Olaiya Igwe: Mo ti ṣetán láti dòwòpọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ Netflix láti gbé fíìmù mi tó ń bọ̀ jáde

Oríṣun àwòrán, olaiyafilmscompany
Agba oṣere tiata Yoruba, Ebun Olyede, ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe ti sọ pe oun ti n gbaradi lati ba ileeṣẹ Netflix dowopọ.
Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin, Olaiya ni oun ti bẹrẹ ijiroro pẹlu ileeṣẹ naa lati gbe fiimu oun to n bọ jade lori ikanni naa.
Olaiya sọ pe ọdun 2008 ni oun ti gbe fiimu jade kẹyin lẹyin ti oun padanu obitibi owo ti iye rẹ fẹẹ to aadọta miliọnu naira nitori awọn to n gbe ẹda fiimu naa jade.
- Olaiya Igwe ò kú o, àyè ló wà
- Eré wa ni kẹ wò, ẹ má wo aṣemáṣe àwa onítíátà - Olaiya Igwe
- Ọba alayé kan àti gómìnà kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi, kí n tó fẹ́ Mr Lawal - Lizzy Anjorin
- Yomi Fabiyi tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Iyabo Ojo torí aáwọ̀ ààrin wọn, ọ̀pọ̀ ní ìwà ojo ló hù
- Ọpọ Obìnrin ní inú wọn kún fún ìbànújẹ lásìkò yìí nítorí wọn kò yó ìfẹ lónà tó yẹ- Tonto Dikeh
- Goriola Hassan, má pe ara rẹ ní ọba Imobi-Ijebu mọ́, bí bẹ́ẹ̀kọ́... - Ilé aṣòfin Ogun
Nigba to n ba iwe iroyin The Nation sọrọ, Olaiya Igwe ni "Mo ti n mura lati gbe fiimu kan jade lori Netflix, eyii ti yoo milẹ titi."
"Arakunrin mi, Femi Adebayo ṣẹṣẹ gbe fiimu kan jade lori Netflix to pe ni Ogundabede, iriri mi nigba ti a n ya fiimu naa jẹ ohun iwuri fun mi lati gbe sinima mi to nbọ jade lori ẹrọ Netflix."

Oríṣun àwòrán, olaiyafilmscompany
Igwe tẹsiwaju pe "Ootọ ni pe mo ti ṣiṣẹ kan to lamilaaka lọdun 2008, eyii ti mo na owo to le ni aadọta miliọnu naira le lori, ṣugbọn ti di itan."
"Lọwọ ti a wa yii, ti eeyan ba ṣe sinima to ba igba mu, sinima ọhun ni lati wa ni ibamu pẹlu awọn alakalẹ ileeṣẹ Netflix."
Olaiya sọ pe ọdun 2008 naa ni oun gbe sinima jade kẹyin, iyẹn lẹyin to padanu owo gọbọi lori sinima ọhun nitori awọn to gbe ẹda rẹ jade lọna ti ko ba ofin mu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sapara-Williams: Ọmọ Oòduà tó kọ́kọ́ dábàá pé kí ilẹ̀ Yorùbá dúró lábẹ́ àkóso kan ṣoṣo
- Wo ohun tó ṣe kí àtọ̀ rẹ fi ní agbára láti di ọmọ
- Orí afárá ni mo sì ti ń wẹ̀ l'Ojuelegba, ilé àkọ́kù ni mò ń gbé tẹ́lẹ̀ - Whitemoney
- Wo ànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Ẹ̀yin agbébọn, ajínigbé àti ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀, ìjọba mi yóò fimú yín dárin - Buhari
- Wo ìye owó tí lítà epo pẹtirólú kan yóò jẹ́ lẹ́yìn ìpàdé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba
- "Inú òjò ní mo sùn fún wákàtí 48 pẹ̀lú ebi ní àhámọ́ ajinigbé"
Ni ti awọn fọnran ti Olaiya ti n kopa lori Instagram pẹlu awọn gbajumọ bii Mr Maccaroni, Yemi Eleso ati bẹẹ bẹẹ lọ, o ni awọn ọjẹ wewẹ naa lo maa n pe oun lati ba awọn ṣere, inu oun si dun lati ba wọn ṣiṣẹ pọ.
O ni "Mo ni lọkan lati gbe awọn fọran apanilẹrin jade lori Instagram laipẹ, ṣugbọn lọwọ yii mo ṣi n ba awọn ọmọ mi ṣere lọwọ."
"Maccaroni jẹ ọkan lara awọn ọmọ mi nidi iṣẹ tiata, o ke si mi, mo si ba ṣe ere papọ."
"Bakan naa ni Abiola ti ọpọ mọ si Lawyer Kunle, to fi mọ Yemi Eleso, niwọn igba to ba ti jẹ ere ori itage naa ni wọn n pe mi si, ko si eyii ti mi o le ṣe nibẹ."
Olaiya Igwe pari ọrọ rẹ pẹlu imọran pe ki awọn oṣere to jẹ ọjẹ wẹwẹ ṣugbon ti irawọ wọn ti tan, maṣe tẹ aṣọ awọn agba oṣere mọlẹ ko le yẹ wọn titi di ọjọ alẹ ninu iṣẹ naa.



















