Taye Currency ní ọmọ ibàdàn tí Saheed Oṣupa jẹ́ kò lè já òun gbà lẹ́yìn Pasuma

Oríṣun àwòrán, Taye currency
Ṣe ẹ mọ wi pe ọmọ ilu kan naa ni Saheed Osupa ati Taiwo Akande Adebisi ti ọpọ mọ si Taye Currency?
Ilu Ibadan ni awọn mejeeji, eyi ti o fi han pe a lee pe wọn ni tẹgbọn taburo.
Amọṣa Taye kọrẹnsi ti sọ pe lootọ ọmọ ilu kan naa ni awọn mejeeji, sibẹ Pasuma Ọganla loun yoo ba lọ lọjọkọjọ.
- Ẹ pàdé Manuella, ọmọ ọdún méje tó ń ṣe àkàrà òyìnbó 'cake'
- Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá -Part 2 Ti Oluwa Nile- dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé- Baba Wande
- Agbábọ́ọ̀lù ọmọ Tunisia dáná sun ara rẹ̀ láti fẹ̀hónúhàn lòdì sí àwọn ọlọ́pàá
- Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi
- Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Mukaila Adedigba ti jáde láyé
- Mọ̀ nípa ààrun tó le mú kí o máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tí o bá n rìn láì mu ọtí yó
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba nigba naa ni, Taye Kọrẹnsi ni lasiko ti aawọ wa laarin Alaaji Alabi Pasumọ Ọganla ati King Saheed Oṣupa, oun o da si aawọ aarin wọn nitori bi Saheed Oṣupa ṣe jẹ ọmọ ilu oun ti o si dara si oun naa ni Pasuma jẹ awokọṣe fun oun to si jẹ pe ati maa ṣe bọ wọn ti le ni ni ogun ọdun.
O ni bi o tilẹ jẹ wi pe awọn eeyan kan n reti ki oun gbe lẹyin Oṣupa nitori awọn jọ jẹ ọmọ ilu kan naa, sibẹ, wọn tun gbọdọ roo pe oun ati Paso ni awọn jumọ jọ wa lati aye alalumọlẹ.
O ni idi niyi ti oun ko fi da si ija aarin awọn mejeeji.
Amọṣa o fi kun un o pe lootọ oninufufu ni Oṣupa Saheed sibẹ o dara si oun ko si si idi kan fun aawọ lati wa laarin oun ati Oṣupa.
Bakan naa ni Alaaji Taiwo Akande Adebisi Taye Kọrẹnsi naa tun sọrọ lori bi o ṣe wakọ wọ agbami oṣelu, ọmọ rẹ, Yusuf Adebisi to jẹ ọkan lara awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ ati oniruuru iṣẹlẹ nipa igbesi aye rẹ.
Gbogbo eyi ni ẹ lee wo ni oju opo facebook BBCNewsYoruba tabi ki ẹ tẹ adirẹsi ayelujara to wa ni isalẹ yii:
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post















