Grey Hair, Health: Wo àwọn ohun tó lè mú kí èèyàn tètè ní irun funfun lórí láì tíì di arúgbó

irun funfun

Oríṣun àwòrán, others

Pupọ èèyàn ló gbagbọ pe irun funfun jẹ ami pe agba ti n de, ṣugbọn awọn eeyan kan máa n ni irun funfun ki wọn tó dàgbà.

Awọn miran ẹwẹ máa n ni irun funfun lẹyìn tí wọn bá kọja ogun ọdun soke, ti wọn a sì máa woye idi tó ṣe rí bẹ fún wọn nigba ti ko ri bẹ fún àwọn ẹlòmíràn tó sún mọ wọn.

Laye isinyi, awọn miran a ma pa irun wọn laro funfun funra wọn laiṣe pe o jẹ amutọrunwa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn awọn onimọ ijinlẹ ti salaye awọn idi ti èèyàn fi lè máa ni irun funfun láì ṣe pé bóyá wọn ti dàgbà, lara èyítí wọn ni o le jẹ mọ ilera irufẹ ẹni bẹẹ tabi ajogunba.

Wo diẹ lara awọn ìdí tí èèyàn fi lè nirun funfun láì tíì dàgbà.

Arun ọkàn àwọn ọkùnrin

Ìwádìí kan ti iwe iroyin to n rí sì ìlera ọkan ṣe ni Egypt fi hàn pé ti tètè nirun funfun le ni nnkan ṣe pẹlu arun ọkan fún àwọn ọkùnrin.

Ìwádìí náà lo awọn ọkunrin 545, esi ìwádìí náà si fihan pe pupọ nínú àwọn tó ní àrùn ọkàn nínú àwọn ọkùnrin náà ni irun wọn funfun ju awọn ti ko ni àrùn ọkàn lo.

Àkọlé fídíò, Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid

Faitamin ti ko to lara:

Ìwádìí ìmọ ijinlẹ ti fi hàn pé èèyàn lè tètè ni irun funfun ti ohun elo amaraji pẹpẹ Vitamin B12 ko ba to nnkan lara rẹ.

Gẹgẹ bí ìwádìí tí International Journal of Trichology ṣe ṣe ṣafihan rẹ, bi vitamin D3, serum calcium ati serum ferritin ko ba to lára, èèyàn yóò tètè máa ni irun funfun.

Àkọlé fídíò, World health day 2020: Kí làwọn iléèwòsàn ń ṣe láti dáàbò bo ara wọn

Wàhálà àṣejù:

Ìwádìí ijinlẹ lati fasiti Harvad ti fihan pe ti èèyàn bá n ṣe wàhálà púpọ ju, o le jẹ kí irufẹ ẹni bẹẹ tete ni irun funfun.

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife

Èròjà tó n dabo bo ara:

Lara awọn ohun tó lè mú kí ọdọ l'angba tètè ni irun funfun ni ti aarẹ ba ti ba awọn sọja to n gbogun ti arun ninu agọ ara rẹ.

Àbínibí:

Awọn kan wà to jẹ pe àìsàn kankan ko se wọn ṣugbọn ti tètè nirun funfun jẹ abinibi fún wọn.

To n túmọ sí pé ti òbí eeyan ba tete ni irun funfun, o ṣeéṣe kí irufẹ ẹni bẹẹ náà tètè ni irun funfun nítorí inú ẹjẹ lo wà.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Siga mímu:

Ìwádìí kan ti Indian Dermatology Online Journal se fihan pe awọn tó máa n mu siga tàbí ẹni tó ti mu siga dáadáa tẹlẹ ri lè tètè ni ewu lórí ṣáájú ẹni tí kii mu siga rara.

Bakan naa ni iwadi ọhun tun fidi rẹ mulẹ pe siga mímu le mú kí èèyàn tètè di apari ọsan gangan.