fí kun un pé kí ó tó kú náà, ó ti ń gbìyànjú láti yọ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n kí ó tó pàdà wá já sí ikú.
















