Olupelumi Fagboyegun, Rotimi Akeredolu: Iléẹ́jọ́ ìpínlẹ̀ Ondo ní ìgbẹ́jọ́ ṣì ń lọ lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Twitter
Ileẹjọ giga nipinlẹ Ondo ni ibanilorukọjẹ ni o waye pẹlu iroyin to gba ẹrọ ayelujara kan pẹlu arakunrin Olupelumi Fagboyegun.
Arakunrin Fagboyegun ni olori ẹka eto idajọ nipinlẹ Ondo, Olanrewaju Akeredolu to jẹ ibatan oun kọ lati tu oun silẹ lẹyin ti wọn ti oun mọle lori ẹsun pe o fa rogbodiyan ni ile baba rẹ.Ẹ bá mi bẹ olórí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Ondo, Olanrewaju Akeredolu kó tú mí sílẹ̀ ní àtìmọ́lé - Ìbátan Akeredolu
Ninu atẹjade ti wọn fi lede, Oṣiṣẹ agba ni ileẹjọ giga naa, Abilẹkọ Bolatito Ajibade ni ibanilorukọjẹ ni ọrọ naa ti ko si si otitọ kankan ni bẹ.
O ni ko si aridaju nipa ẹsun o fi kan Abilekọ Akeredolu, ati wi pe ileẹjọ ko fi igba kankan fi si ẹwọn ri lati igba ti igbẹjọ rẹ ti bẹrẹ ni Ọjọ Kọkandinlogun, Osu Kẹta, ọdun 2018.
Atẹjade naa ni ọjọ ti wọn bẹrẹ igbẹjọ rẹ naa ni wọn gba beeli rẹ, ko to di wi pe wọn tun fi panpẹ ọba mu leekẹji lẹyin to rekọja ofin to de beeli rẹ.
Wọn ni titi di asiko yii, igbẹjọ rẹ ṣi n lọ lọwọ, ti wọn si tun pe ẹjọ rẹ ni Ọjọ Kọkanla, Oṣu Keji, Ọdun 2021.
Nitori naa wọn kesi awọn eniyan lati jawọ ninu pinpin fidio ibanilorukọjẹ naa kaakiri nitori o rufin lati ma a sọrọ nipa ẹjọ to wa ni ileẹjọ.
Bakan naa ni wọn fi da awọn araalu loju wi pe, idajọ otitọ yoo jọba lori iṣẹlẹ naa nitori idajọ ododo ni igbẹkẹlẹ awọn ni ẹka ileẹjọ ipinlẹ Ondo.
Lara ẹsun ti arakunrin Fagboyegun fi kan ileẹjọ ipinlẹ Ondo ni pe wọn dena oun lati ri awọn ebi oun to wa ni okeere lati bi ọdun mẹta bayii.
Ẹ bá mi bẹ olórí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Ondo, Olanrewaju Akeredolu kó tú mí sílẹ̀ ní àtìmọ́lé - Ìbátan Akeredolu
Ijọba ipinlẹ Ondo ti dasi ẹsun ti arakunrin Olupelumi Fagboyegun fi kan olori ẹka eto idajọ nipinlẹ Ondo, Olanrewaju Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Google
Arakunrin Fagboyegun ni arabinrin naa jẹ ibatan oun ni ati ọdọ baba oun.
O ni Akeredolu fi panpẹ ọba mu oun lati bi ọdun mẹta ṣẹyin lori ẹsun pe oun wa si ile baba oun, ti wọn si ti oun mọle lati igba naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Olupelumi Fagboyegun ni ẹsun ti wọn fi kan oun ni pe, oun wa si ile baba oun
Bakan naa ni o fẹsun kan ijọba ipinlẹ Ondo wi pe wọn ko le ran oun lọwọm nitori oṣelu mọlẹbi ni gomina n ṣe.
Ni bayii, gomina ipinlẹ Ondo ti fesi pe kọmisọnna fun eto idajọ nipinlẹ Ondo, Charles Titiloye ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni ijọba fikun wi pe awọn yoo ri wi pe eto idajọ ododo gbalekan nipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, @Akeredolu
Nitori awọn gbagbọ wi pe olootọ ko gbọdọ ku si ipo ika gẹgẹ bi ofin ṣe gba laaye.
- Ọ̀gá àgbà ileeṣẹ ọlọpaa fi àwọn ọlọ́pàá kògbérégbè ṣowọ́ sí ìpińlẹ̀ Oyo lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé ní Sasa
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé sáà ìjọba tiwantiwa yìí
- Àwọn darandaran gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta níjọba ìbílẹ̀ Ariwa Yewa lẹ́yìn àbẹ̀wò àwọn aṣojú ìjọba ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Mo ṣetán láti tún àwọn ilé tó jóná ní ọjà Sasa kọ́- Makinde
- Wọ́n ti kéde Ngozi Okonjo Iweala gẹ́gẹ́ bíi alákóso WTO















