Yollywood: Irọ́ ni o, mí o fẹ̀ Lateef Adedemeji' - Oyin Elebuibọn pẹ̀lú omijé ojú

Adedeji Lateef

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja oṣere, Oyin Elebuibon ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe oun ni nkan ṣepọ pẹlu akẹgbẹ rẹ, Lateef Adedeji.

Eyi ko ṣẹyin iroyin to jade pe oserebinrin Oyin Elebuibon n fẹ Lateef Adedeji, ati wi pe Lateef lo ni ọmọ ọwọ rẹ.

Amọ, ni oju opo Instagram rẹ lo ti sọ wi pe ko si ohun to jọ ọ nitori awọn oniroyin ẹlẹjẹ lo gbẹ iroyin naa jade

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

O ni inu ọkọ oun ati baba oun kodun si iroyin naa, ati wi pe kini oun fẹ salaye fun awọn ololufẹ oun.

O ni oun to ṣẹlẹ ni wi pe awọn ọrẹ oun lọ sọ wi pe ki oun fi orin aladun ki Lateef ti oun ṣe ọjọ ibi ti oun si kii fun ayẹyẹ ọjọ ibi naa.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

O ni ko si ọrọ ifẹ tabi ibaṣepọ kankan laarin wọn bi ko ṣe ti oṣere si oṣere.

Bẹẹ si ni Lateef kọ lo ni ọmọ oun, ati wi pe irọ lasan ni.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Lẹyin to fi iroyin naa lede, ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ lo n kii pe ki o ye sunkun, nitori awọn oniroyin ẹlẹjẹ.

Oyin Eleibuibọn jẹ gbajugbaja oṣere, ti baba rẹ, Yemi Elebuiboon si jẹ onimọ ifa ti ọpọlọpọ eniyan mọ daradara ti wọn si fẹran ji ilẹ Yoruba.

Ilu London ni Ilẹ Gẹẹsi ni Oyin Elebuibọn n gbe, to si ti kopa ninu ọpọlọpọ ere sinima.