Raped for nine months: Oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n fi jí mi gbé tí wọ́n ń fipá bá mi lòpọ̀ títí tó fi di oyún

Mercy ti wọn ji gbe

"Emi ati ọrẹ mi fẹ kaa rinrinajo jade kuro ni Naijiria, ọrẹkunrin rẹ wa sọ fun un pe ẹgbọn oun nilo awọn obinrin lati lọ baa ṣiṣẹ ni Italy.

La ba lọ si Eko lati lọ ri ẹni naa, o sọ fun wa pe ka duro tori wọn ti n ṣe iwe irina wa atawọn nkan mii taa nilo lati fi rinrinajo naa".

Mercy sọ iriri nigba to n ba BBC sọrọ nipa irinajo rẹ ati iriri to ni lakata awọn ajinigbe to ji i.

Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni ọdọbinrin ọmọ Naijiria yii to si n wa iṣẹ - lọna ati wa iṣẹ yii lo ti ba ara rẹ ninu ọgbun awọn ajinigbe lẹyin ti awọn kan tan oun ati ọrẹkunrin rẹ lati wa bẹrẹ iṣẹ kan.

O ṣalaye pe lati inu oṣu kẹwa ọdun 2020 ni iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Irinajo si Eko

Mercy sọ pe oun lọ si ipinlẹ Eko pẹlu ọrẹ oun loṣu Kẹwa ọdun 2020 lẹyin ti ọrẹkunrin rẹ ṣeleri iṣẹ kan fun un pe o wa ni Italy to si ni ki wọn wa si Eko.

O ni ọrẹkunrun oun sọ pe anti oun n wa eeyan ti yoo baa ṣiṣẹ ni orilẹede Italy lou ati ọrẹ rẹ obinrin ṣe gbera lọ si Eko.

Mercy ṣalaye pe nigba ti awọn de Eko, o sọ fun ọrẹ rẹ pe ọkan oun ko fibẹẹ fẹran ibi ti awọn wa amọ ẹni ti wọn lọ ba sọ pe ko fara balẹ pe wọn yoo ko passport wọn ati visa wa nirọlẹ.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

Mercy fi ẹsun kan pe ẹni to gba awọn lalejo fun awọn ni ọti ẹlẹrindodo ti wọn ti fi oogun orun sinu rẹ. "Nigba ti awa mejeji ji, inu igbo la ti ba ara wa".

"A bere fun oun taa le jẹ, taa le mu, wọn gbe ounjẹ ati ọti ẹlẹrindodo ti wọn de pa wa, igba taa mu ọti ẹlẹrindodo naa tan, ibi ti a ko mọ la ti ba ara wa".

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'
Mercy ti wọn ji gbe

Wọn fipa ba wa lopọ, wọn lu wa

Obinrin kan bimọ ninu igbo yẹn to si ku sibẹ. Obinrin kan sọ pe oun ti n ṣeto ati sa lọ. "Wọn n fiya jẹ wa, ko si omi, ko si ounjẹ wọn si n fipa ba wa lopọ".

O ni ninu igbo ọhun, ṣe ni wọn n fiya jẹ awọn ti wọn si n ba wọ lopọ. o ni wọn tun yinbọn pa awọn mii lara wọn nigba miran paapaa awọn to ba ṣe ori kunkun. "Eeyan meji ni wọn yinbọn pa niwaju mi. Wọn a tun sọ fun wa pe ohun to maa ṣẹlẹ si awa naa niyẹn bi a ba ṣe ori kunkun. Gbogbo igba ni iṣan awọn Ọkunrin naa maa n le tori oogun oloro ti wọn n lo ko si si nkan ti wọn o le ṣe lasiko naa".

Mercy tun fẹsun kan pe ọkunrin kan to maa n sọ ede Faranse wa sinu igbo yẹn ti awọn ajinigbe si fun un ni ọmọbinrin kan. Mercy ni awọn ajingbe ọhun tun n ṣe owo fayawọ.

Àkọlé fídíò, Wo ìgbé àyé ìyá àti ọmọbìnrin tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun

Bi ori ṣe ko mi yọ ti mo sa jade

Mercy ni oun rii pe oun ti loyun ninu igbo awọn ajinigbe ọhun inu rẹ ko si dun sii rara.

