Kemisola Ogunniyi: Ọmọ tó bí sọ́gbà ẹ̀wọ̀n ló kọ̀kọ́ gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, kí ti ìyá rẹ̀ tó dé

Lati igba to ti gba itusilẹ nile ẹjọ, se ni idunnu ohun ayọ kan n ṣubu lù ara wọn fún Kemisola Ogunniyi.
Kemisola jẹ akẹkọọ ọmọ ọdun mejidinlogun ti ijọba sọ si ẹwọn pe o kopa ninu iwọde Endsars ni ipinlẹ Ondo.
Eyi taa tun ri gbọ laipẹ yii ni pe obinrin iya ikoko naa ti ri eto ẹkọ ọfẹ gba lọdọ ẹlẹyinju aanu kan.
Agbẹjọro rẹ, Tope Temokun lo fidi ọrọ yi múlẹ fun BBC Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
- Òwọ́n gógó epo bẹntiró ń kànlẹ̀kùn bí IPMAN ṣe ń múra láti daṣẹ́ sílẹ̀
- Á ba ọrọ̀ ajé Nàíjíríà jẹ́ nípa fífọ́ ọ̀pá epo rọ̀bí - Niger Delta Avengers
- Ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀pọ̀ farapa ní Mọ́ṣáláṣí l‘Osogbo lásìkò àdúrà ètò ààbò táwọn Egúngún ṣe
- Dino Melaye sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló ní pẹ̀lú àwọn òṣèrẹ tíátà
O ni ẹni tó ta Kemisola lọọrẹ yii jẹ alaanu, orukọ rẹ si ni Bamidele Omosehin, tii se oludasilẹ Bamidele Omosehin Foundation to sì jẹ ọmọ ipinlẹ Ondo.
Temokun salaye pe bayii, anfaani ẹkọ ọfẹ yii kan sisan owo idanwo Neco ati Idanwo igbaniwọle si yunifasiti ati owó ẹkọ rẹ titi ti yoo fi pari ile ẹkọ giga fasiti.
Ṣaaju ni ikoko Kemisola ti ṣe orire nipa bi eeyan kan ṣe fún ni anfaani ẹkọ ọfẹ lati ile ẹkọ akọbẹrẹ titi de ile ẹkọ girama.
Anfaani yii n waye lẹyìn osu mẹsan ti awọn agbofinro gbe Kemisola ati awọn oluwọde mii, to kopa ninu iwọde Endsars losu kẹwa odun 2020.
Kemisola ati awọn ti wọn mu la gbọ pe wọn dana sun olu ile ẹgbẹ oṣelu APC ni Akure.
Ọgba ẹwọn Surulere ni ijọba ibilẹ iwo oorun Ondo lo wa, tó sí bimọ si lọjọ kẹrindinlogun osu kẹfa.
Okiki Kemisola kan, t'awọn ọmọ Nàìjíríà sí gbarata pe ko dara bo ṣe bimọ si ẹwọn.
Ọrọ Kemisola dayọ ni ọjọ kejilelogun oṣù Kẹfà nigba ti adajọ ile ẹjọ giga gba beeli rẹ.
Ikomọjade fun ọmọ Kemisola waye lẹhin to gba itusilẹ ni ọjọ Kẹtalelogun oṣù Kẹfà ni Akure.














