#Endsars Panel: Adegboruwa ní Sanwo-Olu kò láṣẹ lábẹ́ òfin láti da ìwádìí ìgbìmọ̀ Endsars nù

Oríṣun àwòrán, Others
Agbejoro agba kan ni Naijiria, Ebun-Olu Adegboruwa ti ni ko si ofin kankan to fi aye gba gomina Babajide Sanwo-Olu, lati fi ọwọ da iwadii ajọ to ṣe iwadii Endsars nu.
Ninu atẹjade kan ti Adegboruwa fisita eyi to fi n sọ ero rẹ nipa ipinnu ijba Eko lori iwe ilana to gbe kalẹ nipa abọ igbimọ iwadii EndSARS ni agbẹjọro naa ti fi ero rẹ yii han.
Agbẹjọro agba naa ni ko si ofin to fi aye gba abajade lori iwadii naa ti ijọba pe ni '' white paper''.
- Wo àwọn ìdí tí Adájọ́ fi dá Wòlìí Sotitobire láre, tó sì da ẹ̀wọ̀n gbére nù
- Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa ṣe ìwọ́de lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
- Ìjọ Redeem gbé ojú òpó olólùfẹ́ kalẹ̀ sórí ayélujára fáwọn ọ̀dọ́ láti pàdé ọkọ tàbí aya
- Kókó méje tó wà nínú ‘White Paper’ ìjọba Eko lórí àbọ̀ ìwádìí ìwọ́de EndSARS
- A kò faramọ́ àbájáde ''Endsars Panel Report'', kò sí ẹni tó kú ní Lekki Tollgate sẹ́ẹ̀, "White paper" wa rèé - Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko
- Èsì iléẹ̀kọ́ Dowen rèé sí ìkú akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ ní àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa nítorí kò darapọ̀ mọ́ wọn!
- N kò fara mọ́ ẹ̀rí Princess, ẹ yọ́ dànú torí kò bá òfin mu - Baba Ijesha yarí nílé ẹjọ́
- Òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ló sin Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ OAU tó kú sílé ìtura - Agbẹjọ́rò
''Labẹ ofin, ijọba apapọ to fi idi ofin iwadii Tribunal of Inquiry Law, section 15 mulẹ pe, oun kan ṣoṣo ti gomina ipinlẹ ni aṣẹ lati ṣe ni imuṣẹ iwadii ti awọn oluwadii ṣe.
''Gomina ko le e wa gbe aṣẹ miran jade to da abọ iwadii igbimọ naa nu.''
''Bakan naa ni ko si nkankan to n jẹ white paper ninu ofin to de iwadii Tribunal ni ipinlẹ Eko, to ni ki gomina da iṣẹ wọn nu lẹyin iwadii to munadoko ti wọn gbe jade.''

Oríṣun àwòrán, Others
''Gẹgẹ bi a ṣe sọ tẹlẹ, iwadii igbimọ naa ni agbara lati fi ontẹ lu aṣẹ ti wọn ba pa pe ki wọn ṣe san owo gba ma binu fun awọn ti wọn nilo rẹ.''
''Ko bojumu bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe yan lati fari apa kan, da ikan si lori abajade iwadii wọn.''
''Bawo ni ipinlẹ Eko ṣe gba lati san owo gba ma binu fun awọn ti ọlọpaa hu iwa ifiyajẹni si, amọ ti wọn wa sọ wi pe ileeṣẹ ologun ko si ni abẹ akoso naa?''
''Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ko si ni abẹ akoso ijọba ipinlẹ, nitori naa irọ patapata ni white paper Gomina Sanwo-Olu.''
Agbẹjọro agba, Ebun-Olu Adegboruwa naa fikun pe, ijọba ipinlẹ Eko pa irọ lori pe awọn ko ṣe iwadii awọn daradara.
O ni iwadii awọn fihan pe awọn soja yin ibọn to ni ọta ninu ati eleyii ti ko ni ọta ninu lu awọn oluwode.
Bakan naa ni ifọrọwanilẹnuwọ pẹlu awọn dokita fihan gbangba pe wọn ṣe itọju awọn oluwọde ti wọn ni ọgbẹ ọta ibọn ni ara lẹyin iṣẹlẹ naa.


















