Fulani herdsmen attack: Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu ọba ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé
Awọn janduku kan ti wọn funra si pe wọn jẹ darandaran ti ṣekupa eeyan mẹta o kere tan lagbegbe Agon-Ojodu, ni ijọba ibilẹ Ariwa Yewa, nipinlẹ Ogun.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin wakati diẹ ti awọn aṣoju ijọba ipinlẹ naa ṣabẹwo sagbegbe ọhun, paapaa afin ọba Olu Ilaro, Ọba Kehinde Olugbenle, lati jiroro lori eto abo to mẹhẹ.
Lara awọn awọn to ṣoju ijọba ipinlẹ Ogun lọ si agbegbe naa ni Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Edward Ajagun, kọmiṣọna fun eto iroyin, kọmiṣọna fun ọrọ oye jije, awọn oṣiṣẹ eleto abo ati ileeṣẹ ologun, atawọn eekan miran nipinlẹ Ogun.
- Wo ohun tí Seyi Makinde, Akeredolu fẹ́ ṣe fún àwọn tí wàhálà ọjà Sasa kàn
- A ṣetán láti ṣèwádìí àwọn ọlọ́pàá tó fìyà jẹ àwọn tó ṣewọ́de ní Lekki tollgate- Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá
- Ebola tún dé sílẹ̀ Adúláwọ̀, kí ní ṣíṣe?
- Mọ̀ síi nípa àwọn ohun tó lè mú kí èèyàn tètè ní irun funfun lórí láì tíì di arúgbó
- Ìjà tó wáyé ní Sasa ní Ibadan kìí ṣe ti ẹlẹ́yàmẹ̀yà- Agbẹnusọ ọlọ́pàá
Gẹgẹ bi ohun ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Ogunyemi, sọ fun BBC, o ni "ko ju nnkan bii wakati kan ti a kuro nibẹ ti a gbọ iroyin pe wọn tun ti pa awọn eeyan mẹta miran nibẹ."

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun - MFR
Abimbola sọ pe bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii ri ẹnikẹni gbamu gẹgẹ bii afurasi lori isẹlẹ naa, o ni wọn ti ko awọn ọlọpaa kogberegbe lọ si ilu naa lati dabo bo awọn eeyan to wa nibẹ.
O ni iwadii wọn fi han pe inu igbo nla kan ni awọn aṣekupani ọhun ti n wa.
Abimbola fi kun pe inu ileeṣẹ ọlọpaa ko dun si iṣẹlẹ iṣekupani to n waye ni ipinlẹ Ogun, ṣugbọn iṣẹ ti n lọwọ lati rẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Ọba ilu Iselu, Ọba Akintunde Akinyemi ṣalaye fun BBC pe yatọ si eeyan mẹta ti awọn darandaran naa pa, o ni wọn tun jo ẹnikan mọle.
O ṣalaye pe"bi awọn aṣoju ijọba ṣe lọ tan bayii ni awọn Fulani lọ si Agbon Elere ti wọn si pa eeyan mẹta, wọn lọ si Asa, wọn jo ile gbogbo awọn agbẹ ati adele Asa, wọn tun jo eeyannkan mọle nibẹ."
Ọba Akintunde sọ pe ọdọdun ni awọn Fulani ọhun maa n pa awọn eeyan agbegbe oun bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni dukia kankan nibẹ.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ko tii ri ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa lagbebe ọhun, lẹyin naa lo sọ pe awọn funra wọn yoo gbena woju awọn Fulani ọhun funra wọn lapẹ ti ijọba ko ba wa wọrọkọ fi ṣ'ada.
- Ṣé ìyàwó ilé tàbí àlè níta ló yé kí ọkùnrin lo 'Valentine' rẹ̀ pẹ̀lú?- Mercy Aigbe
- Lọ́jọ́ Valentine, ààrùn COVID-19 pa èèyàn márùn ún ní Nàìjíríà
- Gómìnà Borno fi ọkọ̀ àti N13.9m dá Dókítà Akinbode lọ́lá fún ìṣẹ́ takuntakun ní iléèwòsàn ìjọba ní Borno
- Ìjọba Nàìjíríà tó yé kó pèsè aàbò ló kùnà lẹ́nú ojúṣe wọn- Mr Macaroni lẹ́yìn tó ti àtìmọ́lé dé
















