Sunday Igboho - Àwọn tó n lépa mi n ṣe lásan ni, mí ò ṣe ẹ mú

Oríṣun àwòrán, Sunday igboho
Gbajugbaja ajijagbara nilẹ Yoruba, Sunday Adeyẹmọ Igboho ti sọ pe ko si ẹnikẹni to le mu oun.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin kan, Sunday Igboho, sọ pe gbogbo awọn to n dọdẹ ile oun lati mu u, kan n ṣe lasan ni.
O ni agbara ti oun ni pọ debi i pe ko si ipa ẹnikẹni to le mu oun tabi ka oun lapa ko.
Igboho ni agbara to pọ ni Ọlọrun fun oun.
"Awọn ọmọ Yoruba to mọ nkan ti mo le danwo, mọ pe mi o tiẹ ti i bẹrẹ ija rara."
Igboho fikun ọrọ rẹ pe oun ni agbara lati wọ inu ile eeyan lai ṣi ilẹkun.
"Ọwọ baba mi ni mo ti jogun agbara ti mo ni. Mi o si fi ba ẹnikẹni ja ri."
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Wo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń ti Sunday Igboho lẹ́yìn bí i iké
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
Ọpọlọpọ igba ni iroyin ti jade pe Igboro ni ọpọlọpọ agbara ibilẹ, eyi to gbojule lati ma a ṣe awọn nkan to n ṣe.
Lori iroyin kan to n lọ kaakiri pe awọn oloṣelu kan lo n fun Igboho ni owo lati ma a polongo fun idasilẹ Oduduwa Republic, Sunday Igboho sọ pe oun ko gba owo lọwọ oloṣelu kankan ri.
O ni oun pe oloṣelu yoowu to ba ti fun oun lowo ri, ti oun ko si sọ ni gbangba, nija, lati wa a sọ ni gbangba.
Bakan naa lo sọ pe oun ko tẹwọ gba owo kankan ti wọn ni awọn eeyan kojọ fun -un lori ayelujara.
Amọ, o ni awọn eeyan kan, to fi orukọ bo ni aṣiri, n fun oun lowo lati ma a gbogun ti awọn Fulani to wa ni ilẹ Yoruba.
- Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Kayode Badru ṣe ṣẹlẹ̀ ní Celestial Church of Christ ni Eko? ẹ wo ohun tí a mọ̀!
- Àṣìṣe dókità ló pa Peju, ìbànújẹ́ dorí àgbà kodò- Funke Akindele
- Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé...
- Sadiq Khan jáwé olúborí di 'Mayor' lẹ́ẹ̀kejì ní London
- Rọ́kẹ̀ẹ̀tì China ti balẹ̀, orí omi Indian Ocean ló já sí!- Iléeṣẹ́ ìròyìn China
- A kò ní pe Ọlọ́run ní ẹjọ́ lórí ìkú ọmọ wa, Dare Adeboye - Ẹbí Adeboye
















