Obasanjo: Ọ̀rọ̀ ìgbésùnmọ̀mí ní Naijiria ti kọjá ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá agbègbè

Oríṣun àwòrán, @firstladyship
Ààrẹ Naijiria nigba kan, Olusegun Obasanjo, ti sọ pe idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ, lo le fi òpin si ipenija eto aabo ni Naijiria.
Obasanjo daba yii lasiko to gbalejo awọn adari apapọ ẹgbẹ́ àwọn alaga ìjọba ibilẹ nigba kan, n'ilu Abeokuta.
Atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Kehinde Akinyemi, fi sita, eyi ti iwe iroyin Daily Post jabọ, sọ pe alaga àpapọ̀ akọkọ fun ẹgbẹ́ naa, Ọnarebu Albert Asipa, lo lewaju ikọ abẹwo naa.
- Awakọ̀ ṣekúpa òṣìṣẹ́ LASTMA
- Ẹ̀yà Igbo ni ipò Ààrẹ kàn, tá a ba fẹ́ àlàáfíà àti àìṣègbè - Adebanjo
- "100m tí APC ń bèrè fún owó fọ́ọ̀mù kò ní jẹ́ kí àwọn tó nífẹ́ aráàlù dé ipò ìjọba"
- Rádaràda lẹ̀yin olórin ẹ̀mí tẹ́ẹ̀ ń ṣí ara sílẹ̀, tún kó elégbè mẹ́rin kó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ onílù - Senwele Jesu
- Wo iye tó san to bá fẹ́ lọ sí Hajj ọdún yìí
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá sọ ìgbà tí wọ́n ó gbé ọkọ akọrin Osinachi tó dolóògbé lọ sí iléẹjọ́
Obasanjo sọ pe awọn alaga ìjọba ibilẹ kan ni Naijiria, wulo ju àwọn olori kan to wa nipo nla.
O ni "ọrọ igbesunmọmi ti kọjá idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe.
" Idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lo le yanju rẹ. Lati ara ọlọpaa ipinlẹ, lẹyin eyi la to o le jiroro nipa ọlọpaa agbegbe.
Oloye Obasanjo sọ pe o ṣe koko ki ijọba, ro eto isakoso iṣembaye ati ti ijọba ibilẹ, ti oun ṣètò rẹ lasiko iṣejọba oun ati oloogbe Murtala Muhammed, ni agbara.
"Iwoye mi ni pe o pọn dandan ki ẹka ijọba naa, ṣíṣẹ́ gẹgẹ bi ìjọba ibilẹ to jẹ́, nitori pe wọn ni igbimọ alaṣẹ ti wọn, ẹka idajọ, ati awọn aṣofin.
O ni ṣùgbọ́n o jẹ ibanujẹ pe eto ijọba ibilẹ to n la ọna, mojuto eto ẹ̀kọ́, ilera, iṣẹ agbẹ, ati iṣejọba, ti parẹ patapata.
Eto ìjọba ibilẹ ni Naijiria
- Ijọba ibilẹ ẹgbẹrin din mẹrin, lo wa ni Naijiria
- Ikọọkan si ma n ni wọọdu mẹwaa si ogún
- Lara awọn ojúṣe ti ofin la kalẹ fun ijọba ibilẹ ni:
- Gbigba ìjọba ipinlẹ ni imọran lori eto ọrọ aje
- Gbigba owo ori
- Idasilẹ, amojuto ati atunṣe àwọn ọjà, ibudokọ ati awọn nkan amayedẹrun miran.
- Lila ati amojuto opopona, oju ọna fun àgbàrá, ati oju ọna laarin agboole.
















