Oludayo Olayiwola: Aláwàdà tó ń fi ìpèníjà ojú pa ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rìn-ín lórí Tik-Tok
Ara meeriri gbaa ni iroyin yii, nibi ti mama kan ati ọmọ rẹ ti n fi ipenija oju se awada lati pa ni lẹrin loju opo Tik-Tok.
Adura ti gbogbo ẹda maa n gba nile aye ni pe ki Ọlọrun mase jẹ ka ri adantan, bi adanwo ba tilẹ de.
Sugbọn bi adanwo ba de, iha ti ẹda ba kọ si ni yoo sọ bi adanwo naa yoo se tete di ohun igbagbe si.
- Àrà méèrírí! Ọkùnrin tí kò ríran kan rèé tó ń lọ ẹ̀rọ ata
- Báyìí kọ́ ní wọ́n ṣe bí èmí àti aya mi ṣùgbọ́n a kọ̀ láti tọrọ bárà- Tokotayà tó ni ìpènijà oju
- Kàyèéfì! Ẹ wo ẹni tó ní ìpèníjà ojú tò ń tún ẹ̀rọ̀ ńlá tó ń sọ omi di yìnyín ṣe
- Mo tọrọ ikú pẹ̀lú májèlé torí wàhálà ọkọ́ àmọ́ Ọlọ́run kò fún mi - Onírú tí kò ríran
- Ẹ fún wa láṣẹ́ láti yọ ojú yín tẹ bá kú fún ìwúlò alààyè tí ojú rẹ̀ fọ́ - Ibùdó ìtọ́jú ojú ń pariwo
Iru eeyan bẹẹ ni mama yii, Oludayo Olayiwola to ni ipenija oju.
Mama yii ati ọmọ rẹ si gbajumọ loju opo ayelujara Tik-Tok, ti wọn ti maa n se awada, eyi to maa n pa ọpọ eeyan lẹrin.
Bakan naa tun ni mama ti ko riran rara yii tun maa n lọ ẹrọ ata, maa ro fufu, to si tun maa n se isẹ lorisirisi.
Kayefi nla lo maa n jẹ fun ọpọ eeyan to ba ri mama yii, ti wọn si maa n beere pe bawo lo ti n se e?

Oríṣun àwòrán, Olayiwola
Eyi lo mu ki BBC Yoruba tọ mama Oludayo Olayiwola lọ lati mọ orisun agbara rẹ to fi di gbajumọ loju opo TIK-TOK.
Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, mama yii ati ọmọ rẹ ni ipenija oju yii de lojiji, to si da nnkan ru.
Amọ ọna lati gbe ironu naa kuro lara lo mu ki wọn maa pa ọpọ eeyan lẹrin loju opo Tik-Tok, ti mama naa si di gbajumọ.
Mama Oludayo Olayiwola ni sadede ni ipenija oju naa de ba oun ni bii ọdun mẹwaa sẹyin, ti awọn dokita si ni ko ni atunse mọ.
O ni oun ti maa n lọ ẹrọ ata tẹlẹ ki ipenija oju to de, oun ko si fẹ maa se agbe jẹun tabi jiya lo mu ki oun si tẹsiwaju lati maa rọ ẹrọ ata.
- Wo tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ojú àmọ́ tó ń ṣiṣẹ́ ọwọ́
- Mo di afọ́jú lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí aya mi kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ - Wòlíì Oluwalogbon
- Wo ẹgbẹ́ akọrin ẹlẹ́ni 23, tí 18 ní ìpèníjà ojú, 5 péré ló ríran
- Afọ́jú akẹ́kọ̀ọ́gboyè sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀
- Olè fẹ́ fipá bá ìyá mi lòpọ̀, mo takú, wọ́n sì fìdí ìbọn fọ́ mi lójú - Ayàwòrán olójú kan
- Ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ àti aya lọ lẹ́yìn ti ojú mi lọ ní 2012 ṣùgbọ́n lónìí iṣẹ́ Àdìrẹ ti sọ mi dí eèyàn- Muritala David
Bakan naa ni ọmọ mama naa ni ọpọ ọdọ to ti pa obi wọn to ni ipenija ara ti, ni wọn ti pada n lọ tọju wọn lati igba ti oun ti n gbe mama oun to ni ipenija oju sita loju opo Tik-Tok.
O ni nnkan ti yatọ lati igba tawọn ti bẹrẹ wada naa, ti ọpọ eeyan si maa n fi nnkan ransẹ si mama naa.
Mama Oludayo Olayiwola wa gba awọn eeyan to ni ipenija bii tiẹ nimọran lati mase ro pe o ti tan fun awọn.
- Ìpèníjà ojú kò ní kí ń má ṣiṣẹ́ ‘DJ’ - Etu Sodiq Omotayo
- 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí àpò owó “customer” tí mi ò mọwọ́
- Ẹ̀kún l'oúnjẹ́ mi ní ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ́yìn tí ojú mi fọ́ ní JSS 3- Lawal Ayankemi
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Torí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí



