Agbábọ́ọ̀lù ọmọ Tunisia dáná sun ara rẹ̀ láti fẹ̀hónúhàn lòdì sí àwọn ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, AFP
Agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Tunisia, Nizar Issaoui, ti ku lẹyin to dana sun ara rẹ lọna ati fẹhonuhan lodi si awọn ọlọpaa.
Awọn mọlẹbi rẹ sọ pe bo ṣe farapa lẹyin to dana sun ara rẹ lo mu ẹmi rẹ lọ.
Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ ṣafihan bo ṣe n pariwo pe awọn ọlọpaa fi ẹsun igbesumọmi kan oun lẹyin ede aiyede pẹlu ẹnikan to n ta eso.
Ninu atẹjade kan to fi lede, o ni oun ti ṣedajọ iku fun ara oun pẹlu ina.
Ọlọpaa ti kọkọ fi ẹsun igbesumọmi kan Issaoui lẹyin to ni o ṣoro fun oun lati ra kilo ọgẹdẹ kan ni $3.30, eyii to jẹ ilọpo meji iye owo ti ijọba kede pe ki wọn maa ta eso naa.
Lẹyin naa lo lọ soju opo Facebook rẹ to si kọ atẹjade kan pe “Nitori ariyanjiyan pẹlu ẹni to n ta ọgẹdẹ... wọn fẹsun igbesumọmi kan mi.”
“Bawo ni ẹsun igbesumọmi ṣe jọ mọ ọrọ nipa ọgẹdẹ....”
Ko pẹ lẹyin atẹjade yii to lọ dana sun ara rẹ.
Ọpọ awọn araalu lo kọju ija si ọlọpaa nibi eto isinku oloogbe ọhun lọjọ Ẹti, bi ọlọpaa ṣe n yin gaasi tajutaju lawọn araalu n ju okuta si awọn ọlọpaa.
Aburo rẹ ṣalaye fun awọn akọroyin pe ina naa jo pupọ, awọn onimọ iṣẹgun si gbiyanju lati doola ẹmi rẹ amọ o ti bọ sori.
Issauoi ti fi akoko igba kan gba bọọlu fun ikọ US Monastir ri, ọmọ mẹrin lo si fi silẹ saye lọ.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ijọba Tunisia ko tii sọ ohunkohun nipa iku agbabọọlu naa.












