Ẹgbẹ́ alakatakiti Boko Haram gbèrò láti ló 'Drone' kọju ikọ ológun...Àjọ ISS

Aworan ẹgbẹ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, ológun BokoHaram

Ẹka to n risi ẹtọ aabo ( ISS) ti kede wi pe ẹgbẹ alakatakiti agbebọn ISWAP ń gbero lati lo baalu aju ado oloro sì awọn agbegbe kan odo lake Chad . Ajọ ISS ni ẹgbẹ ISWAP fẹ ṣe ikọlu si awọn agbegbe ti wọn ti foju sun ni orilẹ-ede Naijiria ati awọn ilu to yi ka. Ajọ ISS ni, awọn ikọ ọmọ ologun orilẹ-ede yii ti ṣe ikọlu si ikọ Boko Haram ati awọn ẹka rẹ bi Jama’atu Ahlis-Sunna Lidda’Awati Wal-Jihad (JAS) ati ISWAP. ISS ni akọjọpọ ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn ọmọ ikọ alakatakiti Boko Haram tẹlẹri,atupalẹ awọn iroyin ipolongo ẹgbẹ naa fihan wi pe ikọ Boko Haram nlọ imọ ẹrọ ayelujara ode oni.

Lara awọn ọhun elo igbalode ti ẹgbẹ ọhun lo ni,ẹrọ ibaraẹnisọrọ to nlọ imọ ẹrọ satelite,ẹrọ ayelujara,wifi,gbohu gbohun alalẹ mora ati awọn Ẹrọ ayelujara igbalode miran. Iṣẹ iwadii ajọ ISS fihan pe Abba Yusuf oludari ẹka ibaraẹnisọrọ Boko Haram to tun jẹ ọmọ oludasile ikọ Boko Haram Mohammed Yusuf lo wa nidi ẹka ayelujara ati imọ-ẹrọ ode oni ikọ alakatakiti Boko Haram. Ajọ ISS fìdi rẹ mulẹ wi pe ẹrọ ayelujara Wifi Thuraya ni ikọ Boko Haram nlọ ti wọn si n na ẹgbẹrun mẹfa dọla fun itakun ayelujara,itakun ipinlẹ Eko ni wọn kọkọ lo ṣaaju ki wọn to maa lo itakun orilẹ-ede Chad.

Ọna abayo lati mu opin ba iṣẹlẹ iṣeku pani ẹgbẹ Boko Haram.

Ajọ ISS rọ ikọ ologun lati tẹsiwaju lati ṣe ayẹwo awọn ọkọ ayọkẹlẹ to n wọle jade kí wọn le gbogun ti gbigbe awọn eroja ogun wọle.

Wọn rọ ikọ ologun lati ni ibasepo pẹlu awọn ara ilu kí wọn le ri iroyin ti yoo mu opin ba ikọlu ẹgbẹ alakatakiti Boko Haram.