Fayose, Reno Omokri vs Aisha Buhari: Olùdíje ààrẹ tó bá jẹ́ ìpè Iftar Aisha Buhari kò tó ọkùnrin, ẹ má ṣé dìbò fún un

Aworan Ayo Fayose,Aisha Buhari
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ojumọ kan ọrọ kan, eleyi taa ri gbọ nilẹ oni to mọ ni Naijiria ni bawọn araalu ṣe n fesi pada fun iyawo aarẹ Aisha Buhari.

Eleyi ko si ṣẹyin bo ṣe f'iwe pe awọn oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu jakejado Naijiria lati wa jẹ Iftar lọdọ rẹ.

Agbaọjẹ oloṣelu to fi igba kan jẹ Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayo Fayose wa lara awọn to n dije du ipo aarẹ. O si ti fesi si iyawo aarẹ lori ipe rẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ileeṣẹ BBC Yoruba pẹlu agbẹnusọ Fayose, Lere Olayinka, o ni ''Fayose kii ba eeyan jẹ ijẹkujẹ''

Àkọlé fídíò, Oru tí olóríibú máa ń di olóríire ni "Laylatul Qadr", tóo bá bẹ Ọlọ́hun, orú agbára gidi ni - Akeugbagold

Olayinka sọ pe to ba ṣe pe iyawo aarẹ nifẹ awọn mẹkunnu ni, ko ni fiwe pe awọn to jẹun kanu lati tun wa jẹ ounjẹ iṣinu lọdọ rẹ.

''Ṣe ti iyawo aarẹ ba fẹ ni ki eeyan wa j iṣinu ṣe awọn to ni owo lati ra fọọmu ogoji miliọnu Naira lati dije dupo aarẹ lo yẹ ko kesi?''

''Ṣe o fẹ sọ wipe oun ko ri awọn ọmọ alaini to pọ ni Naijiria lati fun ni ounjẹ lasiko awẹ ni? Ni ti Fayose, kii ba wọn j ijẹkujẹ rara ati rara''

Kini ounjẹ Iftar ati pe ki lo de ti iyawo aarẹ ṣe ni kawọn eeyan wa jẹun?

Ounjẹ Iftar yi jẹ ounjẹ iṣinu tawọn musulumi ma fi n tunu awẹ ti ọpọ a si maa pe ọrẹ tabi alabaṣepọ lati wa tunu awẹ lọdọ wọn.

Ninu awọn to bẹrẹ si ni wọ iyawo aarẹ lori ipe rẹ yi yatọ si Fayose to jẹ oludije ipo aarẹ ni Reno Omokri to ni ẹnikẹni to ba lọ sibẹ kii ṣe ọkunrin.

Tori naa o ni ''ki awọn ọmọ Naijiria ma ṣe dibo fun iru ni bẹ.''

Bakan naa ni Reno Omokri sọ pe oun jẹri oludije kan, iyẹn Atiku Abubakar pe ko ni bawọn kopa ninu apejẹ yi.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Loju opo rẹ ni Reno Omokri ti sọ ọrọ yi ṣugbọn oun nikan kọ ni ero rẹ ri bayi lori ipe iyawo aarẹ Aisha Buhari.

Baa ba bọ si oju opo Twitter fapẹrẹ, niṣe lawọn eeyan bọ sibẹ ti wọn si n ferongba wọn han lori ọrọ Aisha Buhari yi.

aWORAN IWE IPE

Ibi ti wọn ti kọkọ bẹrẹ fakinfa ni iru ọrọ to wa ninu iwe iwe ipe ti iyawo aarẹ fi ranṣẹ paapa wi pe kawọn to n bọ ma ṣe mu foonu wọn lọwọ.

Lori boya iyawo aarẹ paṣẹ pe ki awọn eeyan wa ni tabi o fi tọwọtọwọ pe awọn oludije yi, aroye bẹ silẹ ni pẹrẹwu.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Kini ọfisi iyawo aarẹ sọ si iwe ipe yi?

Ileesẹ BBC Yoruba gbiyanju lati ba awọn agbodegba iyawo aarẹ ni paapa Aliyu Abdullahi to jẹ oluranlọwọ si yawo aar lori ọrọ iroyin sọrọ ṣugbọn pabo lo ja si.

Ohun ta fẹẹ beere lọwọ wọn ni pe ki gaan lo mu ki iyawo aarẹ sọ pe ki awọn oludije ipo aarẹ wa jẹ Iftar to si ni ki wọn ma ṣe mu foonu wọn lọwọ.

Bi iyawo aarẹ ba gbalejo awọn taa n wi yi, ohun ti yoo tunmọ si ni pe iru oludije bi igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo, Asiwaju Bola Tinubu, Bukola Saraki, Rotimi Amaechi,Peter Obi, ati awọn mi yoo wa sibẹ.

Ṣaaju ipe si awọn oludije yi, iyawo aarẹ ti pe awọn iyawo olori ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ati awọn obinrin to jẹ ọmọ ile aṣofin Naijiria.

Koda o tun pe awọn Minisita obinrin kọọkan naa si apejẹ ounjẹ Iftar ni ile ijọba Naijiria Aso Rock.