Sunday Igboho: Kò sí ẹni tó ní kí ń má wá sí Eko tàbí pé wọ́n fẹ́ pa mí lásìkò ìwọ́de

Oloye Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1

Nibayii ti ipalẹmọ fun iwọde Yoruba ti yoo waye nilu Eko lọjọ Satide to n bọ ti doju ọgbagade, awọn eeyan kan ti n kọminu nipa iwọde naa.

Lero tawọn eeyan yii, o seese ki asiwaju kan ninu awọn eeyan to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba Nation, Oloye Sunday Igboho ma yọju silu Eko fun iwọde naa.

Awọn eeyan naa n kọminu lori idunkoko kan ti wsn ni awsn eeyan kan n se nipinlẹ Eko pe awọn ko fẹ ri awọn oluwọde Yoruba Nation kankan nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n fesi lori ero awọn eeyan yii, Sunday Igboho ti leri leka pe oun n bọ nilu Eko lọjọ Satide fun iwọde naa.

Igboho ni ẹfọ kii le ẹfọ lawo, ara ilẹ Yoruba ni ilu Eko wa, ko si si ẹni to le ni ki oun ma wa sibẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Igboho fi ọwọ idaniloju bẹẹ sọya lasiko to n tẹwọgba mọto kan tawọn eeyan kan ra fun iwọde Yoruba Nation.

O kede pe iwọde Yoruba Nation yoo waye gẹgẹ bi wọn se kede rẹ nilu Eko lọjọ Satide, ọjọ Kẹta osu Keje ọdun yii.

"Awọn eeyan kan n pariwo kiri pe ka mase wa silu Eko nitori pe wọn yoo pa wa, irọ nla ni.

Ko si ẹnikẹni to ni ki Igboho mase wa silu Eko, ko si si ẹni to sọ pe oun fẹ pa Sunday Igboho.

Ọmọ Yoruba pọnbele ni mi, ara ilẹ Yoruba si ni ipinlẹ Eko wa, kii se ilẹ Hausa tabi ti ẹya miran.

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

Ẹ mase jẹ ka maa tẹti si gbọyi-sọyi amọ ẹ jẹ ka gbajumọ bi iwọde to n bọ lọna nilu Eko yoo se ri."

Sunday Igboho fikun pe ẹru ko ba oun nipa iwọde naa bi o tilẹ jẹ pe o see see ki ootọ wa ninu ahesọ ọrọ naa.

O ni iwọde alaafia ni awọn n bọ wa se nipinlẹ Eko gẹgẹ bawọn ti se yika awọn ilẹ Yoruba miran, awọn si n seto itaniji ati ilanilọyẹ kiri ni.

O fikun pe awọn ko lọ silu Eko lati lọ da wahala silẹ tabi fa ijangbọn lẹsẹ rara.

Bẹẹ ba gbagbe, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ni oun ko setan lati gbalejo awọn oluwọde naa nipinlẹ Eko nitori ọkansoso ni orilẹede Naijiria.

Bakan naa nileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ni awọn oluwọde Yoruba Nation ko tii bun oun gbọ nipa iwọde ti wọn fẹ se ọhun.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba