Chinese rocket: Orí omi Indian Ocean ni wọ́n ti ri àjákù Rọ́kẹ̀ẹ̀tì China tó já náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Jonathan Amos
- Role, BBC Science Correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Iléeṣẹ iroyin India ti kede pe wọn ti ri ajaku rọkẹẹti China ti aye n pariwo pe o fẹ ja naa.
Wọn ni ori omi Indian Ocean ni wọn ti rii nigba to pada ja si aye.
A dupẹ pe rọkẹẹti yii ko pada ja si aarin ilu nibi ti aye ti n bẹru ipalara pupọ.
Ṣaaju ki o to ja ni awọn onimọ onwoye lati ilẹ Amerika ati Yuroopu ti n woye ibi ti yoo kangu si ni agbaye.
Wọn ni wọn ti n gbiyanju lati pa run ko to tun di pe ageku ejo rẹ pada wa saye lọjọ Aiku to kọja ni Beijing ni China
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
- Mo fẹ́ ìyàwó méjì lọ́jọ́ kan ṣoṣo láti ṣe ju ohun tí bàbá mi gbé ṣe - Uloho Othuko
- Pásítọ̀ pín ounjẹ iṣínu àwẹ̀ Ramadan fún àwọn Músùlùmí
- Ikọlù agbébọn tó jó ilé Gómìnà ìpínlẹ̀ lọ́wọ́ òṣèlú nínú-Ìjọba Imo
- Ǹkan dé o! Àwọn jàndùkú tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méje lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun ọkọ̀ wọn
- Sẹ́nẹ́tọ̀ Ademola Adeleke kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní fásítì l'Amerika
Kini o ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Chinese tú Rọ́kẹ́ẹ̀tì ńlá sílẹ̀ tí yóò tó balẹ̀ s'áyé - Eko, New York àtàwọn ìlú míì ló leè jábọ́ sí
Lagos, New York wà lára àwọn ìlú tí wọ́n dárúkọ pé ó leè tẹ́rí gba Rọ́kẹ́ẹ̀tì China tó wà lójú ọ̀run
Ọkan lara awọn Rọkẹẹti nla orilẹede China ni wọn n reti ko bọ sori ilẹ aye nitori idi kan ti wọn ṣalaye pe airibi ṣamojuto irina rẹ.
Ni iwọn toonu mejidinlogun, ọkan lara awọn Rọkẹẹti to tobi ju fun ọpọlọpọ ọdun ni iwadii fihan pe o fẹ ṣi ọna yii.
Ilẹ Amẹrika sọ lọjọ Iṣẹgun pe awọn n woye ọna ti Rọkẹẹti naa ngba bọ ṣugbọn wọn ko ni erongba lati da ibọn bo o.
"A ni ireti pe yoo balẹ si ibi ti ko ti ni pa ẹnikẹni lara," akọwe ileeṣẹ abo l'Amẹrika, Lloyd Austin lo sọ bẹẹ. "Ireti wa pe boya ninu ko balẹ sinu omi nla tabi iru ibi bayii kan naa".
Oniruuru awọn akọṣẹmọṣẹ to n wo inu ofurufu n tọka si ọwọ irọlẹ tabi alẹ jọ Abamẹta tabi owurọ kutu ọjọ Aiku gẹgẹ bi akoko to ṣeeṣe ko balẹ.
Amọ, iru awọn iwoye bayii lee ma ri bẹẹ nigba miran.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹrin gangan ni Rọkẹẹti "elliptical orbit" ti iwọn ibi to wa bayii to 160km si 375km ga ju aye lọ ṣugbọn to ti n kuna bayii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Kí ni yoo ṣẹlẹ bi Rọkẹẹti yii ba balẹ si aye?
Gbogbo ọkọ lo yẹ ko fẹrẹẹ jona raurau nigba to ba fi gunlẹ latinu afẹfẹ, bo tilẹ jẹ pe o maa n ṣeeṣe ki o ni awọn irin to lee yọ́ lara atawọ́n afaragbaya mii ti yio fi ye bibalẹ rẹ.
Pe o ṣeeṣe ki apa kan tabi omiran lara ara rọkẹẹti ti yoo tuka ta ba eeyan ko fi bẹẹ ri bẹẹ, nitoripe ọp aaye lori aye lo jẹ omi nla ati pe apa ibi ti yoo balẹ si kii fibẹ jẹ ibi ti awọn eeyan n gbe.

Oríṣun àwòrán, Twitter/The Aerospace Corporation
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
- Ẹbí Adeboye kéde bí ìlànà ikú Pásítọ Dare yoo ṣe lọ
- Akeredolu, jọ̀ọ́ gba iṣẹ́ lọ́wọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ tó lu aláboyún - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yarí
- Àwọn Ọba tí kò bọ̀wọ̀ fún ìṣẹ̀ṣe ni wọ́n ń jí gbé - Ọwá Oòyè Okemesi
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
Wo Fọ́to Rọkẹẹ́ti China ọhun

Ki ni China sọ?
china ti fariga pe awọn eeyan n sọ pe awọn ko naani mimoju to iru nkan nla bayii to ṣina.
Awọn eeyan n gbe iroyin oniruuru ijamba ti iṣẹlẹ yii le ṣẹlẹ.
Ẹw, loju opo ayelujara orilede naa, wn ti ṣapejuwe awọn iroyin to n kari aye pe wọn kan n pọn n lasan ni. Ni tiwọn, wọn woye pe Rọkẹẹti naa ṣeeṣe ko balẹ sinu omi nla nla kan.
















