Agbaṣẹ́ṣe jẹ búlálà méjìlá lẹ́yìon tó jí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí iye rẹ̀ tó ₦56,000

Oríṣun àwòrán, @OnwardNG
Ile ẹjọ majistrati kan niluu Kaduna ti dajọ pe ki wọn na agbaṣẹṣe kan, Shehu Abbas lẹgba nigba mejila lẹyin to jẹbi ẹsun jiji ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti iye rẹ to ₦56,000.
Wọn ṣe idajọ naa fun Abbas lẹyin to jẹwọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Adajọ ilẹ ẹjọ naa, Ibrahim Emmanuel sọ pe, idajọ ọhun yoo kọ awọn ẹlomiran to n gbero ati wu irufẹ iwa bẹẹ lọgbọn.
Lẹyin naa lo ke si meji lara awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ naa lati na Abbas lẹgba.
Ṣaaju ni olupẹjọ, Chidi Leo ti kọkọ sọ fun ile ẹjọ naa pe obinrin kan, Sarah Augustine, lo gbe ẹjọ ọdaran naa wa si agọ awọn ọlọpaa to wa ni Sabon Gari, lọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun yii.
Gẹgẹ bi ohun ti Leo sọ, ọdaran naa wọ inu ṣoọbu Sarah to wa lagbegbe Kawo lọ, o si ji ẹrọ ilewọ Tecno naa ti iye rẹ to ₦56,000.
O fikun pe ọwọ tẹ ọdaran ọhun lẹyin ti ẹrọ ibaraẹnisọrọ ọhun dun ninu apo rẹ nigba ti ipe kan wọle sori rẹ, to si gbiyanju lati na papa bora ṣugbbọn o ti bọ sori fun un.
Olupẹjọ naa sọ pe ohun ti Abbas ṣe lodi si ofin to rọ mọ iwa ọdaran, abala 271 ti ipinlẹ Kaduna ti wọn gbe kalẹ lọdun 2017.
- Kíni àwọn gómínà láti Àríwá Naijiria sọ lórí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Shasha?
- Mo ṣetán láti tún àwọn ilé tó jóná ní ọjà Shasha kọ́- Makinde
- Nigeria Army recruitment 2021: Ẹ wo bí ẹ ṣe lè darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ Ọmọogun Nàìjíríà
- Ọ̀gá àgbà ileeṣẹ ọlọpaa fi àwọn ọlọ́pàá kògbérégbè ṣowọ́ sí ìpińlẹ̀ Oyo lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa













