Wo ǹkan méje tó yẹ kí o mọ̀ nipa Mama Taraba tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 61

Aisha Jummai Al-Hassan

Oríṣun àwòrán, Aisha Al Hassan

Iku ko dọjọ, arun ko doṣu, minisita ọrọ awọn obinrin tẹlẹ, Aisha Jummai Al-Hassan ti ọpọ mọ si Mama Taraba ti jade laye.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni yajo yajo sọ pe ilu Cairo lorilẹede Egypt ni Mama Taraba ku si.

Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni minisita ọrọ obinrin tẹlẹ i ṣe ki ọlọjọ to de.

Ohun meje to yẹ ki o mọ nipa Aisha Jummai Al-Hassan niyii

1. A bi Aisha Jummai Al-Hassan ti ọpọ mọ si Mama Taraba ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan an lọdun 1959 niluu Jalingo nipinlẹ Taraba.

2. Mama Taraba ni obinrin akọkọ to jẹ kọmiṣọnaa eto idajọ ati agbẹjọro agba nipinlẹ Taraba.

Oun naa tun ni obinrin akọkọ ti wọn yan gẹgẹ bi akọwe igbimọ eto idajọ l'Abuja lọdun 2003.

3. Ọdun 2015 ni Aarẹ Muhammadu Buhari yan an sipo minisita lẹyin to wọle ibo gbogbo tan.

4. Mama Taraba kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi minisita lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun 2018 lẹyin ti igbimọ to n ṣayẹwo awọn oludije fẹgbẹ APC yọ ọ kuro ninu awọn to dije ninu ibo abẹnu fun ipo gomina lọdun 2019.

5. Ẹgbẹ oṣelu UDP gba Mama Taraba tọwọ tẹsẹ gẹgẹ bi oludipe fun ipo gomina nipinlẹ Taraba lẹti oludije kan yẹba fun un.

6. Wọn fun Aisha Al-Hassan ni inagijẹ ''Mama Taraba'' nitori ipa ribi ribi to n ko ninu eto osẹlu ipinlẹ Taraba.

7. Minisita ọrọ obinrin tẹlẹ ṣe atilẹyin fun ajọ to n ri si ere bọọlu ipinlẹ Taraba nigba aye rẹ.