Sotitobire: Ilé ẹjọ́ ní Wòlíì Sotitobire kò mọ ohunkohun nípa ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé, ìdí rèé

Alfa babatunde, Asaaju ijọ Sotitobire

Ọkan lára àwọn ti ó ń ṣe ẹjọ́ ẹ̀sùn igbimọ-pọ jí ọmọ gbé ti wọn fi kan Woli Alfa Babatinde Sotitobire ni Ìpínlẹ̀ Ondo ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo fúnra wọn, wọn ti wá sọ ìhà tí wọn ko si idajọ to jade lana ọjọ Kẹta oṣù Kejìlá ọdun 2021.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun to wa niluu Akure ti da idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun pasitọ ijọ Sotitobire, Alfa Babatunde nu.

Idajọ yii n waye lẹyin ọdun kan ti ile ẹjọ giga to wa njiluu Akure ṣe idajọ naa fun pasitọ ọhun atawọn mẹfa mii ninu oṣu Kẹwaa ọdun 2020 lori ẹsun jiji ọmọ gbe.

Aworan Woli Alfa

Oríṣun àwòrán, Facebook/wolialfa

Ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa to wa nile ẹjọ, Roseline Aribo, sọ fun BBC Yoruba pe inu oun gidigidi fun itusilẹ oludasilẹ pasitọ awọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Adajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun ọhun sọ pe pasitọ Sotitobire ko mọwọ-mẹsẹ ninu ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan an.

Adajo Hamma Barka to da ẹjọ naa ni awọn ẹri ti wọn fi dajọ ẹwọn gbere fun Sotitobire ko lẹsẹ nilẹ ati pe alufaa ọhun ko mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan.

Akinyemi Omoware, to jẹ ọkan lara awọn agbejọro Sotitobire sọ fun BBC pe otitọ ti leke eke nini ẹjọ alufaa ọhun.

O fi kun pe asiko ti to fun awọn ọmọ ijọ alufaa naa lati maa jo ijo ayọ bayii.

Awọn agbẹjọro ijọba ati ti Sotitobire

Agbẹjọro naa sọ siwaju si pe ile ẹjọ ti tu ọkan lara awọn mẹfa ti wọn dajọ ẹwọn gbere naa fun, ti orukọ́ rẹ n jẹ Egunjobi Motunrayo silẹ ninu ẹwọn lati maa lọ layọ ati alaafia.

Motunrayo jẹ ọkan lara awọn olukọ ewe ile ijọain ti iṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bii ọdun meji sẹyin.

Omoware ni akọsilẹ Ọlọrun ni pe wolii Sotitobire yoo la isoro to la kọja yii.

Ẹwẹ, agbejọro ijọba Charles Titiloye, SAN, sọ pe awọn yoo gba iwe idajọ to waye lonii, awọn yoo si gbe yẹwo lati mọ igbesẹ to kan fun awọn.

Amọ Alfa Babatunde ko yọju sile ẹjọ Kotemilorun naa lonii, o si wa ni ahamọ ọgba ẹwọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kọkanla, ọdun 2019 ni ọmọ ọdun kan, Kolawole Gold di awati ninu ṣọọṣi Sotitobire, to wa niluu Akure.

Ọdun kan lẹyin naa ni wọn ṣe idajọ ẹwọn gbere fun Alfa Babatunde atawọn mẹfa mii pe wọn lọwọ ninu bi ọmọ ọhun ṣe sọnu ki ile ẹjọ Kotẹmilọrun to yi ẹjọ naa danu bayii.

Amin iyasọtọ kan

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí Wòlíì Sotitobire pè?

Sotitobire

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun nilu Akure ti kun fọfọ lonii ọjọ Ẹti lori ẹjọ kotẹmilọrun ti Alfa Babatunde ti ijọ Sotitobire pe.

Ileẹjọ kotẹmilọrun to n joko ni ilu Akure ti kede saaju pe ọjọ Kẹta,Osu Kejila ni awọn yoo gbe idajọ kalẹ lori idajọ ẹwọn gbere ti wọn fun wolii naa lori ẹsun ijinigbe.

Awọn agbẹjọro fun igun olupẹjọ ati ijọba ti gunlẹ sile ẹjọ, to fi mọ Wolii Babatunde to pe ẹjọ Kotemilorun naa.

Bakan naa ni awọn alatilẹyin olupẹjọ naa, to fi mọ awọn ọmọ ijọ rẹ ati awọn onworan ti pe babi lati mọ bi idajọ naa yoo se lọ.

Saaju ni Kọmisọnna fun eto idajọ nipinlẹ Ondo, Charles Titilayo ti fi idi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.

Àkọlé fídíò, Sotitobire church: Ẹgbẹ́ CAN ní kí ìjọba ṣe ohun tó yẹ

Woli Babatunde Alfa ti ọpọ eniyan mọ si Woli Sotitobire ni adari ati oludasilẹ ijọ Sotitobire Miracle Church to wa ni ilu Akure ni ipinlẹ Ondo.

Woli Sotitobirẹ n beere lọwọ ileẹjọ kotẹmilọrun lati da ẹjọ to ran an lọ si ẹwọn gbere ni Ọjọ Kẹfa, Osu Kẹwaa, ọdun to kọja nu.

Osu keji ọdun 2020 ni Wòlíì Sotitobire ti bẹrẹ si ni foju wina ẹjọ lori ẹsun ijọmọgbe, ti adajọ si ni o jẹbi ẹsun ijọmọgbe ti wọn fi kan gbajugbaja wolii naa atawọn mẹfa miran

Bi idajọ naa ba si se n lọ, ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.

Awọn ero to pejọ sile ẹjọ
Àkọlé fídíò, Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba