Kairo Oshodi Market Fire: LASEMA tọ́ka pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó ba dúkìá jẹ́

Nkan abugbamu

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ti sọ pe ejo lọwọ ninu ijamba ina to sakoba fun ọpọ dukia ni ọja alasọ Kairo ni Oshodi l'Ọjọbọ.

Ninu atẹjade kan ti ọga ajọ naa, Dokita Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu fi sọwọ si BBC Yoruba, o ni awọn ṣi n se iwadii lọwọ ṣugbọn ninu nkan ti awọn ri, o dabi ẹni pe awọn kan yin ado oloro kekeeke kan to seese ki o sokunfa ina to jo ọja naa.

Ko si eeyan kankan to ba isẹlẹ naa lọ ati pe lọwọ lọwọ bayi, wọn ti n bu omi si ina lati mu ki agbegbe ọhun tutu diẹ.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá
Nkan abugbamu

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Dokita Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu ni awọn ti fi ọrọ yi to awọn agbofinro leti ti wọn si ti bẹrẹ iwadii lati tusu di isalẹ koko ohun to sokunfa ina naa.

Ohun taa si mọ nipa ijamba ina yi

Nkan bi ago mẹjọ alẹ ọjọbọ ni ina yi bẹrẹ to si sakoba fawọn sọọbu to wa nibi ti wọn ti n ta asọ lọja naa.

Ohun to sokunfa ina naa ko daju sugbọn awọn dukia ti iye owo rẹ wọ ẹgbẹgbẹrun miliọnu Naira lo sakoba fun.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'
Ọja Kairo

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Pupọ awọn ile itaja ti wọn sọ agadagodo si ni ina yi ti bẹrẹ to si gbalẹ laipẹ.

O gba awọn osisẹ pajawiri, ọlọpaa ati panapana lọpọ asiko ki wọn to ri ina yi pa.

Pupọ awọn olutaja lo ti palẹmọ lọ sile nigba ti ina naa yoo fi bẹrẹ.

Ko si eeyan kankan ti akọsilẹ wa pe o ba ijamba ina yi lọ.