Nkechi Blessing: Jide Kosoko, pè mí ní ọmọ àlè tí Ọlọ́run kò bá ṣiṣẹ́ takò ọ́

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing Sunday
Awuyewuye laarin awọn oṣere tiata Yoruba tun ti ba ọna mii yọ lẹyin ti Nkechi Blessing sọ oko ọrọ si Jide Kosoko.
Kosoko lo kọkọ sọrọ ninu fidio kan eleyii tawọn agba ẹgbẹ TAMPAN bii Adebayo Salami ati Mr Latin wa lẹgbẹ rẹ pe, oun yoo lo gbogbo agbara oun lati ṣiṣẹ tako Blessing.
Eyi lo mu ki Blessing naa ja gudugbẹ ọrọ lulẹ pe, ti oun ba fi le tu aṣiri Kosoko sita, awọn ọmọbinrin rẹ yoo dọwọ boju ni.
- Dino Melaye sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló ní pẹ̀lú àwọn òṣèrẹ tíátà
- Olórin bíi Tiwa Salvage ni mo fẹ́ jẹ́ lọ́jọ́ ìwájú, ẹ má jẹ́ kí ń kú - Chidima afurasí apààyàn
- Àwọn àjẹ́ fọhún síta lórí ìgbésẹ́ àti pín Nàìjíríà sí wẹ́wẹ́
- Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà, TAMPAN fọnmú mọ́ Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing lọ́wọ́
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
Nkechi fi aake kọri, o ni, ''iwọ fẹ ṣiṣẹ tako mi abi, iwọ ti o jẹ baba fawọn ọmọ tiẹ naa.
Ọlọrun mi yoo ṣiṣẹ tako iran diran rẹ ti wọn ko tii bi saye, ayafi ti o ba jade lati sọ ohun ti mo ṣe fun ẹ, ti o jẹ ẹṣẹ mi loku."

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Nkechi Blessing
Blessing tẹsiwaju pe bawo ni wọn ṣe fẹ da ẹni tii kii ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn duro lẹnu iṣẹ?
O ni ṣe kii ṣe oogun niyẹn? Fidio ti o ti sọrọ naa ti lu ori ayelujara pa.
"Ẹ jẹ ki a maa woo bọ bi Ọlọrun ko ba ni doju ti yin, ki ẹ pe mi ni ọmọ ale,'' Nkechi tutọ soke, o foju gba a.
Nkechi Blessing n kopa idije CCBNaija, o fẹ jẹ ọgọfa miliọnu naira
Ẹwẹ, Nkechi ti fi ọrọ ẹgbẹ TAMPAN ṣe afisẹyin ti eegun n fi aṣọ, o si tẹra mọ idije CCBNaija ninu eleyi ti o ti le jẹ ẹbun owo ọgọfa miliọnu naira(N120m).
N ṣe ni Nkechi mu orin bọ ẹnu, ti o si fi ijo bẹ lati fihan pe oun ṣetan lati jẹ ẹbun owo tabua naa lai naani idunkoko ẹgbẹ TAMPAN.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Gbajugbaja oṣere mii, Bolanle Ninolowo naa sọrọ lori idije CCBNaija, o ni iku nikan lo le ni ki oun maa sa gbogbo agbara oun lati jẹbun owo N120m to wa nilẹ.
Ninalowo ni asiko iku oun ko si tii to bayii nitori Ọlọrun ko tii fi aṣẹ sii.
Koda awọn oṣere nikan kọ ni yoo jẹbun ninu idije ọhun, ẹni ti o ba ni ibo to pọ julọ, naa yoo lanfaani lati jẹ ẹbun ile fulaati oniyara mẹta niluu Eko.

Gbàs gbós míì tún ti ń rúgbó bọ̀ láàrín Jide Kosoko ati Nkechi Blessing

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe agbo osere tiata lorileede Naijiria ti n yọ eruku lala pẹlu bi awọn oṣere meji to gbajumọ kan ṣe láwọn ṣetán láti naa tan bi owo pẹlu arawọn.
Itahunsiraẹni yi ko si sẹyin wahala ọrọ Baba Ijesha ati awọn to ni dandan ko foju wina ofin lori ẹsun ti wọn fi kan pe o ṣẹ aṣemaṣe pẹlu ọmọde.
Awọn oṣere ti o wa lagbami surutu yi ni Nkechi Blessing ati agba osere nii, Jide Kosoko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
Bi ọrọ naa ṣe n lọ bayi, Nkechi ti tutọ soke foju gba to si n béèrè lọwọ Jide Kosoko pe ṣe o to bẹ lati fori ru wahala oun ti o ba delẹ tan.
Ọrọ Nkechi yi ko sẹyin bi Kosoko ti ṣe sọko ọrọ si Nkechi ati Iyabo Ojo nibi to ti n ba awọn akọroyin sọrọ.
Nibi taa n wí yí, Kosoko bẹnu atẹ lu awọn mejeeji pẹlu bi ọ ṣe ni wọn n dojú ìjà kọ àwọn akẹgbẹ wọn to tako bi wọn ṣe n tabuku Baba Ijesha lori ayelujara.
"A ti ni ki Nkechi Blessing lọ rọọkun nile.Kii ṣe ọmọ ẹgbẹ wa.Gbogbo ẹnu ni mo fi sọ, a ṣetan lati se alatako rẹ nidi iṣẹ wa yii"

Oríṣun àwòrán, AP
Jide Kosoko to jẹ aarẹ Egbe oṣere tiata TAMPAN ni awọn ko ni jẹ ki awọn mejeeji yi ri imu mi lagbo osere.
Oro ti Kosoko yi bi Nkechi ninu to sì ni "ṣe Jide Kosoko ṣetan lati fara gba wahala to n fa lẹsẹ bayi?"
Loju opo Insta stories rẹ ni Instagram Nkechi fi ikilọ sita fún Kosoko pe oun ri ọrọ rẹ gẹgẹ bi idunkoko mọ ẹni.
O ni ko fi ẹlẹ ṣe kí o ma ba fori ru igi oyin.
A ko ti gbọ ki Kosoko Fesi tabi ki Iyabo Ojo ti o mẹnu ba pẹlu Nkechi Blessing sọ nkankan lori ọrọ yi.
















