Insecurity: Abdulsalami Abubakar kìlọ̀ pé Nàìjíríà lè pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ bí nǹkan ṣe ń lọ

Oríṣun àwòrán, @Abdulasalam
Ẹ fura o! Nàìjíríà ń pín lọ díẹ̀ díẹ̀ rèé- Abdulsalami.
Aarẹ ologun orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ ri, Ajagun fẹyinti Abubakar Abdulsalami ti kilọ pe afaimọ ki Naijiria ma pin tawọn eeyan ko ba semedọ.
Abdulsalami rọ awọn ọmọ Naijiria to n da rogbodiyan silẹ pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Lori aawọ to n ṣẹlẹ lawọn apa orile-ede yii kan, Abdulsalami kepe awọn gomina lati wa egbo dẹkun fáwọn ohun to le jẹ ki orilẹ-ede Naijiria pin.
- Akẹ́kọ̀ọ́ 27, òṣìṣẹ́ méjì àti mọ̀lẹ́bí méjìlá ni àwọ́n agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano ṣèrànwọ́ ₦18.5m fún àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ rẹ̀ tó faragbá nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa
- Kíní ìtumọ̀ àyájọ́ Ọ̀jọ ''Ash Wednesday' tó wáyé lóní?
- Wo ohun 10 tó yẹ́ kó mọ̀ nípà Ọ̀gà EFCC, Abdulrasheed Bawa tí ààrẹ̀ Buhari yàn
- Wo àwọn ohun méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ngozi Okonjo-Iwealla àti ọkọ rẹ̀ Ikemba
Abdulsalami ni "iṣẹlẹ ijinigbe, idigunjale ati igbesunmọmi n dakun iṣoro orilẹ-ede Naijiria."
Abdulsalami to jẹ alága igbimọ to n lepa alaafia ni Naijiria sọ fawọn akọroyin pe awọn ọmọ Naijiria ni lati fọwọ so ọwọ pọ lati le bori awọn ipenija to n dojukọ kọ ilẹ naa bayii.
"Ni bíi ọsẹ meji sẹyin bayii, aawọ to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria n ṣafihan pe ìyapa n bọ ti a ko ba kiye sara," Abdulsalami lo woye bẹẹ.
Abdulsalami ni: "Awa igbimọ pẹtu sí aawọ ni Naijiria n fi akoko yii rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ṣemẹdọ lasiko yii," Abdulsalami lo sọ bẹẹ.
Olori ijoba ologun Naijiria tẹlẹ sọ pe asiko yii kii se asiko ti "a le maa sọ aṣiṣe ara wa."
O ni ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo ti di alai nile lori mọ ni Naijiria nigba t'awọn kan sì wà ní agọ ogun le n de nitori rogbodiyan to n ṣẹlẹ.
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
- Àyè wà fún àwọn Fulani tí kíì ṣe ọ̀daràn láti wá fi ilú Iwo ṣebùgbé - Oluwo
- Ìdí rè é tí adájọ́ fí yọ ọba bí jìgá ní ìlú Ọyọ́...
- Agbaṣẹ́ṣe jẹ búlálà méjìlá lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Ṣàngbá fọ́! Mbappe pòkọ ìyà fún Messi àti Barcelona mu ní Nou Camp
Abdulsalami ṣọ pe awọn ọmọ Naijiria gbọdọ wa ni iṣọkan lati bori gbogbo aawọ to n ṣẹlẹ bayii.
Bakan naa lo rọ awọn olori ileeṣẹ ologun ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣẹṣẹ yan sipo lati fori kori wa ojutuu sí eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.


















