Pains and Pleasure Band: Ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tó ní ìpèníjà ojú ló jẹ́ Ẹnjiníà, atagìtá, alugángan etc

Àkọlé fídíò, Pains and Pleasure Band: Ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tó ní ìpèníjà ojú ló jẹ́ Ẹnjiníà, atagìtá

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni fidio yiii nitori ko daju pe iru isẹlẹ yii pe meji yika agbaye.

Abi ẹyin ti gbọ ri pe ẹgbẹ akọrin kan wa, ti ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni ipenija oju, ti wọn si n dabira ni awuja.

Ninu ẹgbẹ akọrin yii, eeyan mẹtalelogun lo wa nibẹ, amọ eeyan marun pere ninu wọn lo le riran kedere, se ni awọn yoku ni ipenija oju.

Orukọ ẹgbẹ akọrin amuludun naa ni Pains and Pleasure (PP), ti wọn si n kọrin lati da awọn eeyan laraya lagbo ariya lorisirisi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bawo ni wọn se ko ara wọn jọ?

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, diẹ lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ni ipenija oju salaye pe awọn sa wa ara awọn ri ni.

Ẹgbẹ akọrin PP naa, ti wọn lo bẹrẹ lọdun mẹrinlelogun sẹyin, si lo n pawo wọle fun wọn lati ri ọwọ mu lọ sẹnu.

Awọn eeyan to ni ipenija oju naa ni wọn ko bi ohun bii afọju amọ awọn miran ninu wọn lo gbe ipenija oju wa lati ọrun.

A ni Onimọẹrọ, agbohunsilẹ, atagija, afọnfere, alugangan ati bẹẹ bẹẹ lọ - Manija ẹgbẹ

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, alakoso ẹgbẹ akọrin amuludu naa, taa tun mọ si Manager salaye pe inu ile kan soso ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ni ipenija oju naa n gbe.

O ni oun dijọ n gbe ile pẹlu wọn ni, ti wọn si ni ki oun wa se manija awọn.

O salaye pe o maa n jẹ iyalẹnu ni ode ariya lati ri awọn akọrin naa, ti ọpọ wọn ko riran rara amọ ti wọn n kọrin ju awọn eeyan miran to riran lọ.

Manija fikun pe lara awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin naa to ni ipenija oju ni Onimọẹrọ, agbohunsilẹ, atagija, afọnfere, alugangan ati bẹẹ bẹẹ lọ wa.

‘Wọn fẹ ko ye awujọ pe awọn si wulo lai se agbe ni wọn se n kọrin’

Manija naa fikun pe iyalẹnu ni ipinnu awọn ọmọ ẹgbẹ to ni ipenija oju naa lori bi wọn se pinnu lati maa krin jẹun.

O ni wọn ko fẹ maa se agbe jẹun tabi tọrọ baara, lo mu ki wọn maa kọrin, bakan naa si tun ni wọn fẹ fi han awujọ wa pe awọn si wulo.

O fikun pe lara awọn eeyan wọn yii gan kawe, ti wọn si lọ sile ẹkọ giga.

Bakan naa lo ni wọn ti se igbeyawo,, wọn ti bimọ, ti omiran ninu wọn gan ti ni ọmọ-ọmọ.

O ni ọpọ obinrin to ba ri wọn bi wọn se n kọrin, lo n nifẹ wọn, ti wọn si gba lati fẹ awọn akọrin to ni ipenija oju naa bii ọkọ wọn.

A nilo awọn nnkan amayedẹrun bii ọkọ akero fun isẹ wa – Ẹgbẹ akọrin PP

Awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin Pains and Pleasure wa salaye pe lootọ ni awọn n ri ọwọ mu lọ sẹnu amọ awn si nilo awọn ohun eelo amayedẹrun kan fun idagbasoke ẹgbẹ naa.

Lara ohun ti wọn mẹnuba ni ipese ọkọ akero ti yoo maa ko awọn ọmọ ẹgbẹ naa jade, paapaa lọ sode ariya ti wọn ba ti ni isẹ.