Kano case: Kí ló mú kí géńdé Olorun fi àfọ́kù ìgò gé ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ ní Kano?

Oríṣun àwòrán, @Kano Police command
Ki lo mu ọdọ lanti lanti fi afọku igo ge nkan ọmọkunrin rẹ ni Kano?
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti fidi ọrọ naa mulẹ pe arakunrin kan Mustapaha Muhammad ti o jẹ olugbe agbegbe Kurna ni Malam Na Andi ti gbẹmi ara rẹ.
Iroyin yi n ṣe gbogbo eeyan ni kayeefi nitori pe wọn lo fi afọku igo ge ara rẹ ni nkan ọmọkunrin ni.
Wọn ni o ti ara rẹ mọle ninu yara kan lẹyin naa to fo igana wọle naa ni adugbo Musukwani ni Kano ni ariwa Naijiria.
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- A kò tíì gbọ́ pé ilé ẹjọ́ wọ́gilé gbígba owó lọ́wọ́ àwọn dẹ́rẹ́bà ni ibudokọ ipinlẹ Oyo- awọn Awakọ̀
- Alhaja Muslimot Salami tí àwọn darandaran kọlù ní Ogun tí padà jẹ́ Olorun nípè!
- Àìṣàtìpó rí ló ń da Ejiogbe láàmú, àsìkò ìjọba tèmi ló dé- Alhaji Mukaila Auxilliary
Alukoro ọlọpaa ni Kano, DSP Haruna Kiyawa sọ pe isẹlẹ yii waye lọjọ Aiku ti se ọjọ ayajọ ololufẹ.
O ni awọn lọ si adugbo naa lẹyin iroyin to tẹ awọn lọwọ pe arakunrin kan ti fo igana wọle ni Musukwani to si mu afọku igo lọwọ.
DSP Kiyawa salaye pe o wọ inu iyara kan ninu ile naa to si fi afọku igo yi ge ara rẹ ni nkan ọmọ kunrin ati lawọn ibomiran lara rẹ.
"Laipẹ ta gbọ pe iroyin isẹlẹ yi lawọn ọlọpaa wa debẹ.Wọn sare gbe arakunrin naa lọ si ile iwosan Murtala nigboro nibẹ ni awọn dokita ti gbiyanju lati doola ẹmi rẹ sugbọn ẹpa ko boro mọ''
Lara awọn ti obinrin ile ti isẹlẹ yi ti waye ti BBC ba sọrọ sọ pe''lowurọ la kan ri arakunrin yi to n sa gidigidi wọle wa.Taara ninu iyara mama wa lo lọ ti o si ti ilẹkun mọri.''
''Ko pẹ si igba naa la ri wi pe o ti fori gba ti o si ge ara rẹ nigo lori.Nise ni ẹjẹ n da jade gan an''
- Mínístà, Kọ̀wé fipò rẹ sílẹ̀ tàbí kí o dákẹ́ tí ò kó bá wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó sọnù- ọmọ Nàìjíríà
- A fẹ́ kí ìjọba fòfin de àwọn darandaran tó máa ń fi ìbọn Ak47 da málúù láàrín ìlú- MURIC
- Ẹ fura o! Nàìjíríà ń pín lọ díẹ̀ díẹ̀ rèé- Abdulsalami
- Gbenga Daniel kò ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní PDP, ó kàn fi ẹ̀ka APC kan sílẹ̀ lọ sí òmíràn ni- PDP
- Ìjì òtútù pa èèyàn 21 ní Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ míràn ń dojúkọ ìṣoro àìsíná ẹ̀lẹ́ńtíríkì
Usman Umar to jẹ ọkan lara awọn ọrẹ oloogbe sọ fun BBC pe''awọn wa pẹlu rẹ ni wakati diẹ sẹyin ki o to pa ara rẹ ati pe oun ri to n wo sokoto penpe to si n ba baba afọju kan jiyan''
O salaye pe: "lati kekere ni a ti jijọ jẹ ọrẹ, eeyan daada si ni. Mo ri to n ba eeyan kan jiyan to si wọ sokoto penpe.
''Arọ ni ẹni to n ba jiyan to si ni o fẹ wa pa oun laaarin ooru. Mo baa sọrọ pe ki o pada lọ sile ko lọ wọ asọ rẹ. Nigba to lọ tan, mi o mọ nkan to pada sẹlẹ''
Ibrahim Abdulsalam to jẹ aburo Mustapha salaye pe arun ọpọlọ n damu rẹ ati pe lati igba to ti dari lati Saudi lo ti bẹrẹ.Koda o ni o pọ si ni nkan bi ọjọ mẹta sigba to pada wa gbẹmi ara rẹ.
Isẹlẹ yi n waye lẹyin igba ti a gbọ imiran to nise pẹlu akẹkọọ fasiti ijọba apapọ ni Dutsen ipinlẹ Jigawa ti oun naa gbẹmi ara rẹ lẹyin ede aiyede pẹlu ọrẹbinrin rẹ.
- Philip ẹni ọdún 99 tó jẹ́ ọkọ Ọbabìnrin Elizabeth ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
- Àìṣàtìpó rí ló ń da Ejiogbe láàmú, àsìkò ìjọba tèmi ló dé- Alhaji Mukaila Auxilliary
- Mínístà, Kọ̀wé fipò rẹ sílẹ̀ tàbí kí o dákẹ́ tí ò kó bá wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó sọnù- ọmọ Nàìjíríà