Ọkan lara awọn obinrin ti wọn ba nibẹ lo ṣe ọna bi wọn ṣe sa lọ mọ awọn ajinigbe lọwọ. "Dẹrẹba ọkọ ajagbe to ran awa mẹrin lọwọ kuro nibẹ de opopona marosẹ sọ pe Eko ni oun n lọ".

Mercy sọ pe inu igbo ni Blessing ku si nigba ti wọn duro lati sinmi bi wọn ṣe n sa lọ.

Oṣu Keje ọdun 2021 ni ori ko Mercy yọ to kuro ni ibudo awọn ajinigbe ọhun lati inu oṣu Kẹwa ọdun 2020 to ti wa nibẹ.

Ọrẹ ori Facebook ni akoba yii ti bẹrẹ

Aburo obi Mercy, Maureen naa ba BBC sọrọ lori ọrọ yii - Mercy ko tii ni okun pupọ lati sọrọ tori ko tilẹ tii mọ bo ṣe n ṣe e.

"Ọrẹ rẹ kan lo sọ fun un pe ọrẹkunrin oun loju opo Facebook lo sọ pe iṣẹ kan wa ni Italy fun wọn pe ẹgbọn oun kan to wa nibẹ lo n ṣe agbatẹru sisan owo irina fun awọn obinrin lọ sibẹ. o sọ fun un pe owo gọbọi ni wọn yoo maa gba".

Maureen ni "ọpọ ọkunrin ni yoo wa, mu oogun oloro ti wọn a si ba Mercy atawọn obinrin mii lopọ. Bakan naa ni wọn tun n ṣe oogun owo ninu igbo ọhun. Mercy sọ pe wọn ni tabili kan lori eyi ti wọn ti n dunbu awọn eeyan".

Anti Mercy sọ pe awọn ajinigbe ọhun lo maa n fun awọn obinrin to ba ti wa lasiko nkan oṣu wọn ni akisa lati fi si abẹ fi di ẹjẹ to n da.

"Awọn ọkunrin naa yoo wa mu apo wa lati ko gbogbo akisa to ti rẹ pẹlu ẹjẹ nkan oṣu awọn obinrin".

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

Maureen ni lati ọdun to kọja lawọn ti n wa Mercy afi to ṣẹṣẹ di Ọjọbọ ọsẹ to kọja ninu oṣu kọkanla ni awọn to foju kan ara.

Mercy to ti jẹ ẹni to n ṣe iṣẹ ase ounjẹ tẹlẹ ki iṣẹlẹ yii to ṣẹlẹ ni oun kan fẹ maa ba igbe aye oun lọ ati lati ran ọmọ oun lọwọ.

"Mo fẹ kawọn ọmọ Naijiria ran mi lọwọ ni ọnakọna ti wọn ba lagbara. iṣẹ alase ounjẹ ni mo n ṣe tẹlẹ ki wọn to sọ fun mi pe mo lee ri iṣẹ gidi ni Italy pẹlu owo to tun san".

Kii ṣe igba akọkọ ti iru nkan bayii yoo ṣẹlẹ ni Naijiria, ni Akwa Ibom loṣu kẹrin ọdun 2021, iroyin gba ori ayelujara pe obinrin kan Iniobong Umoren dawati lẹyin to lọ ba ọkunrin kan to ni ko wa bẹrẹ iṣẹ.

Ọrẹ Umoren, Umoh Uduak lo gbe ọrọ naa sori Twitter to si tun kede nigba to ya pe ọrẹ oun ko si laaye mọ o.

Ọlọpaa mu afurasi kan, Uduak Akpan lori ọrọ naa ti wọn si fi ẹsun ijinigbe kan an ati ẹsun ifipabanilopọ ati pipa Umoren.

Iroyin naa kan gbogbo ọmọ Naijiria

Ni oṣu Kẹwa ọdun 2021, iroyin bi obinrin kan to jẹ ọdun mẹrinlelogun, Joy Onoh naa ṣe ku lẹyin ti eeyan kan to lọ ta aṣọ fun ṣe e lọṣẹ.

Aburo rẹ sọ fun BBc pe lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹwa ni onibara kan ni ko wa gbe aṣọ fun oun amọ ti wọn bẹrẹ si ni fura nigba to lọ ti ko pada de ni irọlẹ.