Muhammadu Buhari: Àwọn ẹni ibi kan ń wá gbogbo ọ̀nà láti tú orílẹ̀èdè Nàíjíríà ká - Ààrẹ́ Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Presidency
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ke gbajare pe awọn kan n gbe igbese lati ba gbogbo igbiyanju ijọba jẹ lori eto aabo to dẹnukọlẹ.
Buhari lo sọ bẹẹ lasiko ipade rẹ pẹlu ajọ oludamọran pẹlu aarẹ Buhari lori ọro aje.
Ajọ naa sọ fun aarẹ Buhari pe eto aabo to dẹnukọlẹ gan an lo ṣokunfa eto ọrọ aje ti ko gbe pẹẹli soke ni Naijiria.
- Akeredolu, jọ̀ọ́ gba iṣẹ́ lọ́wọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ tó lu aláboyún - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yarí
- Mide ṣèrántí ikú ìyá rẹ̀, Salawa, Bukunmi, Ninalowo ṣọjọ́ ìbí...
- Wo ǹkan méje tó yẹ kí o mọ̀ nipa Mama Taraba tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 61
- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin yìnbọn lu akẹẹgbẹ́ rẹ̀ àti Olùkọ̀ níléèwé
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
Ninu ọrọ rẹ, aarẹ Buhari ni awọn eniyan kan ko fẹ ilọsiwaju orilẹede Naijiria rara.
''A ti ibode ki wọn yee gbe ayederu bẹntirol wọ Naijiria ati bi wọn ṣe n gbe ounjẹ, ohun ija wọle si Naijiria lọna aitọ,''

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency
''Wọn ṣi n gbe awọn ohun ija wọle si Naijiria, wọn tun gbe irẹsi wọle si Naijiria pẹlu ọkọ ati ọkada,''
''Mo tun paṣẹ ki wọn pa ẹnikẹni to ba gbe ibọn AK-47 ni ọna aitọ, sibẹ wọn ko gbọ.''

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Presidency
Kini awọn ohun miran to tun jẹyọ nibi ipade naa
Ajọ to n gba aarẹ nimọran lori ọrọ aje naa tun parọwa si aarẹ Buhari lati ṣiṣẹ lori pipese ohun elo eto ọgbin kaakiri orilẹ̀ede Naijiria.
Aarẹ Buhari ni awọn yoo tiraka mọ eto ọgbin lorilẹede naa lati le mu ki orilẹede naa bori ipenija eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Presidency
Bakan naa ni wọn gba aarẹ Buhari nimọran lati wa opin si ipenija eto aabo to n buruju ti tẹlẹ lọ kaakiri orilẹede Naijiria.














