Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ akẹ́kọ̀ọ́ tó mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé ni Cross River

CR

Oríṣun àwòrán, Valiant Samson Idowu-Alaba

Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Cross River ti tẹ akẹkọọ kan to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn fẹsun kan pe o mu ibọn ilewọ lọ sile iwe lati yin lu ọkan lara awọ olukọ rẹ.

Iroyin ni ọmọdebirni naa ti wọn ko fi orukẹ rẹ lede jẹ akẹkọọ Government Secondary School to wa ni Ikot Ewa, ni ijọba ibilẹ Akpabuyo nipinlẹ naa.

Ẹni kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Otunba Charles Edem, sọ fun BBC pe akẹkọọ naa mu ibọn ọhun lọ ile iwe lati yin lu olukọ rẹ kan to paṣẹ fun pe ko lọ ge irun ori rẹ.

O ni "Lọsẹ to kọja, olukọ rẹ kan sọ fun pe ko lọ ge irun to wa lori rẹ nitori o lodi si ofin ileewe wọn."

"Ṣugbọn ka to wi ka to fọ, niṣe lo mu ibọn wa sile iwe naa lọjọ keji lati yin olukọ naa nitori ọrọ to sọ si."

Àkọlé fídíò, Oladele Ogbeyemi Albert: Irin tí mò ń lò máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀mí kí ń tó gbẹ́ wọn sóh

Edem tẹsiwaju pe adari ileewe ọhun lo kọkọ ṣakiyesi rẹ to si figbe ta, eyii to mu awọn olukọ to ku atawọn akẹkọọ miran da si ọrọ ọhun.

Edem ni oun lọ ṣabẹwo si ọrẹ oun kan to n gbe lagbegbe ti ileewe naa wa ni oun gbọ ti awọn eeyan n pariwo, ti oun si lọ wo ohun to ṣẹlẹ ti oun si gbọ si ọrọ naa.

Nigba ti wọn bere lọwọ ọmọdebinrin naa bo ṣe ri ibọn ilewọ, o ṣalaye pe baba agbalagba kan lo fun oun ni ibọn naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà