Lateef Adedimeji: Mo ri iṣẹ́ Ọlọ́run, omijé gbọ̀n mí, mo sì rí ìdí tí ọpẹ́ fi tọ́ sí mi

Oríṣun àwòrán, adedimejilateef/Instagram
Yoruba ni ẹda to ba mọ inu ro, yoo mọ ọpẹ du nitori ẹni to ba ri isẹ Ọlọrun yoo fi ọpẹ fun Eledua.
Ọpọ isẹ Ọba Oke si la n ri ni ojoojumọ ti a ko ka kun ayafi igba to ba kan wa gangan.
Bẹẹ si ni ọpọ akanda ẹda to yi wa ka ni a ko ti ara wọn yin Ọlọrun logo, ayafi ta ba ri itọni lati se bẹẹ.
Boya itọni yii gan ni gbajumọ osere tiata Yoruba kan, Lateef Adedimeji ri, ti omije fi bọ loju rẹ, to si bẹrẹ si ni fi ọpẹ fun ọba oke.
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Adedimeji?
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- Mo ti ní ìyàwó àfẹ́sọ́nà, ayẹyẹ ìgbeyàwó mi ń bọ̀ láìpẹ́ - Lateef Adedimeji
- Irọ́ ni o, mí o fẹ̀ Lateef Adedemeji- Oyin Elebuibọn pẹ̀lú omijé ojú
- Sinimá tí Lateef Adedimeji dá nikan jẹ́ òṣèré yóò jáde, Yemi Solade fi ọ̀pọ̀ fọ́tò "dẹngẹ pó" lọ́jọ́ ìbí rẹ̀
Nigba to n salaye ohun to mu omije jade loju rẹ naa, agba osere tiata naa ni oun ronu jinlẹ lori ipo tawọn ẹda to ni ipenija oju wa ni.
Adedimeji, ẹni to salaye ohun to foju kan lasiko to sabẹwo sile ẹkọ awọn akanda ẹda to ni ipenija oju loju opo Instagram rẹ, ni ẹru Ọlọrun ba oun.

Oríṣun àwòrán, adedimejilateef/Instagram
"Mo ri ẹwa awọn isẹda Ọlọrun lonii lẹkunrẹrẹ, pẹlu omije loju, mo si ri didi to fi yẹ ki n maa dupẹ lọwọ adaniwaye.
Ọlọrun lagbara, to si maa n mu ki ẹnu ya ẹda pẹlu awọn ohun iyanu to n se, ọna rẹ si yatọ si ti eniyan patapata.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Arapaja jáwé olúborí nínú ìdìbò alága ẹgbẹ́ ìwọ òòrùn gúúsù
- Ọlọ́pàá yìnbọn lu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nílùú Eko, wàhálà dé
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ lágbo tíátà Yoruba, àgbà òṣèré míì tún jáde láyé
- Makinde fàgbà han Fayose, Arapaja fi ẹyin alátako janlẹ̀ láti dì alága PDP ní SW
- Ọmọ yẹrí ẹ, èpè ń bọ̀! Kí ló dé tí Foluke Daramola bu èpè jólẹ̀ lórí ayélujára?
- N kò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Boko Haram àti Al-Qaeda, ẹbu ìròyìn ló jáde síta - Mínísítà
Loni ni mo jami lori aayan mi lati ni oye nipa iru ẹda ti Ọlọrun jẹ, eyi kii se isẹ mi lati mọ, ki oun sa maa jẹ Ọlọrun, ki emi si maa jẹ ẹda ọwọ rẹ."
Adedimeji, ẹni to fi fidio abẹwo to se sile ẹkọ awọn akanda ẹda to ni ipenija oju naa soju opo Instagram rẹ, wa fi ẹmi imoore rẹ han si Ọlọrun fun ipo to wa.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Mo gbadun akoko ti mo lo pẹlu awọn akẹkọọ to ni ipenija oju nile ẹkọ Bethesda, wọn ko ni mọra pupọ.
Ko si ọna miran ti yoo dara ti mo fi le lo akoko mi ju ki n wa pẹlu awọn akanda ẹda yii lọ, awọn eeyan yii ni ẹyin n pe ni afọju amọ mo n pe wọn ni Oju Ọlọrun.
Awọn eeyan yii ko le ri mi bii ẹlẹran ara amọ wọn so pọ mọ ẹmi mi ju ọna kan lọ, Ọlọrun fi ẹbun ọwọ to lagbara jinki wọn ati ẹmi to yanranti."
Adedimeji tẹsiwaju pe lati isẹju akọkọ ti oun de ọdọ wọn, titi di akoko ti oun fi wọn silẹ, se ni ayọ ati okun wa lara wọn.

Oríṣun àwòrán, adedimejilateef/Instagram
O ni bi o tilẹ jẹ pe oun ti kuro lọdọ wọn, sibẹ ẹmi oun ko kuro nibẹ, to si n rọ awọn ololufẹ rẹ lati maa sabẹwo sawọn akanda ẹda naa.
"Ohun ti mo n salaye yoo tete ye yin tẹ ba n bẹ awọn eeyan yii wo, lati akoko yii lọ, maa sọ abẹwo mi sile awọn eeyan to ni ipenija oju naa di ajọdun ọdọọdun.
Wọn ko ni da wa mọ, wọn yoo si maa ri mi ni oore koore ju ti tẹlẹ lọ."
Adedimeji ni ipa sise bii afọju ti oun ko ninu ere ti oun se nile ẹkọ awọn afọju naa jẹ ki oun mọ si nipa ohun tawọn eeyan to ni ipenija oju n la kọja.
Osere tiata naa wa rọ awọn eeyan to ba n la ipo to nira kọja lati ni ọkan akin, ki wọn si maa ranti pe alaanu ni Ọlọrun.
"Ọlọrun yoo farahan yin lasiko ti ẹ ko nireti rẹ, ẹ sa maa fi ẹmi imoore yin han si, kẹ si maa dupẹ lọwọ rẹ.
Bi ẹmi ba wa, ireti n bẹ, ẹ mase sọ ireti nu nitori ile aye yii rẹwa pupọ, Ọlọrun si dara.



















