Baba Ijesha: Ebun Oloyede ní àwọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN ní ẹgbẹ́ fòfin dè láti máṣe bá Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing ṣiṣẹ́ papọ̀

Olaiya Igwe

Oríṣun àwòrán, NaijaExpress.com

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Ebun Oloyede, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Olaiya Igwe ti sọ pe, ẹgbẹ awọn ko lagbara lati fofin de Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo lẹyin ti wọn ri awọn agba ẹgbẹ naa fin.

Olaiya lo ṣiṣọ loju ọrọ naa lori eto kan to ti fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu BBC Yoruba.

Igwe ṣalaye pe niwọn igba ti awọn oṣere naa kii tii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn, iyẹn TAMPAN, awọn ko le fofin de wọn lati ma ṣere mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn o ṣalaye pe ẹgbẹ ọhun ti paṣẹ pe ẹnikẹni ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ko gbọdọ ba eyikeyi ninu Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing da iṣẹ pọ mọ fun saa yii.

O ni "Oṣere tiata ni wọn, ṣugbọn wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, nitori naa ẹgbẹ wa ko le fofin de awọn memeji."

Olaiya Igwe

Oríṣun àwòrán, @olaiya_igwe01

"Ṣugbọn iru emi ti mo n ba yin sọrọ yii atawọn ọmọ ẹgbẹ ti orukọ wọn wa ninu iwe ẹgbẹ wa, ni wọn fofin de lati mase ba Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo ṣiṣẹ mọ."

Ṣaaju ni Nkechi ati Iyabo ti kọkọ sọrọ kobakungbe si awọn agba ẹgbẹ TAMPAN loju opo Instagram wọn, lori awọn ọrọ kan to ti ṣẹlẹ ṣaaju, paapaa lori ọrọ baba Ijesha.

Ẹwẹ, ni ti ijiya to wa fun awọn oṣẹre tiata Yoruba to ba tasẹ agẹrẹ, Olaiya sọ pe Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Bola Amusan, ta tun mọ si Mr Latin, nikan lo le sọ irufẹ ijiya to yẹ fun wọn.

Olaiya sọ pe awọn idanilẹkọ maa n waye ninu ẹgbẹ TAMPAN, nibi ti wọn ti maa n ba awọn oṣere sọrọ lori bo ṣe yẹ ki wọn ṣe maa ṣe lawujọ, ṣugbọn onikaluku ni yoo mọ bi yoo ṣe maa ko ara rẹ ni ijanu.

Àkọlé fídíò, Loni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni wọn o tun gbe oṣerekunrin, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha, lọ si ile ẹjọ.

Ni ti afojusun rẹ fun ọjọ iwaju, Olaiya sọ pe ere ti oun yoo ṣe kẹyin yoo milẹ titi, koda aye yoo gbọ, ọrun yoo mọ pẹlu.

O ni yoo wu ohun ki sinima naa le wọ ori ẹrọ Ntflix, nibi ti awọn eeyan yoo ti le maa wo kaakiri agbaye, ati pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ere naa ni sinima ti oun yoo gbe jade kẹyin.

Lẹyin naa lo gba awọn ololufẹ tiata Yoruba niyanju lati maṣe maa wo awọn aṣemaṣe awọn oṣere, ṣugbọn ki wọn maa wo awọn ere wọn lati kọgbọn ati fun oniruru awokọṣe rere.

Àkọlé fídíò, Tunbosun Odunsin: Ẹlẹ́dàá ló fún mi ní tálẹǹtì ẹ̀kún sísun ní ìrọ̀rùn nínú eré tíátà