Wo èníyàn 100 , tó fi mọ́ Bola Tinubu, tó gbajúgbajà jùlọ ní ágbàyé

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram
Orukọ Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Naijiria, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu ti wa lara awọn eniyan ọgọrun to gbajugbaja julọ ni agbaye.
Ileeṣẹ iroyin Time Magazine lo ri awọn orukọ naa lede, ti orukọ Tinubu si pẹlu awọn adari lagbaye bii ogun ti orukọ wọn wọ inu akọsilẹ naa.
Ileeṣẹ iroyin naa ni Tinubu sẹ ohun ti ẹnikan ko ‘seri pẹlu bi o ṣe bori ninu idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria lẹyin to ti lo ogun ọdun lati gbaradi fun ipo aarẹ naa.
Akọsilẹ Time Magazine naa ni o ma n wo iṣẹ ribiribi ti awọn eniyan to gbajugbaja ṣe lagbaye, paapaa ni awọn iṣẹ ti wọn yan laayo.
Alaye ree lori idi ti Tinubu fi wa lara awọn eeyan to laami laaka julọ lagbaye
Ileesẹ iroyin Times ni ''Kii ṣe ohun to dẹrun ni lati bori ninu idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria.''
''Gẹgẹ bi aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu gbaradi fun ipo yii fun odidi ogun ọdun.''
''Jagaban to tumọ si olori awọn ologun lo jẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọrin, to dibo sipo aarẹ fun igba akọkọ ni Naijiria pẹlu akọle pe 'Emi lo kan’.
''Ni ọdun 1999, Tinubu wa lara awọn to ja fun ijọba tiwantiwa lati pada si Niajiria lẹyin ti wọn koju ijọba ologun, to si dipo gomina ipinlẹ Eko mu fun saa meji.''
Bakan naa ni ileeṣẹ iroyin naa ko ṣẹnu po lori awọn ipenija to tẹle eto idibo to gbe Tinubu wọle.
''Bi o tilẹ jẹ pe Tinubu bori ninu idibo naa amọ ohun to fi bori ko pọ rara, ti ọpọ ninu awọn ọdọ si fẹ ki ẹni to gbe ipo kẹta, Peter Obi jẹ aarẹ.''
''Nibayii, Tinubu yoo maa tukọ orilẹede ti ẹlẹyamẹya ti ṣe bi ẹni pe o gbinlẹ si ati iwa jẹgudujẹra to fi mọ ija ẹsin ati awọn ikọ agbebọn ati Boko Haram to doju eto aabo Naijiria bolẹ.''
''Bakan naa ni Tinubu yoo maa koju awọn to fidirẹmi ninu idibo naa ni ileẹjọ lati fi idi rẹ mulẹ pe boya lootọ lo jawe olubori ninu idibo naa.''

Oríṣun àwòrán, Dimie Ogoina
Orukọ dokita mii lati Naijiria, Dimie Ogoina , wa lara wọn to laami laaka julọ lagbaye
Awọn miran ti orukọ wọn wa ninu akọsilẹ naa ni Dokita Dimie Ogoina to jẹ Ọjọgbọn nipa imọ ajakalẹ aarun ni fasiti UCLA ni Amẹrika.
Oun lo pe akiyesi awọn onimọ lagbaye si ajakalẹ arun Monkeypox, to ṣewadii rẹ fun bii ogun ọdun.
Ilu Okolobiri to wa nipinlẹ Bayelsa lorilẹede Naijiria ni onisegun oyinbo naa ti wa.
Dokita naa ni wọn lo la awọn eniyan lọyẹ nipa ajakalẹ aarun Monkeypox, to si pe akiyesi sii, ki aarun naa ma ba di nkan miran ni agbaye bii Coronavirus.
El Anatsui lati Ghana, Lionel Messi, adari ileeṣẹ Tiktok, Shou Zi Chew ati awọn miran lo gba ami ẹyẹ naa fun ọdun 2023.
Orukọ awọn ọmọ Naijiria to ti wọ inu akọsilẹ yii ni aarẹ Muhammadu Buhari, Ngozi Okonjo-Iweala, Tony Elumelu, Oby Ezekwesili, Chimamanda Adichie ati awọn miran.
Wo awọn eeyan ọgọrun ti orukọ wọn wa lara awọn to laami laaka lagbaye
Michael B. Jordan
Drew Barrymore
Ali Wong
Austin Butler
Aubrey Plaza
Rian Johnson
Salma Hayek Pinault
Zoe Saldaña
Judy Blume
Colin Farrell
Lea Michele
Simone Leigh
Wolfgang Tillmans
Suzan-Lori Parks
Neil Gaiman
Shervin Hajipour
El Anatsui
Colleen Hoover
Steve Lacy
Jennifer Coolidge
Ke Huy Quan
Sara Mardini and Yusra Mardini
Shah Rukh Khan
Pedro Pascal
Brittney Griner
King Charles
Salman Rushdie
RowVaughn Wells
Tracie D. Hall
Peng Lifa
Shannon Watts
Haluk Levent
Imara Jones
Yvon Chouinard
Doja Cat
Mikaela Shiffrin
Bella Hadid
Sam Altman
Niloofar Hamedi and Elaheh Mohammadi
Thom Browne
S.S. Rajamouli
MrBeast
Elizabeth Maruma Mrema
Britney Schmidt and Peter Davis
Sam Rivera
Robin Zeng
Edward Reynolds
Margaret Mitchell
Olena Zelenska
Luiz Inácio Lula da Silva
Hakeem Jeffries
Evan Gershkovich
Janet Yellen
Sherry Rehman
Mitch McConnell
Anthony Albanese
Margrethe Vestager
Joe Biden
Samuel Alito
Gustavo Petro
Gina Raimondo
Oleksandra Matviichuk
Fumio Kishida
Cindy McCain
María Herrera Magdaleno
Olaf Scholz
Bola Ahmed Tinubu
Min Aung Hlaing
Angela Bassett
Laurene Powell Jobs
Lionel Messi
Padma Lakshmi
Johan Rockstrom
Beyoncé
Patrick Mahomes II
Elon Musk
Gina Prince-Bythewood
Karen Lynch
Shou Zi Chew
Ozlem Tureci and Ugur Sahin
Deborah Lipstadt
Bob Iger
Sarah Kate Ellis
Kylian Mbappé
Natasha Lyonne
Monica Simpson
Nathan Fielder
Wanjira Mathai
Hidetaka Miyazaki
Jerrod Carmichael
Catherine Coleman Flowers
Sean Sherman
Iga Swiatek
Kate Orff
Dimie Ogoina
Andrea Kritcher












