Banditry in Nigeria: Abubakar Malami ní ìjọba ti gba àṣẹ iléẹjọ́ láti pe agbébọn ní agbésùnmọ̀mí

Malami

Oríṣun àwòrán, Others

Minisita feto idajọ ati agbẹjọro agba ni Naijiria, Abubakar Malami, ti fi idi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ti di agbesunmọmi bayii.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileesẹ mohunmaworan kan nilu Eko ni Malami ti sọ wi pe awọn ti beere fun aṣẹ ileẹjọ, ti awọn si ti ri gba.

Malami ni laipẹ ni imuṣẹ aṣẹ ileẹjọ naa yoo bẹrẹ, ti ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ gẹgẹ bi agbebọn yoo si foju wina ofin gẹgẹ bi agbesunmọmi.

Lori ẹsun pe o pẹ ju ki ijọba to fi ontẹ lu u pe awọn agbebọn ti di agbesunmọmi ni Naijiria, Malami ni ipenija yii nira fun ijọba lati tete gbe igbesẹ lori rẹ ni kiakia.

Bakan naa lo fikun pe, lati wakati yii agbesunmọmi ni wọn yoo ma a pe awọn agbebọn lati isinyii lọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

''Aṣẹ ileẹjọ duro ni gbogbo igba paapaa lori ọrọ awọn agbesunmọmi yii.''

''Nitori naa gbogbo aṣẹ ileẹjọ lori awọn agbesunmọmi duro wamuwamu titi ijọba yoo fi gbe ontẹ lu u.''

Olootu eto idajọ naa ni lati isinyii awọn eleto aabo ati ẹṣọ alaabo ni aṣẹ lati fi iya jẹ awọn agbebọn gẹgẹ bi awọn agbebọn.

Bakan naa ni Malami ni oun ko le e fi ọwọ sọya pe awọn soja lo ọta ibọn gidi lati fi pa awọn ọdọ Endsars ni Lekki Tollgate ni ọdun to kọja.