Parent beats Teacher in Oyo: Ìjọba Oyo dá akẹ́kọ̀ọ́ dúró tórí ìyá rẹ̀ lu tíṣà

Obi to kọlu awọn olukọ nile iwe

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Akẹkọọbinrin ile ẹkọ girama Jericho niluu Ibadan ti gba idaduro lẹnu ẹkọ rẹ lori ẹsun pe o ko awọn ẹbi rẹ lọ si ile ẹkọ, nibi ti wọn ti fiya jẹ akẹgbẹ rẹ kan at'awọn olukọ rẹ pẹlu.

Kọmiṣọnna feto ẹkọ nipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Rahman Abiodun Abdu-Raheem lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita niluu Ibadan.

Kọmiṣọnna eto ẹkọ ni laipẹ yii ni iya akẹkọọbinrin naa yabo ilẹ ẹkọ rẹ pẹlu awọn tọọgi ti wọn sì bẹrẹ si ni lu awọn eeyan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Kọmiṣọnna ṣalaye pe awọn tọọgi ọhún lu akẹkọọkunrin kan, awọn olukọ at'awọn at'awọn obi nibi ti ìpàdé obi ti n waye.

O sọ fun BBC Yoruba pe gbogbo awọn ti ọrọ kan lóri iṣẹlẹ naa ni ijoba yoo kan si lati le ri pe iru rẹ ko waye mọ lọjọ iwaju.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

Ọgbẹni Abdu-Raheem rọ gbogbo eeyan lati ni ẹmi ikonimọra, iṣọkan ati ibọwọ fun ara ẹni.

Kọmiṣọnna eto ẹkọ tun sọ pe ijọba ipinlẹ Oyo ko ni fi oju ire wo ẹnikẹni to ba n hùwa jagidijagan.

Bakan naa ni o rọ awọn obi, akẹkọọ ati gbogbo awọn ti ọrọ kan lati gbaruku ti eto ẹkọ to yanranti.

Ile ẹkọ girama Jericho High School